Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 3:20 - Yoruba Bible

20 Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń ṣe burúkú a máa kórìíra ìmọ́lẹ̀; kò jẹ́ wá sí ibi tí ìmọ́lẹ̀ bá wà, kí eniyan má baà bá a wí nítorí iṣẹ́ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

20 Nitori olukuluku ẹniti o ba hùwa buburu ni ikorira imọlẹ, ki isi wá si imọlẹ, ki a máṣe ba iṣẹ rẹ̀ wí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

20 Nítorí olúkúlùkù ẹni tí ó bá hùwà búburú ní ìkórìíra ìmọ́lẹ̀, kì í sì í wá sí ìmọ́lẹ̀, kí a má ṣe bá iṣẹ́ rẹ̀ wí.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 3:20
18 Iomraidhean Croise  

ó sì dà á sinu àwo kan, ó gbé e fún un. Ṣugbọn Amnoni kọ̀, kò jẹ ẹ́, ó ní kí ó sọ fún gbogbo àwọn tí wọ́n wà ninu ilé kí wọ́n jáde, gbogbo wọn bá jáde.


Ahabu dá a lóhùn pé, “Ẹnìkan tí ó kù, tí ó tún lè bá wa wádìí lọ́dọ̀ OLUWA ni Mikaaya ọmọ Imila, ṣugbọn mo kórìíra rẹ̀; nítorí pé kò sọ àsọtẹ́lẹ̀ rere nípa mi rí, àfi burúkú.” Jehoṣafati dá a lóhùn pé, “Kabiyesi, má wí bẹ́ẹ̀.”


Ó bá dìde ní ọ̀gànjọ́ òru, ó wá jí ọmọ tèmi gbé ní ẹ̀gbẹ́ mi nígbà tí mo sùn lọ, ó tẹ́ ẹ sí ọ̀dọ̀ ara rẹ̀, ó sì tẹ́ òkú ọmọ tirẹ̀ sọ́dọ̀ mi.


Nítorí ẹ kórìíra ẹ̀kọ́; ẹ sì ti ta àṣẹ mi nù.


Nítorí pé ẹ kórìíra ìmọ̀, ẹ kò sì bẹ̀rù OLUWA.


Inú pẹ̀gànpẹ̀gàn kì í dùn sí ìbáwí, kì í bèèrè ìmọ̀ràn lọ́wọ́ ọlọ́gbọ́n.


Ẹni tí ó bá ń ṣẹ́jú sí ni, ète ibi ló fẹ́ pa, ẹni tí ó bá ń fúnnu pọ̀ sọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ burúkú ni yóo sọ jáde.


àwọn tí wọ́n ti kọ ọ̀nà òdodo sílẹ̀ tí wọn sì ń rìn ninu òkùnkùn;


Ṣugbọn ọ̀nà olódodo dàbí ìmọ́lẹ̀ àfẹ̀mọ́júmọ́, tí ń mọ́lẹ̀ sí i láti ìdájí títí tí ilẹ̀ yóo fi mọ́ kedere.


nígbà náà ni o óo wí pé, “Kí ló dé tí mo kórìíra ìtọ́ni, tí ọkàn mi sì kẹ́gàn ìbáwí!


Ìninilára ń gorí ìninilára, ẹ̀tàn ń gorí ẹ̀tàn, OLUWA ní, “Wọ́n kọ̀ wọn kò mọ̀ mí.”


Ọ̀kan ninu àwọn amòfin sọ fún un pé, “Olùkọ́ni, nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ báyìí, ò ń fi àbùkù kan àwa náà!”


Ṣugbọn ẹni tí ó bá ń hùwà òtítọ́ á máa wá sí ibi ìmọ́lẹ̀, kí iṣẹ́ rẹ̀ lè hàn pé agbára Ọlọrun ni ó fi ń ṣe wọ́n.


Ayé kò lè kórìíra yín, èmi ni wọ́n kórìíra, nítorí ẹ̀rí mi lòdì sí wọn nítorí pé iṣẹ́ wọn burú.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan