Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 4:14 - Yoruba Bible

14 Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá mu ninu omi tí èmi yóo fi fún un, òùngbẹ kò ní gbẹ ẹ́ mọ́ lae, ṣugbọn omi tí n óo fún un yóo di orísun omi ninu rẹ̀ tí yóo máa sun títí dé ìyè ainipẹkun.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

14 Ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba mu ninu omi ti emi o fifun u, orùngbẹ kì yio gbẹ ẹ mọ́ lai; ṣugbọn omi ti emi o fifun u yio di kanga omi ninu rẹ̀, ti yio ma sun si ìye ainipẹkun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

14 Ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá mu nínú omi tí èmi ó fi fún un, òǹgbẹ kì yóò gbẹ ẹ́ mọ́ láé; ṣùgbọ́n omi tí èmi ó fi fún un yóò di kànga omi nínú rẹ̀, tí yóò máa sun si ìyè àìnípẹ̀kun.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 4:14
32 Iomraidhean Croise  

Ebi kò ní pa wọ́n, òùngbẹ kò sì ní gbẹ wọ́n, atẹ́gùn gbígbóná kò ní fẹ́ lù wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni oòrùn kò ní pa wọ́n, nítorí ẹni tí ó ṣàánú wọn ni yóo máa darí wọn, yóo sì mú wọn gba ẹ̀gbẹ́ omi tí ń ṣàn.


OLUWA ní, “Gbogbo ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ, ẹ máa bọ̀ níbi tí omi wà; bí ẹ kò tilẹ̀ lówó lọ́wọ́, ẹ wá ra oúnjẹ kí ẹ sì jẹ. Ẹ wá ra ọtí waini láì mú owó lọ́wọ́, kí ẹ sì ra omi wàrà, tí ẹnikẹ́ni kò díyelé.


N óo máa tọ yín sọ́nà nígbà gbogbo, n óo fi nǹkan rere tẹ yín lọ́rùn; n óo mú kí egungun yín ó le, ẹ óo sì dàbí ọgbà tí à ń bomi rin, ati bí orísun omi, tí omi rẹ̀ kì í gbẹ.


OLUWA wí pé, “Nítorí pé àwọn eniyan mi ṣe nǹkan burúkú meji: wọ́n ti kọ èmi orísun omi ìyè sílẹ̀, wọ́n ṣe kànga fún ara wọn; kànga tí ó ti là, tí kò lè gba omi dúró.


Nítorí pé n óo fún àwọn tí àárẹ̀ mú ní agbára; n óo sì tu gbogbo ọkàn tí ń kérora lára.”


Ọpọlọpọ ohun ẹlẹ́mìí yóo wà ní ibikíbi tí omi náà bá ti ṣàn kọjá. Ẹja yóo pọ̀ ninu rẹ̀; nítorí pé omi yìí ṣàn lọ sí inú òkun, omi tí ó wà níbẹ̀ yóo di mímọ́ gaara, ohunkohun tí ó bá sì wà ní ibi tí odò yìí bá ti ṣàn kọjá yóo yè.


Tí ó bá jẹ́ odò, tabi kànga tí ó ní omi ni, wọn kì í ṣe aláìmọ́, ṣugbọn gbogbo nǹkan yòókù tí ó fara kan òkú wọn di aláìmọ́.


Àwọn wọnyi ni yóo lọ sinu ìyà àìlópin. Ṣugbọn àwọn olódodo yóo wọ ìyè ainipẹkun.”


Ayọ̀ ń bẹ fún àwọn tí ebi òdodo ń pa, tí òùngbẹ òdodo sì ń gbẹ, nítorí Ọlọrun yóo bọ́ wọn ní àbọ́yó.


Olè kì í wá lásán, àfi kí ó wá jalè, kí ó wá pa eniyan, kí ó sì wá ba nǹkan jẹ́. Èmi wá kí eniyan lè ní ìyè, kí wọn lè ní i lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.


Gbogbo ẹni tí ó bá wà láàyè, tí ó bá gbà mí gbọ́, kò ní kú laelae. Ǹjẹ́ o gba èyí gbọ́?”


Jesu dá a lóhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé o mọ ẹ̀bùn Ọlọrun ati ẹni tí ó wí fún ọ pé, ‘Fún mi ní omi mu,’ Ìwọ ìbá bèèrè omi ìyè lọ́wọ́ rẹ̀, òun ìbá sì fún ọ.”


Obinrin náà sọ fún un pé, “Alàgbà, o kò ní ohun tí o lè fi fa omi, kànga yìí sì jìn, níbo ni ìwọ óo ti mú omi ìyè wá?


Jesu dá a lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá mu ninu omi yìí òùngbẹ yóo tún gbẹ ẹ́.


Ẹni tí ń kórè a máa rí èrè gbà, ó ń kó irè jọ sí ìyè ainipẹkun, kí inú ẹni tí ń fúnrúgbìn ati ti ẹni tí ń kórè lè jọ máa dùn pọ̀.


Ẹ má ṣe làálàá nítorí oúnjẹ ti yóo bàjẹ́, ṣugbọn ẹ ṣiṣẹ́ fún oúnjẹ tí ọmọ eniyan yóo fun yín, tí yóo wà títí di ìyè ainipẹkun, nítorí ọmọ eniyan ni Ọlọrun Baba fún ní àṣẹ.”


Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi gan-an ni oúnjẹ tí ń fún eniyan ní ìyè, ẹni tí ó bá wá sọ́dọ̀ mi, ebi kò ní pa á, ẹni tí ó bá sì gbà mí gbọ́, òùngbẹ kò ní gbẹ ẹ́ laelae.


Èyí ni oúnjẹ tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀, kì í ṣe irú èyí tí àwọn baba yín jẹ, tí wọ́n sì kú sibẹsibẹ. Ẹni tí ó bá jẹ oúnjẹ yìí yóo wà láàyè laelae.”


Nígbà tí ó di ọjọ́ tíí àjọ̀dún yóo parí, tíí ṣe ọjọ́ tí ó ṣe pataki jùlọ, Jesu dìde dúró, ó kígbe pé, “Bí òùngbẹ bá ń gbẹ ẹnikẹ́ni, kí ó wá sọ́dọ̀ mi kí ó mu omi.


Nípa bẹ́ẹ̀, bí ikú ṣe sọ ẹ̀ṣẹ̀ di ọba, bẹ́ẹ̀ ni ìdáláre náà ń fi oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun jọba, ó sì mú wa wọnú ìyè ainipẹkun nípasẹ̀ Jesu Kristi Oluwa wa.


Ikú ni èrè ẹ̀ṣẹ̀, ṣugbọn ẹ̀bùn Ọlọrun ni ìyè ainipẹkun pẹlu Jesu Kristi Oluwa wa.


Ó ti fi èdìdì rẹ̀ sí wa lára, ó tún fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe onídùúró sí ọkàn wa gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí ohun tí yóo tún fún wa.


Ẹ má kó ìbànújẹ́ bá Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọrun, tí Ọlọrun fi ṣèdìdì yín títí di ọjọ́ ìràpadà.


Níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti wẹ ọkàn yín mọ́ nípa ìgbọràn sí òtítọ́, tí ẹ sì ní ìfẹ́ àìlẹ́tàn sí àwọn onigbagbọ ara yín, ẹ fi tinútinú fẹ́ràn ọmọnikeji yín.


A tún mọ̀ pé Ọmọ Ọlọrun ti dé, ó ti fún wa ní làákàyè kí á lè mọ ẹni Òtítọ́. À ń gbé inú Ọlọrun, àní inú Ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi. Òun ni Ọlọrun tòótọ́ ati ìyè ainipẹkun.


Ebi kò ní pa wọ́n mọ́, bẹ́ẹ̀ ni òùngbẹ kò ní gbẹ wọ́n mọ́. Oòrùn kò ní pa wọ́n mọ́, ooru kankan kò sì ní mú wọn mọ́.


Nítorí Ọ̀dọ́ Aguntan tí ó wà láàrin ìtẹ́ náà ni yóo máa ṣe olùtọ́jú wọn, yóo máa dà wọ́n lọ síbi ìsun omi ìyè. Ọlọrun yóo wá nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan