Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 3:19 - Yoruba Bible

19 Ìdálẹ́bi náà ni pé ìmọ́lẹ̀ ti dé sinu ayé, ṣugbọn aráyé fẹ́ràn òkùnkùn ju ìmọ́lẹ̀ lọ, nítorí iṣẹ́ wọn burú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

19 Eyi ni idajọ na pe, imọlẹ wá si aiye, awọn enia si fẹ òkunkun jù imọlẹ lọ, nitoriti iṣẹ wọn buru.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

19 Èyí ni ìdájọ́ náà pé, ìmọ́lẹ̀ wá sí ayé, àwọn ènìyàn sì fẹ́ òkùnkùn ju ìmọ́lẹ̀ lọ, nítorí tí iṣẹ́ wọn burú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 3:19
33 Iomraidhean Croise  

àwọn tí wọ́n ti kọ ọ̀nà òdodo sílẹ̀ tí wọn sì ń rìn ninu òkùnkùn;


Ìninilára ń gorí ìninilára, ẹ̀tàn ń gorí ẹ̀tàn, OLUWA ní, “Wọ́n kọ̀ wọn kò mọ̀ mí.”


ògòǹgò, ati ẹyẹ kan bí ẹ̀lulùú tí ń gbé aṣálẹ̀,


Kí alufaa yẹ̀ ẹ́ wò, bí ibìkan bá wú ní ara rẹ̀, tí ó funfun, tí ó sì sọ irun ọ̀gangan ibẹ̀ di funfun, bí ibi tí ó wú yìí bá di egbò,


Èyí ni ìyà tí yóo jẹ ilẹ̀ Ijipti ati gbogbo orílẹ̀-èdè tí kò bá wá síbi Àjọ Àgọ́.


“Ọmọ-ọ̀dọ̀ tí ó bá mọ ohun tí oluwa rẹ̀ fẹ́, ṣugbọn tí kò múra sílẹ̀, tí kò sì ṣe ìfẹ́ oluwa rẹ̀ yóo jìyà pupọ.


Nígbà tí àwọn Farisi tí wọ́n fẹ́ràn owó gbọ́ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí, ńṣe ni wọ́n ń yínmú sí i.


Òun ni orísun ìyè, ìyè náà ni ìmọ́lẹ̀ aráyé.


Ìmọ́lẹ̀ náà ń tàn ninu òkùnkùn, òkùnkùn kò sì lè borí rẹ̀.


Àkókò tó fún ìdájọ́ ayé yìí. Nisinsinyii ni a óo lé aláṣẹ ayé yìí jáde.


nítorí wọ́n fẹ́ràn ìyìn eniyan ju ìyìn Ọlọrun lọ.


Mo wá sinu ayé bí ìmọ́lẹ̀, kí ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́ má baà wà ninu òkùnkùn.


Báwo ni ẹ ti ṣe lè gbàgbọ́ nígbà tí ó jẹ́ pé láàrin ara yín ni ẹ ti ń gba ọlá, tí ẹ kò wá ọlá ti ọ̀dọ̀ Ọlọrun nìkan ṣoṣo?


Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọrun, olúwarẹ̀ yóo mọ̀ bí ẹ̀kọ́ yìí bá jẹ́ ti Ọlọrun, tabi bí ó bá jẹ́ pé ti ara mi ni mò ń sọ.


Ayé kò lè kórìíra yín, èmi ni wọ́n kórìíra, nítorí ẹ̀rí mi lòdì sí wọn nítorí pé iṣẹ́ wọn burú.


Jesu tún wí fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ẹni tí ó bá ń tẹ̀lé mi kò ní rìn ninu òkùnkùn, ṣugbọn yóo wá sinu ìmọ́lẹ̀ ìyè.”


Níwọ̀n ìgbà tí mo wà ní ayé, èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.”


Wọ́n mọ ìlànà ti Ọlọrun; wọ́n mọ̀ pé ikú ni ó tọ́ sí àwọn tí wọn bá ń hu irú ìwà wọnyi; sibẹ kì í ṣe pé wọ́n ń hu irú ìwà bẹ́ẹ̀ nìkan, wọ́n tún ń kan sáárá sí àwọn tí ń hùwà bẹ́ẹ̀.


Ṣugbọn ní ti àwọn tí ó jẹ́ pé ti ara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀, ati àwọn tí kò gba òtítọ́, àwọn tí wọ́n gba ohun burúkú, Ọlọrun yóo fi ibinu ati ìrúnú rẹ̀ hàn wọ́n;


kí gbogbo àwọn tí kò gba òtítọ́ gbọ́ lè gba ìdálẹ́bi, àní, àwọn tí wọ́n ní inú dídùn sí ìwà ibi.


Ati, “Òkúta tí yóo mú eniyan kọsẹ̀, ati àpáta tí yóo gbé eniyan ṣubú.” Àwọn tí ó ṣubú ni àwọn tí kò gba ọ̀rọ̀ náà gbọ́. Bẹ́ẹ̀, bí ti irú wọn ti níláti rí nìyí.


Ní àkọ́kọ́, kí ẹ mọ èyí pé ní ọjọ́ ìkẹyìn, àwọn tí wọn óo máa fi ẹ̀sìn ṣe ẹlẹ́yà yóo wá, tí wọn óo máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan