Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 4:29 - Yoruba Bible

29 “Ẹ wá wo ọkunrin tí ó sọ gbogbo ohun tí mo ti ṣe fún mi. Ǹjẹ́ Mesaya tí à ń retí kọ́?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

29 Ẹ wá wò ọkunrin kan, ẹniti o sọ ohun gbogbo ti mo ti ṣe ri fun mi: eyi ha le jẹ Kristi na?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

29 “Ẹ wá wò ọkùnrin kan, ẹni tí ó sọ ohun gbogbo tí mo ti ṣe rí fún mi: èyí ha lè jẹ́ Kristi náà?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 4:29
12 Iomraidhean Croise  

Ẹnu ya gbogbo àwọn eniyan, wọ́n ń wí pé, “Ó ha lè jẹ́ pé ọmọ Dafidi nìyí bí?”


Obinrin náà sọ fún un pé, “Mo mọ̀ pé Mesaya, tí ó ń jẹ́ Kristi, ń bọ̀. Nígbà tí ó bá dé, yóo fi ohun gbogbo hàn wá.”


Obinrin náà fi ìkòkò omi rẹ̀ sílẹ̀, ó lọ sí ààrin ìlú, ó sọ fún àwọn eniyan pé,


Wọ́n bá jáde láti inú ìlú lọ sọ́dọ̀ Jesu.


Ọpọlọpọ ninu àwọn ará Samaria tí ó wá láti inú ìlú gbà á gbọ́ nítorí ọ̀rọ̀ obinrin tí ó jẹ́rìí pé, “Ó sọ gbogbo ohun tí mo ṣe fún mi.”


Wò ó bí ó ti ń sọ̀rọ̀ ní gbangba tí wọn kò sì sọ ohunkohun sí i. Àbí àwọn aláṣẹ ti mọ̀ dájú pé òun ni Mesaya ni?


Ọpọlọpọ ninu àwọn eniyan gbà á gbọ́, wọ́n ń sọ pé, “Bí Mesaya náà bá dé, ǹjẹ́ yóo ṣe iṣẹ́ ìyanu ju èyí tí ọkunrin yìí ń ṣe lọ?”


Ẹ̀mí ati Iyawo ń wí pé, “Máa bọ̀!” Ẹni tí ó gbọ́ níláti sọ pé, “Máa bọ̀.” Ẹni tí òùngbẹ bá ń gbẹ kí ó wá, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mu omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.


Samuẹli dá a lóhùn pé, “Èmi aríran náà nìyí. Ẹ máa lọ sí ibi tí wọ́n ti ń rú ẹbọ, nítorí ẹ óo bá mi jẹun lónìí. Bí ó bá di òwúrọ̀ ọ̀la, n óo jẹ́ kí ẹ lọ, n óo sì sọ gbogbo ohun tí ẹ fẹ́ mọ̀ fun yín.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan