Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 4:1 - Yoruba Bible

1 Àwọn Farisi gbọ́ pé àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń pọ̀ ju àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu lọ; ati pé Jesu ń ṣe ìrìbọmi fún ọpọlọpọ eniyan ju Johanu lọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 NITORINA nigbati Oluwa ti mọ̀ bi awọn Farisi ti gbọ́ pe, Jesu nṣe o si mbaptisi awọn ọmọ-ẹhin pupọ jù Johanu lọ,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Àwọn Farisi sì gbọ́ pé, Jesu ni, ó sì ń ṣe ìtẹ̀bọmi fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn púpọ̀ ju Johanu lọ,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 4:1
15 Iomraidhean Croise  

“Ìwọ, ọmọ mi, wolii Ọ̀gá Ògo ni a óo máa pè ọ́, nítorí ìwọ ni yóo ṣáájú Oluwa láti palẹ̀ mọ́ dè é,


Bí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ fi ń tú u?’ Kí ẹ sọ fún un pé, ‘Oluwa nílò rẹ̀ ni.’ ”


Wọ́n sọ fún wọn pé, “Oluwa nílò rẹ̀ ni.”


Nítorí a bí Olùgbàlà fun yín lónìí, ní ìlú Dafidi, tíí ṣe Oluwa ati Mesaya.


Nígbà tí Oluwa rí obinrin náà, àánú rẹ̀ ṣe é. Ó sọ fún un pé, “Má sunkún mọ́.”


ó rán wọn sí Oluwa láti bi í pé, “Ṣé ìwọ ni ẹni tí ń bọ̀ ni, tabi kí á máa retí ẹlòmíràn?”


Lẹ́yìn èyí, Jesu ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sí ilẹ̀ Judia, wọ́n ń gbé ibẹ̀, ó bá ń ṣe ìrìbọmi fún àwọn eniyan.


Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà bá lọ sọ́dọ̀ Johanu, wọ́n wí fún un pé, “Olùkọ́ni, ọkunrin tí ó wà pẹlu rẹ ní òdìkejì odò Jọdani, tí o jẹ́rìí nípa rẹ̀, ń ṣe ìrìbọmi, gbogbo eniyan sì ń tọ̀ ọ́ lọ.”


Ẹ mọ iṣẹ́ tí ó rán sí àwọn ọmọ Israẹli, ọ̀rọ̀ ìyìn rere alaafia nípasẹ̀ Jesu Kristi, ẹni tíí ṣe Oluwa gbogbo eniyan.


Nítorí pé Kristi kò fi iṣẹ́ ṣíṣe ìrìbọmi rán mi, iṣẹ́ iwaasu ìyìn rere ni ó fi rán mi, kì í sìí ṣe nípa ọ̀rọ̀ ọgbọ́n, kí agbelebu Kristi má baà di òfo.


Ọkunrin kinni tí a fi erùpẹ̀ dá jẹ́ erùpẹ̀, láti ọ̀run ni ọkunrin keji ti wá.


Kò sí ọ̀kan ninu àwọn aláṣẹ ayé yìí tí ó mọ àṣírí yìí, nítorí tí ó bá jẹ́ pé wọ́n mọ̀ ọ́n ni, wọn kì bá tí kan Oluwa tí ó lógo mọ́ agbelebu.


Nítorí kì í ṣe nípa ara wa ni à ń waasu. Ẹni tí à ń waasu rẹ̀ ni Jesu Kristi pé òun ni Oluwa. Iranṣẹ yín ni a jẹ́, nítorí ti Kristi.


Ẹ̀yin ará mi, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní igbagbọ ninu Oluwa wa, Jesu Kristi, Oluwa tí ó lógo, ẹ má máa ṣe ojuṣaaju.


A kọ orúkọ kan sára ẹ̀wù ati sí itan rẹ̀ pé: “Ọba àwọn ọba ati Oluwa àwọn olúwa.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan