Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 21:7 - Yoruba Bible

7 Ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn sọ fún Peteru pé, “Oluwa ni!” Nígbà tí Simoni Peteru gbọ́ pé Oluwa ni, ó wọ ẹ̀wù rẹ̀, nítorí ó ti bọ́ra sílẹ̀ fún iṣẹ́, ó bá bẹ́ sinu òkun, ó ń lúwẹ̀ẹ́ lọ sébùúté.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Nitorina li ọmọ-ẹhin na ti Jesu fẹran wi fun Peteru pe, Oluwa ni. Nigbati Simoni Peteru gbọ́ pe Oluwa ni, bẹli o di amure ẹ̀wu rẹ̀ mọra, (nitori o wà ni ìhoho), o si gbé ara rẹ̀ sọ sinu okun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn náà tí Jesu fẹ́ràn wí fún Peteru pé, “Olúwa ni!” Nígbà tí Simoni Peteru gbọ́ pé Olúwa ni, bẹ́ẹ̀ ni ó di àmùrè ẹ̀wù rẹ̀ mọ́ra, nítorí tí ó wà ní ìhòhò, ó sì gbé ara rẹ̀ sọ sínú Òkun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 21:7
20 Iomraidhean Croise  

OLUWA ló ṣe èyí; ó sì jẹ́ ohun ìyanu lójú wa.


Ọ̀pọ̀ omi kò lè pa iná ìfẹ́, ìgbì omi kò sì lè tẹ̀ ẹ́ rì. Bí eniyan bá gbìyànjú láti fi gbogbo nǹkan ìní rẹ̀ ra ìfẹ́, ẹ̀tẹ́ ni yóo fi gbà.


Bí ẹnikẹ́ni bá bi yín pé, ‘Kí ló dé tí ẹ̀ ń tú u?’ Kí ẹ dáhùn pé, ‘Oluwa fẹ́ lò ó ni, lẹsẹkẹsẹ tí ó bá ti lò ó tán yóo dá a pada sibẹ.’ ”


“Ẹ wà ní ìmúrasílẹ̀, kí ẹ di ara yín ní àmùrè, kí àtùpà yín wà ní títàn.


Nítorí a bí Olùgbàlà fun yín lónìí, ní ìlú Dafidi, tíí ṣe Oluwa ati Mesaya.


Nítorí èyí, mo sọ fún ọ, a dárí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó pọ̀ jì í, nítorí ó ní ìfẹ́ pupọ. Ṣugbọn ẹni tí a bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ díẹ̀ jì, ìfẹ́ díẹ̀ ni yóo ní.”


Ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu, ẹni tí ó fẹ́ràn, jókòó níbi oúnjẹ, ó súnmọ́ Jesu pẹ́kípẹ́kí.


Nígbà tí Jesu rí ìyá rẹ̀ ati ọmọ-ẹ̀yìn tí ó fẹ́ràn tí wọ́n dúró, ó wí fún ìyá rẹ̀ pé, “Obinrin, wo ọmọ rẹ.”


Ó bá sáré lọ sọ́dọ̀ Simoni Peteru ati ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn, ó sọ fún wọn pé, “Wọ́n ti gbé Oluwa kúrò ninu ibojì, a kò sì mọ ibi tí wọ́n tẹ́ ẹ sí.”


Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, ó fi ọwọ́ rẹ̀ ati ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ hàn wọ́n.


Tomasi dá a lóhùn pé, “Oluwa mi ati Ọlọrun mi!”


Nígbà tí Peteru bojú wẹ̀yìn, ó rí ọmọ-ẹ̀yìn tí Jesu fẹ́ràn tí ó ń tẹ̀lé e. Òun ni ó súnmọ́ Jesu pẹ́kípẹ́kí nígbà tí wọn ń jẹun, tí ó bi Jesu pé, “Oluwa, ta ni yóo fi ọ́ lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ rí?”


Ọmọ-ẹ̀yìn náà ni ó jẹ́rìí sí nǹkan wọnyi. Òun ni ó kọ nǹkan wọnyi: a mọ̀ pé òtítọ́ ni ẹ̀rí rẹ̀.


Ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yòókù ń bọ̀ ninu ọkọ̀, nítorí wọn kò jìnnà sí èbúté, wọn kò jù bí ìwọ̀n ọgọrun-un ìgbésẹ̀ lọ.


Ẹ mọ iṣẹ́ tí ó rán sí àwọn ọmọ Israẹli, ọ̀rọ̀ ìyìn rere alaafia nípasẹ̀ Jesu Kristi, ẹni tíí ṣe Oluwa gbogbo eniyan.


“Nítorí náà kí gbogbo ilé Israẹli mọ̀ dájú pé Jesu yìí tí ẹ̀yin kàn mọ́ agbelebu ni Ọlọrun ti fi ṣe Oluwa ati Mesaya!”


Ọkunrin kinni tí a fi erùpẹ̀ dá jẹ́ erùpẹ̀, láti ọ̀run ni ọkunrin keji ti wá.


nítorí ìfẹ́ Kristi ni ó ń darí wa, nígbà tí a ti mọ̀ pé ẹnìkan ti kú fún gbogbo eniyan, a mọ̀ pé ikú gbogbo eniyan ni ó gbà kú.


Ẹ̀yin ará mi, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní igbagbọ ninu Oluwa wa, Jesu Kristi, Oluwa tí ó lógo, ẹ má máa ṣe ojuṣaaju.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan