Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 3:27 - Yoruba Bible

27 Johanu fèsì pé, “Kò sí ẹni tí ó lè rí ohunkohun gbà àfi ohun tí Ọlọrun bá fún un.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

27 Johanu dahùn o si wipe, Enia ko le ri nkankan gbà, bikoṣepe a ba ti fifun u lati ọrun wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

27 Johanu dáhùn ó sì wí pé, “Ènìyàn kò le rí nǹkan kan gbà, bí kò ṣe pé a bá ti fi fún ún láti ọ̀run wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 3:27
27 Iomraidhean Croise  

“Kí n tó dá ọ sinu ìyá rẹ ni mo ti mọ̀ ọ́, kí wọ́n sì tó bí ọ ni mo ti yà ọ́ sọ́tọ̀, mo yàn ọ́ ní wolii fún àwọn orílẹ̀-èdè.”


N kò bẹ̀bẹ̀ pé kí o rán ibi sí wọn, bẹ́ẹ̀ ni n kò fẹ́ ọjọ́ ibi fún wọn. OLUWA, o mọ̀ bẹ́ẹ̀. Ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu mi jáde kò tún lè ṣàjèjì sí ọ.


OLUWA ló pè mí níbi iṣẹ́ mi, òun ló ní kí n lọ máa sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún Israẹli, eniyan òun.


Ọ̀pá ẹni tí mo bá yàn yóo rúwé; bẹ́ẹ̀ ni n óo ṣe fi òpin sí kíkùn tí àwọn ọmọ Israẹli ń kùn sí ọ.”


Ìrìbọmi tí Johanu ń ṣe, báwo ló ti jẹ́: ṣé láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá ni tabi láti ọ̀dọ̀ eniyan?” Wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí bá ara wọn jiyàn, wọ́n ń wí pé, “Bí a bá sọ pé, ‘Láti ọ̀run ni,’ yóo bi wá pé, ‘Kí ló dé tí ẹ kò fi gbà á gbọ́?’


Ó fún ọ̀kan ni àpò owó marun-un, ó fún ekeji ní àpò meji, ó fún ẹkẹta ní àpò kan. Ó fún ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn bí agbára rẹ̀ ti tó; ó bá lọ sí ìdálẹ̀.


Ó dàbí kí ọkunrin kan máa lọ sí ìdálẹ̀, kí ó fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, kí ó fi àṣẹ fún àwọn iranṣẹ rẹ̀, kí ó fi iṣẹ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan fún un, kí ó wá pàṣẹ fún olùṣọ́nà pé kí ó ṣọ́nà.


Ọpọlọpọ eniyan lọ sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń sọ pé, “Johanu kò ṣe iṣẹ́ ìyanu kankan, ṣugbọn gbogbo ohun tí ó sọ nípa ọkunrin yìí ni ó rí bẹ́ẹ̀.”


Ó ní, “Nítorí èyí ni mo ṣe sọ fun yín pé kò sí ẹni tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi, àfi bí Baba mi bá ṣí ọ̀nà fún un láti wá.”


nípa ẹni tí a ti rí oore-ọ̀fẹ́ gbà, tí a sì gba iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní orúkọ rẹ̀, pé kí gbogbo eniyan lè gba Jesu gbọ́, kí wọ́n sì gbọ́ràn sí i lẹ́nu.


Bí a ti ní oríṣìíríṣìí ẹ̀bùn gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun ti pín oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí á lò wọ́n. Bí ẹnìkan bá ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, kí ó lò ó gẹ́gẹ́ bí igbagbọ rẹ̀ ti mọ.


Èmi Paulu, tí Ọlọrun pè láti jẹ́ òjíṣẹ́ Kristi Jesu, ati Sositene arakunrin wa ni à ń kọ ìwé yìí–


Ọ̀dọ̀ Ẹ̀mí kan ṣoṣo ni gbogbo ẹ̀bùn wọnyi ti wá; bí ó sì ti wù ú ni ó pín wọn fún ẹnìkọ̀ọ̀kan.


Ṣugbọn nípa oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun ni mo jẹ́ ohun tí mo jẹ́. Oore-ọ̀fẹ́ yìí kò sì jẹ́ lásán lórí mí, nítorí mo ṣe akitiyan ju gbogbo àwọn aposteli yòókù lọ. Ṣugbọn kì í ṣe èmi tìkara mi, oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun tí ó wà pẹlu mi ni.


Nítorí ta ni Apolo? Ta ni Paulu? Ṣebí iranṣẹ ni wọ́n, tí ẹ ti ipasẹ̀ wọn di onigbagbọ? Olukuluku wọn jẹ́ iṣẹ́ tirẹ̀ bí Ọlọrun ti rán an.


Ta ni ó gbe yín ga ju ẹlòmíràn lọ? Kí ni ohun tí ẹ dá ní, tí kò jẹ́ pé ọwọ́ Ọlọrun ni ẹ ti rí i gbà? Kí wá ni ìdí ìgbéraga yín bí ẹni pé ẹ̀yin ni ẹ dá a ní?


Èmi Paulu, kì í ṣe eniyan ni ó pè mí láti jẹ́ aposteli, n kò sì ti ọ̀dọ̀ eniyan gba ìpè, Jesu Kristi ati Ọlọrun Baba, tí ó jí Jesu dìde, ni ó pè mí.


Èmi Paulu, aposteli Kristi Jesu nípa ìfẹ́ Ọlọrun, ni mò ń kọ ìwé yìí sí àwọn eniyan Ọlọrun tí ó wà ní Efesu, àwọn tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ sí Kristi Jesu.


Òtítọ́ ni mò ń sọ, n kò purọ́, pé ohun tí a yàn mí láti jẹ́ akéde ati aposteli sí ni pé kí n jẹ́ olùkọ́ni fún àwọn tí kì í ṣe Juu nípa nǹkan tí ó jẹ mọ́ igbagbọ ati òtítọ́ Ọlọrun.


Láti òkè ni gbogbo ẹ̀bùn rere ati gbogbo ẹ̀bùn pípé ti ń wá, a máa wá láti ọ̀dọ̀ Baba tí ó dá ìmọ́lẹ̀, baba tí kì í yí pada, tí irú òjìji tíí máa wà ninu ìṣípò pada kò sì sí ninu rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan