Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 21:3 - Yoruba Bible

3 Simoni Peteru sọ fún wọn pé, “Mò ń lọ pa ẹja.” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Àwa náà yóo bá ọ lọ.” Wọ́n bá jáde lọ, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi. Ní gbogbo alẹ́ ọjọ́ náà wọn kò rí ẹja kankan pa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

3 Simoni Peteru wi fun wọn pe, Emi nlọ ipẹja. Nwọn wi fun u pe, Awa pẹlu mba ọ lọ. Nwọn jade, nwọn si wọ̀ inú ọkọ̀; li oru na nwọn kò si mú ohunkohun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Simoni Peteru wí fún wọn pé, “Èmi ń lọ pẹja!” Wọ́n wí fún un pé, “Àwa pẹ̀lú ń bá ọ lọ.” Wọ́n jáde, wọ́n sì wọ inú ọkọ̀ ojú omi; ní òru náà wọn kò sì mú ohunkóhun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 21:3
11 Iomraidhean Croise  

Simoni dáhùn pé, “Alàgbà, gbogbo òru ni a fi ṣiṣẹ́ láì rí ohunkohun pa, ṣugbọn nítorí ọ̀rọ̀ rẹ, n óo da àwọ̀n sí omi.”


Nígbà tí ó di àfẹ̀mọ́jú Jesu dúró ní èbúté, ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kò mọ̀ pé Jesu ni.


Nítorí pé iṣẹ́ kan náà ni wọ́n ń ṣe, Paulu lọ wọ̀ lọ́dọ̀ wọn, ó sì ń ṣiṣẹ́. Iṣẹ́ ọnà awọ tí wọ́n fi ń ṣe àgọ́ ni wọ́n ń ṣe.


Ẹ̀yin fúnra yín mọ̀ pé ọwọ́ ara mi yìí ni mo fi ṣiṣẹ́ tí mo fi ń gbọ́ bùkátà mi ati ti àwọn ẹlẹgbẹ́ mi.


Nítorí èyí, kì í ṣe ẹni tí ń gbin nǹkan, tabi ẹni tí ń bomi rin ín ni ó ṣe pataki, bíkòṣe Ọlọrun tí ó ń mú un dàgbà.


Àbí èmi ati Banaba nìkan ni a níláti máa ṣiṣẹ́ bọ́ ara wa?


Ará, ẹ ranti ìṣòro ati làálàá wa, pé tọ̀sán-tòru ni à ń ṣiṣẹ́ láti gbọ́ bùkátà ara wa, kí á má baà ni ẹnikẹ́ni ninu yín lára nígbà tí à ń waasu ìyìn rere Ọlọrun fun yín.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan