Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 3:2 - Yoruba Bible

2 Ọkunrin yìí fi òru bojú lọ sọ́dọ̀ Jesu. Ó wí fún un pé, “Rabi, a mọ̀ pé olùkọ́ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá ni ọ́, nítorí kò sí ẹni tí ó lè ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu tí ò ń ṣe wọnyi àfi ẹni tí Ọlọrun bá wà pẹlu rẹ̀.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 On na li o tọ̀ Jesu wá li oru, o si wi fun u pe, Rabbi, awa mọ̀ pe olukọni lati ọdọ Ọlọrun wá ni iwọ iṣe: nitoripe kò si ẹniti o le ṣe iṣẹ àmi wọnyi ti iwọ nṣe, bikoṣepe Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Òun náà ní ó tọ Jesu wá ní òru, ó sì wí fún un pé, Rabbi, àwa mọ̀ pé olùkọ́ni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá ni ìwọ ń ṣe: nítorí pé kò sí ẹni tí ó lè ṣe iṣẹ́ ààmì wọ̀nyí tí ìwọ ń ṣe, bí kò ṣe pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 3:2
30 Iomraidhean Croise  

Obinrin náà sọ fún Elija pé, “Mo mọ̀ nisinsinyii pé eniyan Ọlọrun ni ọ́, ati pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ OLUWA tí ń ti ẹnu rẹ jáde.”


“Ẹ̀yin tí ẹ mọ òdodo, ẹ gbọ́ ohùn mi, ẹ̀yin tí ẹ fi tọkàntọkàn gba òfin mi, ẹ má bẹ̀rù ẹ̀gàn àwọn eniyan; ẹ má sì jẹ́ kí yẹ̀yẹ́ wọn já a yín láyà.


Sedekaya ọba bá búra fún Jeremaya ní ìkọ̀kọ̀ pé, “Mo fi OLUWA alààyè ẹni tí ó dá ẹ̀mí wa búra, pé n kò ní pa ọ́, n kò sì ní fi ọ́ lé àwọn tí wọn ń wá ọ̀nà láti pa ọ́ lọ́wọ́.”


Wọ́n bá rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wọn pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Hẹrọdu láti bi í pé, “Olùkọ́ni, a mọ̀ pé olóòótọ́ ni ọ́, ati pé pẹlu òtítọ́ ni o fi ń kọ́ eniyan ní ọ̀nà Ọlọrun; o kì í ṣe ojuṣaaju fún ẹnikẹ́ni nítorí o kì í wojú eniyan kí o tó sọ̀rọ̀.


Wọ́n fẹ́ràn kí eniyan máa kí wọn láàrin ọjà ati kí àwọn eniyan máa pè wọ́n ní ‘Olùkọ́ni.’


Ṣugbọn ẹ̀yin ní tiyín, ẹ má jẹ́ kí wọ́n pè yín ní ‘Olùkọ́ni,’ nítorí ẹnìkan ṣoṣo ni olùkọ́ni yín; arakunrin ni gbogbo yín jẹ́.


Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Olùkọ́ni, sọ fún wa, ṣé ó tọ̀nà pé kí á máa san owó-orí fún Kesari ni, àbí kò tọ̀nà?”


Nígbà tí Jesu yipada, tí ó rí wọn tí wọn ń tẹ̀lé òun, ó bi wọn pé, “Kí ni ẹ̀ ń wá?” Wọ́n ní, “Rabi, níbo ni ò ń gbé?” (Ìtumọ̀ “Rabi” ni “Olùkọ́ni.”)


Ṣugbọn bí mo bá ń ṣe é, èmi kọ́ ni kí ẹ gbàgbọ́, àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe ni kí ẹ gbàgbọ́. Èyí yóo jẹ́ kí ẹ wòye, kí ẹ wá mọ̀ pé Baba wà ninu mi, ati pé èmi náà wà ninu Baba.”


Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Jesu ti ṣe ọpọlọpọ iṣẹ́ ìyanu lójú wọn, sibẹ wọn kò gbà á gbọ́.


Àbí o kò gbàgbọ́ pé mo wà ninu Baba ati pé Baba wà ninu mi ni? Èmi fúnra mi kọ́ ni mò ń sọ ọ̀rọ̀ tí mò ń sọ fun yín. Baba tí ó ń gbé inú mi ni ó ń ṣe iṣẹ́ rẹ̀.


Bí n kò bá ṣe irú iṣẹ́ tí ẹnikẹ́ni kò ṣe rí, wọn kì bá tí ní ẹ̀ṣẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, wọ́n ti rí àwọn iṣẹ́ mi, sibẹ wọ́n kórìíra èmi ati Baba mi.


Èyí ni ìbẹ̀rẹ̀ àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jesu ṣe ní Kana ti Galili. Èyí gbé ògo rẹ̀ yọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì gbà á gbọ́.


Jesu bá pè é lórúkọ, ó ní, “Maria!” Maria bá yipada sí i, ó pè é ní èdè Heberu pé, “Raboni!” (Ìtumọ̀ èyí ni “Olùkọ́ni.”)


Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn náà bá lọ sọ́dọ̀ Johanu, wọ́n wí fún un pé, “Olùkọ́ni, ọkunrin tí ó wà pẹlu rẹ ní òdìkejì odò Jọdani, tí o jẹ́rìí nípa rẹ̀, ń ṣe ìrìbọmi, gbogbo eniyan sì ń tọ̀ ọ́ lọ.”


Lẹ́yìn tí obinrin náà ti lọ sí ààrin ìlú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ń bẹ̀ ẹ́ pé, “Rabi, jẹun.”


Ṣugbọn mo ní ẹ̀rí tí ó tóbi ju ti Johanu lọ. Àwọn iṣẹ́ tí Baba ti fún mi pé kí n parí, àní àwọn iṣẹ́ tí mò ń ṣe, àwọn ni ẹlẹ́rìí mi pé Baba ni ó rán mi níṣẹ́.


Ọ̀pọ̀ eniyan ń tẹ̀lé e nítorí wọ́n rí iṣẹ́ ìyanu tí ó ń ṣe lára àwọn aláìsàn.


Ọpọlọpọ ninu àwọn eniyan gbà á gbọ́, wọ́n ń sọ pé, “Bí Mesaya náà bá dé, ǹjẹ́ yóo ṣe iṣẹ́ ìyanu ju èyí tí ọkunrin yìí ń ṣe lọ?”


Àwọn kan ninu àwọn Farisi ń sọ pé, “Ọkunrin yìí kò ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun wá, nítorí kò pa òfin Ọjọ́ Ìsinmi mọ́.” Ṣugbọn àwọn mìíràn ń sọ pé “Báwo ni ẹni tí ó jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ ṣe lè ṣe irú iṣẹ́ ìyanu yìí?” Ìyapa bá bẹ́ sáàrin wọn.


Ẹ mọ̀ nípa Jesu ará Nasarẹti, bí Ọlọrun ti ṣe yàn án, tí ó fún un ní Ẹ̀mí Mímọ́ ati agbára; bí ó ti ṣe ń lọ káàkiri tí ó ń ṣe rere, tí ó ń wo gbogbo àwọn tí Satani ti ń dá lóró sàn, nítorí Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀.


“Ẹ̀yin ará, ọmọ Israẹli, ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi. Jesu ará Nasarẹti ni ẹni tí Ọlọrun ti fihàn fun yín pẹlu iṣẹ́ agbára, iṣẹ́ ìyanu, iṣẹ́ abàmì tí Ọlọrun ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe láàrin yín. Ẹ̀yin fúnra yín sì mọ̀ bẹ́ẹ̀.


Èyí fún ọpọlọpọ ninu àwọn onigbagbọ tí wọ́n mọ ìdí tí mo fi wà ninu ẹ̀wọ̀n ní ìgboyà gidigidi láti máa waasu ìyìn rere láì bẹ̀rù.


Gideoni mú mẹ́wàá ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀, ó sì ṣe bí OLUWA ti ní kí ó ṣe, ṣugbọn kò lè ṣe é lọ́sàn-án, nítorí ẹ̀rù àwọn ará ilé ati àwọn ará ìlú rẹ̀ ń bà á, nítorí náà lóru ni ó ṣe é.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan