Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 21:5 - Yoruba Bible

5 Jesu bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin ọmọde, ǹjẹ́ ẹ ní ohunkohun fún jíjẹ?” Wọ́n bá dá a lóhùn pé, “Rárá o!”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Nitorina Jesu wi fun wọn pe, Ẹnyin ọmọde, ẹ li onjẹ diẹ bi? Nwọn da a lohùn wipe, Rára o.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Jesu wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ọmọdé, ẹ ní ẹja díẹ̀ bí?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá o.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 21:5
10 Iomraidhean Croise  

Ó wò yíká, ó sì rí ìṣù àkàrà kan, ati ìkòkò omi kan lẹ́bàá ìgbèrí rẹ̀. Ó jẹun, ó mu omi, ó sì tún dùbúlẹ̀.


Gbẹ́kẹ̀lé OLUWA; kí o sì máa ṣe rere. Máa gbe ilẹ̀ náà; ewu kò sì ní wu ọ́.


Nígbà tí ó di ìrọ̀lẹ́, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ tọ̀ ọ́ wá, wọ́n ní, “Aṣálẹ̀ ni ibí yìí, ọjọ́ sì ti lọ. Fi àwọn eniyan wọnyi sílẹ̀ kí wọ́n lè lọ ra oúnjẹ fún ara wọn ninu àwọn ìletò.”


Wọ́n tún ní àwọn ẹja kéékèèké díẹ̀. Ó gbadura sí i, ó ní kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pín in fún àwọn eniyan.


Ọlọrun mi yóo pèsè fún gbogbo àìní ẹ̀yin náà, gẹ́gẹ́ bí ọpọlọpọ ọrọ̀ rẹ̀ tí ó lógo nípasẹ̀ Jesu Kristi.


Ẹ má jẹ́ kí ìfẹ́ owó gbà yín lọ́kàn. Ẹ ní ìtẹ́lọ́rùn pẹlu ohun tí ẹ ní. Nítorí Ọlọrun fúnrarẹ̀ ti sọ pé, “N kò ní fi ọ́ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni n kò ní kọ̀ ọ́!”


Ẹ̀yin baba, mò ń kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ ti mọ ẹni tí ó wà láti ìṣẹ̀dálẹ̀ ayé. Ẹ̀yin ọdọmọkunrin, mò ń kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ ti ṣẹgun Èṣù. Ẹ̀yin ọmọde, mo kọ ìwé si yín, nítorí pé ẹ ti mọ Baba.


Ẹ̀yin ọmọde, àkókò ìkẹyìn nìyí! Gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gbọ́ pé Alátakò Kristi ń bọ̀, nisinsinyii ọpọlọpọ àwọn alátakò Kristi ti ń yọjú. Èyí ni a fi mọ̀ pé àkókò ìkẹyìn nìyí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan