Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 4:22 - Yoruba Bible

22 Ẹ̀yin ará Samaria kò mọ ẹni tí ẹ̀ ń sìn. Àwa Juu mọ ẹni tí à ń sìn, nítorí láti ọ̀dọ̀ wa ni ìgbàlà ti wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

22 Ẹnyin nsìn ohun ti ẹnyin kò mọ̀: awa nsìn ohun ti awa mọ̀: nitori igbala ti ọdọ awọn Ju wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

22 Ẹ̀yin ń sin ohun tí ẹ̀yin kò mọ̀: àwa ń sin ohun tí àwa mọ̀: nítorí ìgbàlà ti ọ̀dọ̀ àwọn Júù wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 4:22
20 Iomraidhean Croise  

Ọ̀pá àṣẹ ọba kì yóo kúrò ní ilé Juda, arọmọdọmọ rẹ̀ ni yóo sì máa jọba, títí tí yóo fi dé ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ni ín; gbogbo ìran eniyan ni yóo sì máa pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.


wọ́n wá sọ́dọ̀ Serubabeli, ati sọ́dọ̀ àwọn baálé baálé, wọ́n wí fún wọn pé, “Ẹ jẹ́ kí á jọ kọ́ ọ nítorí ọ̀kan náà ni wá, Ọlọrun yín ni àwa náà ń sìn, a sì ti ń rúbọ sí i láti ìgbà ayé Esaradoni, ọba Asiria, tí ó mú wa wá síhìn-ín.”


Ó ṣí ọ̀rọ̀ rẹ̀ payá fún Jakọbu, ó sì fi òfin ati ìlànà rẹ̀ han Israẹli.


Ọlọrun tí ń gbani là ni Ọlọrun wa; OLUWA Ọlọrun ni ń yọni lọ́wọ́ ikú.


Wò ó! Ọlọrun ni olùgbàlà mi, n óo gbẹ́kẹ̀lé e ẹ̀rù kò sì ní bà mí, nítorí pé OLUWA Ọlọrun ni agbára mi, ati orin mi, òun sì ni Olùgbàlà mi.”


Ẹ̀yin tí ń gbé Sioni, ẹ hó, ẹ kọrin ayọ̀, ẹ̀yin olùgbé Sioni, nítorí Ẹni ńlá ni Ẹni Mímọ́ Israẹli tí ó wà láàrin yín.”


Ọpọlọpọ eniyan ni yóo wá, tí wọn yóo máa wí pé: “Ẹ wá! Ẹ jẹ́ kí á gun òkè OLUWA lọ, kí á lọ sí ilé Ọlọrun Jakọbu, kí ó lè kọ́ wa ní ìlànà rẹ̀, kí á sì lè rìn ní ọ̀nà rẹ̀. Nítorí pé láti Sioni ni òfin Ọlọrun yóo ti jáde wá ọ̀rọ̀ OLUWA yóo sì wá láti Jerusalẹmu.”


Mo mú ìdáǹdè mi wá sí tòsí, kò jìnnà mọ́, ìgbàlà mi kò ní pẹ́ dé. N óo fi ìgbàlà mi sí Sioni, fún Israẹli, ògo mi.”


Ẹ máa yọ̀, ẹ̀yin ará Sioni! Ẹ hó ìhó ayọ̀, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu! Wò ó! Ọba yín ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín; ajagun-ṣẹ́gun ni, sibẹsibẹ ó jẹ́ onírẹ̀lẹ̀, ó sì gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, kódà, ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni ó gùn.


Ati pé ní orúkọ rẹ̀, kí á máa waasu ìrònúpìwàdà ati ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ohun tí ó bẹ̀rẹ̀ láti Jerusalẹmu.


Bí mo ti ń lọ tí mò ń bọ̀ ni mò ń fojú wo àwọn ohun tí ẹ̀ ń sìn. Mo rí pẹpẹ ìrúbọ kan tí ẹ kọ àkọlé báyìí sí ara rẹ̀ pé: ‘Sí Ọlọrun tí ẹnìkan kò mọ̀.’ Ohun tí ẹ kò mọ̀ tí ẹ̀ ń sìn, òun ni mò ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ fun yín.


Ọlọrun ti fojú fo àkókò tí eniyan kò ní ìmọ̀ dá. Ṣugbọn ní àkókò yìí, ó pàṣẹ fún gbogbo eniyan ní ibi gbogbo láti ronupiwada.


Nígbà tí Ọlọrun gbé Ọmọ rẹ̀ dìde, ẹ̀yin ni ó kọ́kọ́ rán an sí, kí ó lè bukun yín láti mú kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yipada kúrò ní ọ̀nà burúkú rẹ̀.”


Nítorí náà, má ṣe fọ́nnu bí ẹni pé o sàn ju àwọn ẹ̀ka ti àkọ́kọ́ lọ. Tí o bá ń fọ́nnu, ranti pé kì í ṣe ìwọ ni ò ń gbé gbòǹgbò ró.


Nítorí ó hàn gbangba pé láti inú ẹ̀yà Juda ni Oluwa wa ti wá. Mose kò sì sọ ohunkohun tí ó jẹ mọ́ iṣẹ́ alufaa nípa ẹ̀yà yìí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan