Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 4:18 - Yoruba Bible

18 nítorí o ti ní ọkọ marun-un rí, ẹni tí o wà lọ́dọ̀ rẹ̀ nisinsinyii kì í sì í ṣe ọkọ rẹ. Òtítọ́ ni o sọ.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

18 Nitoriti iwọ ti li ọkọ marun ri; ẹniti iwọ si ni nisisiyi kì iṣe ọkọ rẹ; iwọ sọ otitọ li eyini.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

18 Nítorí tí ìwọ ti ní ọkọ márùn-ún rí; ọkùnrin tí ìwọ sì ní báyìí kì í ṣe ọkọ rẹ. Ohun tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí, òtítọ́ ni.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 4:18
16 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn Ọlọrun tọ Abimeleki wá lóru lójú àlá, ó sì wí fún un pé, “O jẹ́ mọ̀! Ikú ti pa ọ́ tán báyìí, nítorí pé obinrin tí o mú sọ́dọ̀, aya aláya ni.”


Nígbà tí Ṣekemu ọmọ Hamori, ará Hifi, tíí ṣe ọmọ ọba ìlú náà rí i, ó fi ipá mú un, ó sì bá a lòpọ̀ tipátipá.


Ṣugbọn wọ́n dáhùn pé, “Àwa kò lè gbà kí ó ṣe arabinrin wa bí aṣẹ́wó.”


Dájúdájú bí obinrin alaiṣootọ tíí fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni o ti ṣe alaiṣootọ sí mi, ìwọ Israẹli. Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”


Ìwọ iyawo onípanṣágà tí ò ń kó àwọn ọkunrin ọlọkunrin wọlé dípò ọkọ rẹ.


Nítorí náà, ìwọ aṣẹ́wó yìí, gbọ́ ohun tí OLUWA wí.


“Èyí ni ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe nígbà tí obinrin bá ṣe aiṣootọ sí ọkọ rẹ̀, tí ó sì ba ara rẹ̀ jẹ́ nítorí pé ọkunrin mìíràn bá a lòpọ̀;


Bí ó bá sì jẹ́ pé obinrin ni ó kọ ọkọ rẹ̀, tí ó fẹ́ ọkọ mìíràn, òun náà ṣe àgbèrè.”


Jesu wí fún un pé, “Lọ pe ọkọ rẹ wá ná.”


Obinrin náà dáhùn pé, “Èmi kò ní ọkọ.” Jesu wí fún un pé, “O wí ire pé o kò ní ọkọ,


Obinrin náà sọ fún un pé, “Alàgbà, mo wòye pé wolii ni ọ́.


Wàyí ò, bí obinrin náà bá lọ bá ọkunrin mìíràn nígbà tí ọkọ rẹ̀ wà láàyè, alágbèrè ni a óo pè é. Ṣugbọn tí ọkọ rẹ̀ bá ti kú, ó bọ́ lọ́wọ́ òfin igbeyawo, kì í ṣe àgbèrè mọ́, bí ó bá lọ fẹ́ ọkọ mìíràn.


Ohun tí ó lọ́lá ni igbeyawo. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì yẹ kí gbogbo yín kà á sí. Ibùsùn tọkọtaya gbọdọ̀ jẹ́ aláìléèérí. Nítorí Ọlọrun yóo dájọ́ fún àwọn oníṣekúṣe ati àwọn àgbèrè.


Ati pé, mo ṣú Rutu, ará Moabu, opó Maloni lópó, ó sì di aya mi; kí orúkọ òkú má baà parun lára ohun ìní rẹ̀, ati pé kí á má baà mú orúkọ rẹ̀ kúrò láàrin àwọn arakunrin rẹ̀ ati ní ẹnu ọ̀nà àtiwọ ìlú baba rẹ̀. Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí lónìí.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan