Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 4:24 - Yoruba Bible

24 Ẹ̀mí ni Ọlọrun, àwọn tí ó bá ń sìn ín níláti sìn ín ní ẹ̀mí ati ní òtítọ́.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

24 Ẹmí li Ọlọrun: awọn ẹniti nsìn i ko le ṣe alaisìn i li ẹmí ati li otitọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

24 Ẹ̀mí ni Ọlọ́run: àwọn ẹni tí ń sìn ín kò lè ṣe aláìsìn ín ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 4:24
13 Iomraidhean Croise  

OLUWA súnmọ́ gbogbo àwọn tí ń pè é, àní, àwọn tí ń pè é tọkàntọkàn.


Ẹni tí ó bá mu ọpẹ́ wá, tí ó fi rúbọ sí mi, ni ó bu ọlá fún mi; ẹni tí ó bá sì rìn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́ ni èmi Ọlọrun yóo gbà là.”


Ẹbọ tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ ìwọ Ọlọrun ni ẹ̀mí ìròbìnújẹ́, ọkàn ìròbìnújẹ́ ati ìrònúpìwàdà ni ìwọ kì yóo gàn.


Bí mo bá gba ẹ̀ṣẹ̀ láyè ní ọkàn mi, OLUWA ìbá tí gbọ́ tèmi.


Nítorí Ẹni Gíga, tí ó ga jùlọ, ẹni tí ń gbé ninu ayérayé, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mímọ́: òun ni ó ní, “Ibi gíga ati mímọ́ ni mò ń gbé lóòótọ́, ṣugbọn mo wà pẹlu àwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn ati àwọn onírẹ̀lẹ̀. Láti sọ ọkàn wọn jí.


Ṣugbọn àkókò ń bọ̀, ó tilẹ̀ dé tán báyìí, nígbà tí àwọn tí ń jọ́sìn tòótọ́ yóo máa sin Baba ní ẹ̀mí ati ní òtítọ́, nítorí irú àwọn bẹ́ẹ̀ ni Baba ń wá kí wọ́n máa sin òun.


Nǹkankan wà tí a lè fi ṣe ìgbéraga, ẹ̀rí-ọkàn wa sì jẹ́rìí sí i pé pẹlu ọkàn kan ati inú kan níwájú Ọlọrun ni a fi ń bá gbogbo eniyan lò, pàápàá jùlọ ẹ̀yin gan-an. Kì í ṣe ọgbọ́n eniyan bíkòṣe oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun.


Ǹjẹ́ Oluwa tí à ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí ni Ẹ̀mí Mímọ́. Níbikíbi tí Ẹ̀mí Oluwa bá wà, òmìnira wà níbẹ̀.


Nítorí àwa gan-an ni ọ̀kọlà, àwa tí à ń sin Ọlọrun nípa Ẹ̀mí, tí à ń ṣògo ninu Kristi Jesu, tí a kò gbára lé nǹkan ti ara,


Kí ọlá ati ògo jẹ́ ti Ọba ayérayé, Ọba àìkú, Ọba àìrí, Ọlọrun kan ṣoṣo, lae ati laelae. Amin.


Ṣugbọn OLUWA wí fún Samuẹli pé, “Má ṣe wo ìrísí rẹ̀ tabi gíga rẹ̀, nítorí pé, mo ti kọ̀ ọ́. OLUWA kìí wo nǹkan bí eniyan ti ń wò ó, eniyan a máa wo ojú, ṣugbọn OLUWA a máa wo ọkàn.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan