Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 4:3 - Yoruba Bible

3 Nígbà tí Jesu mọ̀ pé àwọn Farisi ti gbọ́ ìròyìn yìí, ó kúrò ní Judia, ó tún pada lọ sí Galili.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 O fi Judea silẹ, o si tún lọ si Galili.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Ó fi Judea sílẹ̀, ó sì tún lọ sí Galili.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 4:3
11 Iomraidhean Croise  

Bí wọn bá ṣe inúnibíni yín ní ìlú kan, ẹ sálọ sí ìlú mìíràn. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹ kò ní tíì ya gbogbo ìlú Israẹli tán kí Ọmọ-Eniyan tó dé.


Jesu pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ yẹra lọ sí ẹ̀bá òkun. Ogunlọ́gọ̀ eniyan sì ń tẹ̀lé e. Wọ́n wá láti Galili ati Judia ati Jerusalẹmu;


Bí Jesu ti ń bá ìrìn àjò rẹ̀ lọ sí Jerusalẹmu, ó ń gba ààrin Samaria ati Galili kọjá.


Ní ọjọ́ keji, bí Jesu ti fẹ́ máa lọ sí ilẹ̀ Galili, ó rí Filipi. Ó sọ fún un pé, “Máa tẹ̀lé mi.”


Ó tún pada lọ sí òdìkejì odò Jọdani níbi tí Johanu tí ń ṣe ìrìbọmi ní àkọ́kọ́, ó bá ń gbé ibẹ̀.


Nítorí náà, Jesu kò rìn ní gbangba mọ́ láàrin àwọn Juu, ṣugbọn ó kúrò níbẹ̀, ó lọ sí ìlú kan lẹ́bàá aṣálẹ̀, tí ó ń jẹ́ Efuraimu. Níbẹ̀ ni ó ń gbé pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.


Èyí ni ìbẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jesu ṣe ní Kana ti Galili. Èyí gbé ògo rẹ̀ yọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á gbọ́.


Lẹ́yìn èyí, Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Judia, wọ́n ń gbé ibẹ̀, ó bá ń ṣe ìrìbọmi fún àwọn eniyan.


Ohun tí ó rí, tí ó sì gbọ́ ni ó ń jẹ́rìí sí, ṣugbọn ẹ̀yin kò gba ẹ̀rí rẹ̀.


Nígbà tí ó gbọ́ pé Jesu ti dé sí Galili láti Judia, ó lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ láti bẹ̀ ẹ́ pé kí ó wá wo ọmọ òun sàn, nítorí ọmọ ọ̀hún ń kú lọ.


Lẹ́yìn èyí, Jesu ń lọ káàkiri ní ilẹ̀ Galili nítorí kò fẹ́ máa káàkiri ilẹ̀ Judia mọ́, nítorí àwọn Juu ń wá ọ̀nà láti pa á.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan