Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 4:20 - Yoruba Bible

20 Ní orí òkè tí ó wà lọ́hùn-ún yìí ni àwọn baba wa ń sin Ọlọrun, ṣugbọn ẹ̀yin wí pé Jerusalẹmu ni ibi tí a níláti máa sìn ín.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

20 Awọn baba wa sìn lori òke yi; ẹnyin si wipe, Jerusalemu ni ibi ti o yẹ ti a ba ma sìn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

20 Àwọn baba wa sìn lórí òkè yìí; ẹ̀yin sì wí pé, Jerusalẹmu ni ibi tí ó yẹ tí à bá ti máa sìn.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 4:20
20 Iomraidhean Croise  

ó wí fún un pé, “Mo ti gbọ́ adura ati ẹ̀bẹ̀ rẹ, mo sì ti ya ilé tí o kọ́ yìí sí mímọ́. Ibẹ̀ ni wọn óo ti máa sìn mí títí lae. N óo máa mójú tó o, n óo sì máa dáàbò bò ó nígbà gbogbo.


Dafidi tẹ́ pẹpẹ níbẹ̀, ó rú ẹbọ sísun ati ẹbọ alaafia, ó bá képe OLUWA. OLUWA dá a lóhùn: ó rán iná sọ̀kalẹ̀ láti jó ẹbọ sísun náà.


Nítorí náà Dafidi pàṣẹ pé, “Ibí yìí ni ilé OLUWA Ọlọrun, ati pẹpẹ ẹbọ sísun yóo wà fún Israẹli.”


Ṣugbọn nisinsinyii, mo yan Jerusalẹmu fún ibi ìjọ́sìn ní orúkọ mi, mo sì ti yan Dafidi láti jẹ́ olórí Israẹli, eniyan mi.’ ”


Lẹ́yìn náà, OLUWA fara han Solomoni lóru, ó ní, “Mo ti gbọ́ adura rẹ, mo sì ti yan ibí yìí ní ilé ìrúbọ fúnra mi.


Mo ti yan ibí yìí, mo sì ti yà á sí mímọ́, kí á lè máa jọ́sìn ní orúkọ mi níbẹ̀ títí lae. Ojú ati ọkàn mi yóo wà níbẹ̀ nígbà gbogbo.


Nítorí OLUWA ti yan Sioni; ó fẹ́ ẹ fún ibùjókòó rẹ̀:


ṣugbọn ó yan ẹ̀yà Juda, ó sì yan òkè Sioni tí ó fẹ́ràn.


OLUWA ní: “Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ayé ni àpótí ìtìsẹ̀ mi. Ilé tí ẹ kọ́ fún mi dà? Níbo sì ni ibi ìsinmi mi wà?


Ṣugbọn wọn kò gbà á, nítorí ó hàn dájú pé ó ń lọ sí Jerusalẹmu.


Ìwọ kò ṣá ju Jakọbu baba-ńlá wa, tí ó gbẹ́ kànga yìí fún wa lọ, tí òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ ati ẹran-ọ̀sìn rẹ̀ sì ń mu níbẹ̀?”


Nígbà tí OLUWA Ọlọrun yín bá mú yín dé ilẹ̀ tí ẹ̀ ń wọ̀ lọ, tí ẹ óo sì gbà, ẹ kéde ibukun náà lórí òkè Gerisimu, kí ẹ sì kéde ègún náà lórí òkè Ebali.


“Nígbà tí ẹ bá kọjá odò Jọdani sí òdìkejì, àwọn ẹ̀yà Simeoni, ẹ̀yà Lefi, ti Juda, ti Isakari, ti Josẹfu ati ti Bẹnjamini yóo dúró lórí òkè Gerisimu láti súre.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan