Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 4:10 - Yoruba Bible

10 Jesu dá a lóhùn pé, “Bí ó bá jẹ́ pé o mọ ẹ̀bùn Ọlọrun ati ẹni tí ó wí fún ọ pé, ‘Fún mi ní omi mu,’ Ìwọ ìbá bèèrè omi ìyè lọ́wọ́ rẹ̀, òun ìbá sì fún ọ.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Ibaṣepe iwọ mọ̀ ẹ̀bun Ọlọrun, ati ẹniti o wi fun ọ pe, Fun mi mu, iwọ iba si ti bère lọwọ rẹ̀, on iba ti fi omi ìye fun ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Jesu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ìbá ṣe pé ìwọ mọ ẹ̀bùn Ọlọ́run, àti ẹni tí ó wí fún ọ pé, Fún mi ni omi mu, ìwọ ìbá sì ti béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, òun ìbá ti fi omi ìyè fún ọ.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 4:10
49 Iomraidhean Croise  

OLUWA, o óo gbọ́ igbe àwọn tí a nilára; o óo mú wọn lọ́kàn le, o óo sì dẹ etí sílẹ̀ sí igbe wọn


Odò kan wà tí omi rẹ̀ ń mú inú ìlú Ọlọrun dùn, ìlú yìí ni ibùgbé mímọ́ Ọ̀gá Ògo.


N óo dúró níwájú rẹ lórí àpáta ní òkè Horebu. Nígbà tí o bá fi ọ̀pá lu àpáta náà, omi yóo ti inú rẹ̀ jáde, àwọn eniyan náà yóo sì mu ún.” Mose bá ṣe bẹ́ẹ̀ níwájú gbogbo àwọn àgbààgbà Israẹli.


Ọgbà tí ó ní orísun omi ni ọ́, kànga omi tútù, àní, odò tí ń ṣàn, láti òkè Lẹbanoni.


Tayọ̀tayọ̀ ni ẹ óo fi máa rí ìgbàlà bí ẹni pọn omi láti inú kànga.


arọ yóo máa fò bí ìgalà, odi yóo sì máa kọ orin ayọ̀. Nítorí odò ńlá yóo ṣàn jáde ninu aginjù àwọn odò kéékèèké yóo máa ṣàn ninu aṣálẹ̀.


Ó ní, “Èmi ni OLUWA, mo ti pè ọ́ ninu òdodo, mo ti di ọwọ́ rẹ mú, mo sì pa ọ́ mọ́. Mo ti fi ọ́ ṣe majẹmu fún aráyé, mo sì fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè;


Àwọn ẹranko ìgbẹ́ yóo máa yìn mí lógo, ati àwọn ọ̀fàfà ati ògòǹgò; nítorí pé mo ti ṣe odò ńlá fún wọn ninu aṣálẹ̀, kí àwọn àyànfẹ́ mi lè máa rí omi mu:


“N óo tú omi sórí ilẹ̀ tí òùngbẹ ń gbẹ n óo sì ṣe odò sórí ilẹ̀ gbígbẹ. N óo tú ẹ̀mí mi sórí àwọn ọmọ yín, n óo da ibukun mi sórí arọmọdọmọ yín,


Ebi kò ní pa wọ́n, òùngbẹ kò sì ní gbẹ wọ́n, atẹ́gùn gbígbóná kò ní fẹ́ lù wọ́n, bẹ́ẹ̀ ni oòrùn kò ní pa wọ́n, nítorí ẹni tí ó ṣàánú wọn ni yóo máa darí wọn, yóo sì mú wọn gba ẹ̀gbẹ́ omi tí ń ṣàn.


Nítorí a bí ọmọ kan fún wa, a fún wa ní ọmọkunrin kan. Òun ni yóo jọba lórí wa. A óo máa pè é ní Ìyanu, Olùdámọ̀ràn, Ọlọrun alágbára, Baba ayérayé, Ọmọ-Aládé alaafia.


OLUWA wí pé, “Nítorí pé àwọn eniyan mi ṣe nǹkan burúkú meji: wọ́n ti kọ èmi orísun omi ìyè sílẹ̀, wọ́n ṣe kànga fún ara wọn; kànga tí ó ti là, tí kò lè gba omi dúró.


Nítorí náà, ìwọ aṣẹ́wó yìí, gbọ́ ohun tí OLUWA wí.


OLUWA ní, “Nígbà tó bá yá, orísun omi kan yóo ṣí sílẹ̀ fún ilé Dafidi, ati fún àwọn ará Jerusalẹmu láti wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà èérí wọn.


Tó bá di ìgbà náà, àwọn odò tí wọ́n kún fún omi ìyè yóo máa ṣàn jáde láti Jerusalẹmu. Apá kan wọn yóo máa ṣàn lọ sinu òkun tí ó wà ní ìwọ̀ oòrùn, apá keji yóo máa ṣàn lọ sí òkun tí ó wà ní ìlà oòrùn, yóo sì máa rí bẹ́ẹ̀ tòjò-tẹ̀ẹ̀rùn.


Nítorí náà bí ẹ̀yin tí ẹ burú báyìí bá mọ̀ bí a tií fún àwọn ọmọ yín ní ohun tí ó dára, mélòó-mélòó ni Baba yín ọ̀run yóo fi Ẹ̀mí Mímọ́ fún àwọn tí ó bá bèèrè lọ́wọ́ rẹ̀!”


Wọn yóo ṣe nǹkan wọnyi nítorí wọn kò mọ Baba, wọn kò sì mọ̀ mí.


Ìyè ainipẹkun náà ni pé, kí wọ́n mọ̀ ọ́, ìwọ Ọlọrun tòótọ́ kanṣoṣo, kí wọ́n sì mọ Jesu Kristi ẹni tí o rán níṣẹ́.


Nítorí Ọlọrun fẹ́ aráyé tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kanṣoṣo fúnni, pé kí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbà á gbọ́ má baà ṣègbé, ṣugbọn kí ó lè ní ìyè ainipẹkun.


Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá mu ninu omi tí èmi yóo fi fún un, òùngbẹ kò ní gbẹ ẹ́ mọ́ lae, ṣugbọn omi tí n óo fún un yóo di orísun omi ninu rẹ̀ tí yóo máa sun títí dé ìyè ainipẹkun.”


Jesu dá wọn lóhùn pé, “Èmi gan-an ni oúnjẹ tí ń fún eniyan ní ìyè, ẹni tí ó bá wá sọ́dọ̀ mi, ebi kò ní pa á, ẹni tí ó bá sì gbà mí gbọ́, òùngbẹ kò ní gbẹ ẹ́ laelae.


Èmi ni oúnjẹ tí ó wà láàyè tí ó ti ọ̀run sọ̀kalẹ̀. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ninu oúnjẹ yìí, olúwarẹ̀ yóo wà láàyè laelae. Oúnjẹ tí èmi yóo fi fún un ni ẹran ara mi tí yóo fi ìyè fún gbogbo ayé.”


Oluwa bá sọ fún un pé, “Dìde. Lọ sí títì tí à ń pè ní ‘Títì títọ́,’ ní ilé Judasi kí o bèèrè ẹni tí ó ń jẹ́ Saulu, ará Tasu. O óo bá a ní ibi tí ó gbé ń gbadura.


Ọlọrun, tí kò dá Ọmọ rẹ̀ sí, ṣugbọn tí ó yọ̀ǹda rẹ̀ nítorí gbogbo wa, báwo ni kò ṣe ní fún wa ní ohun gbogbo pẹlu rẹ̀?


Nípa iṣẹ́ Ọlọrun, ẹ̀yin wà ní ìṣọ̀kan pẹlu Kristi Jesu. Òun ni Ọlọrun fi ṣe ọgbọ́n wa ati òdodo wa. Òun ni ó sọ wá di mímọ́, tí ó dá wa nídè.


Gbogbo wọn ni wọ́n mu omi ẹ̀mí kan náà, nítorí wọ́n mu omi tí ó jáde láti inú òkúta ẹ̀mí tí ó ń tẹ̀lé wọn. Òkúta náà ni Kristi.


Ọpẹ́ ni fún Ọlọrun nítorí ẹ̀bùn rẹ̀ tí kò ní òǹkà.


Nítorí oore-ọ̀fẹ́ ni a fi gbà yín là nípa igbagbọ. Kì í ṣe nítorí iṣẹ́, ẹ̀bùn Ọlọrun ni. Kì í ṣe ìtorí iṣẹ́ tí eniyan ṣe, kí ẹnikẹ́ni má baà máa gbéraga.


Nítorí àwọn tí a bá ti là lójú, tí wọ́n ti tọ́wò ninu ẹ̀bùn tí ó ti ọ̀run wá, àwọn tí wọ́n ti ní ìpín ninu ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́,


A tún mọ̀ pé Ọmọ Ọlọrun ti dé, ó ti fún wa ní làákàyè kí á lè mọ ẹni Òtítọ́. À ń gbé inú Ọlọrun, àní inú Ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi. Òun ni Ọlọrun tòótọ́ ati ìyè ainipẹkun.


Ó ní, “Ó parí! Èmi ni Alfa ati Omega, ìbẹ̀rẹ̀ ati òpin. N óo fún ẹni tí òùngbẹ bá ń gbẹ ní omi mu láti inú kànga omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.


Ẹ̀mí ati Iyawo ń wí pé, “Máa bọ̀!” Ẹni tí ó gbọ́ níláti sọ pé, “Máa bọ̀.” Ẹni tí òùngbẹ bá ń gbẹ kí ó wá, ẹni tí ó bá fẹ́ kí ó mu omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.


Nítorí Ọ̀dọ́ Aguntan tí ó wà láàrin ìtẹ́ náà ni yóo máa ṣe olùtọ́jú wọn, yóo máa dà wọ́n lọ síbi ìsun omi ìyè. Ọlọrun yóo wá nu gbogbo omijé kúrò ní ojú wọn.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan