Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 4:15 - Yoruba Bible

15 Obinrin náà sọ fún un pé, “Alàgbà, fún mi ní omi yìí kí òùngbẹ má baà gbẹ mí mọ́, kí n má baà tún wá pọn omi níhìn-ín mọ́.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

15 Obinrin na si wi fun u pe, Ọgbẹni, fun mi li omi yi, ki orùngbẹ ki o màṣe gbẹ mi, ki emi ki o má si wá fà omi nihin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

15 Obìnrin náà sì wí fún u pé, “Alàgbà, fún mi ní omi yìí, kí òǹgbẹ kí ó má ṣe gbẹ mí, kí èmi kí ó má sì wá fa omi níbí mọ́.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 4:15
11 Iomraidhean Croise  

Ọ̀pọ̀ eniyan ni ó ń bèèrè pé “Ta ni yóo ṣe wá ní oore?” OLUWA, tan ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ sí wa lára.


Jesu wí fún un pé, “Lọ pe ọkọ rẹ wá ná.”


Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, kì í ṣe nítorí pé ẹ rí iṣẹ́ ìyanu mi ni ẹ ṣe ń wá mi, ṣugbọn nítorí ẹ jẹ oúnjẹ àjẹyó ni.


Wọ́n bá sọ fún un pé, “Alàgbà, máa fún wa ní oúnjẹ yìí nígbà gbogbo.”


Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi gan-an ni oúnjẹ tí ń fún eniyan ní ìyè, ẹni tí ó bá wá sọ́dọ̀ mi, ebi kò ní pa á, ẹni tí ó bá sì gbà mí gbọ́, òùngbẹ kò ní gbẹ ẹ́ laelae.


Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, ṣugbọn ẹ̀bùn Ọlọrun ni ìyè ainipẹkun pẹlu Jesu Kristi Oluwa wa.


Nítorí àwọn tí ó ń hùwà gẹ́gẹ́ bí ẹni tí ẹran- ara ń lò a máa lépa ìtẹ́lọ́rùn fún ẹran-ara; ṣugbọn àwọn tí Ẹ̀mí ń darí a máa lépa àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí.


Ṣugbọn eniyan ẹlẹ́ran-ara kò lè gba àwọn nǹkan ti Ẹ̀mí Ọlọrun, nítorí bí ọ̀rọ̀ òmùgọ̀ ni yóo rí lójú rẹ̀. Kò tilẹ̀ lè yé e, nítorí pé ẹni tí ó bá ní Ẹ̀mí ni ó lè yé.


Bí ẹ bá sì bèèrè, ẹ kò rí ohun tí ẹ bèèrè gbà nítorí èrò burúkú ni ẹ fi bèèrè, kí ẹ lè lo ohun tí ẹ bèèrè fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara yín.


A tún mọ̀ pé Ọmọ Ọlọrun ti dé, ó ti fún wa ní làákàyè kí á lè mọ ẹni Òtítọ́. À ń gbé inú Ọlọrun, àní inú Ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi. Òun ni Ọlọrun tòótọ́ ati ìyè ainipẹkun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan