Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 3:10 - Yoruba Bible

10 Jesu ní, “Mo ṣebí olùkọ́ni olókìkí ní Israẹli ni ọ́, sibẹ o kò mọ nǹkan wọnyi?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Ṣe olukọni ni Israeli ni iwọ iṣe, o kò si mọ̀ nkan wọnyi?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Jesu dáhùn, ó sì wí fún un pé, “Ṣé olùkọ́ni ní Israẹli ni ìwọ ń ṣe, o kò sì mọ nǹkan wọ̀nyí?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 3:10
28 Iomraidhean Croise  

Jọ̀wọ́, jẹ́ kí Solomoni ọmọ mi, fi gbogbo ọkàn rẹ̀ pa òfin, àṣẹ ati ìlànà rẹ mọ́, kí ó lè ṣe ohun gbogbo, kí ó sì lè kọ́ tẹmpili tí mo ti múra rẹ̀ sílẹ̀ fún.”


Dá ọkàn mímọ́ sí inú mi, Ọlọrun, kí o sì fi ẹ̀mí ọ̀tun ati ẹ̀mí ìṣòótọ́ sí mi lọ́kàn.


O fẹ́ràn òtítọ́ inú; nítorí náà, kọ́ mi lọ́gbọ́n ní kọ́lọ́fín ọkàn mi.


Nítòótọ́ Ọlọrun ṣeun fún Israẹli, ó ṣeun fún àwọn tí ọkàn wọn mọ́.


Afọ́jú ni àwọn aṣọ́de Israẹli gbogbo wọn kò mọ nǹkankan. Ajá tí ó yadi ni wọ́n, wọn kò lè gbó; oorun ni wọ́n fẹ́ràn. Wọn á dùbúlẹ̀, wọn á máa lá àlá.


Àwọn tí ń darí àwọn eniyan wọnyi ń ṣì wọ́n lọ́nà ni, àwọn tí wọn ń tọ́ sọ́nà sì ń já sinu ìparun.


Ṣugbọn majẹmu tí n óo bá ilé Israẹli dá nígbà tó bá yá nìyí: N óo fi òfin mi sí inú wọn, n óo sì kọ wọ́n sí ọkàn wọn. N óo máa jẹ́ Ọlọrun wọn, wọn yóo sì máa jẹ́ eniyan mi.


Ó ní, mo sọ pé, n óo fún wọn ní ọkàn kan, n óo fi ẹ̀mí titun sí wọn ninu. N óo yọ ọkàn òkúta kúrò láyà wọn, n óo sì fún wọn ní ọkàn ẹran;


Nígbà náà ni Jesu sọ báyìí pé, “Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, Baba, Oluwa ọ̀run ati ayé, nítorí o ti pa nǹkan wọnyi mọ́ fún àwọn ọlọ́gbọ́n ati àwọn olóye, ṣugbọn o fi wọ́n han àwọn òpè.


Ẹ fi wọ́n sílẹ̀. Afọ́jú tí ó ń fọ̀nà hanni ni wọ́n. Bí afọ́jú bá ń fọ̀nà han afọ́jú, àwọn mejeeji yóo jìn sinu kòtò.”


Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ṣìnà, nítorí pé ẹ kò mọ Ìwé Mímọ́ ati agbára Ọlọrun.


Lẹ́yìn ọjọ́ mẹta, wọ́n rí i ninu Tẹmpili, ó jókòó láàrin àwọn olùkọ́ni, ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn, òun náà sì ń bi wọ́n ní ìbéèrè.


Ní ọjọ́ kan bí Jesu ti ń kọ́ àwọn eniyan, àwọn Farisi ati àwọn amòfin jókòó níbẹ̀. Wọ́n wá láti gbogbo ìletò Galili ati ti Judia ati láti Jerusalẹmu. Agbára Oluwa wà pẹlu Jesu láti fi ṣe ìwòsàn.


Nikodemu wá bi í pé, “Báwo ni nǹkan wọnyi ti ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?”


Ṣugbọn Farisi kan ninu àwọn ìgbìmọ̀ dìde. Orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gamalieli, olùkọ́ nípa ti òfin ni, ó lókìkí láàrin gbogbo àwọn eniyan. Ó ní kí àwọn ọkunrin náà jáde fún ìgbà díẹ̀.


Kì í ṣe nǹkan ti òde ara ni eniyan fi ń jẹ́ Juu, bẹ́ẹ̀ ni ìkọlà kì í ṣe kí á fabẹ gé ara.


Nítorí náà, ẹ gbọ́ràn sí Ọlọrun lẹ́nu, kí ẹ má sì ṣe oríkunkun mọ́.


OLUWA Ọlọrun yín yóo fún ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín ní ẹ̀mí ìgbọràn tí ó fi jẹ́ pé ẹ óo fẹ́ràn rẹ̀ tọkàntọkàn, ẹ óo sì wà láàyè.


Nítorí àwa gan-an ni ọ̀kọlà, àwa tí à ń sin Ọlọrun nípa Ẹ̀mí, tí à ń ṣògo ninu Kristi Jesu, tí a kò gbára lé nǹkan ti ara,


Ninu Kristi yìí ni a ti kọ yín nílà, kì í ṣe ilà tí a fi ọwọ́ kọ nípa gígé ẹran-ara kúrò, ṣugbọn ilà ti Kristi;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan