Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 21:23 - Yoruba Bible

23 Nígbà tí gbolohun yìí dé etí àwọn onigbagbọ, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí sọ pé ọmọ-ẹ̀yìn náà kò ní kú. Ṣugbọn kò sọ fún un pé kò ní kú. Ohun tí ó wí ni pé, “Bí mo bá fẹ́ kí ó wà títí n óo fi dé, èwo ni ó kàn ọ́?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

23 Nitorina ọ̀rọ yi si tàn ka lãrin awọn arakunrin pe, ọmọ-ẹhin nì kì yio kú: ṣugbọn Jesu kò wi fun u pe, On kì yio kú; ṣugbọn, Bi emi ba fẹ ki o duro titi emi o fi de, kili eyinì si ọ?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

23 Ọ̀rọ̀ yìí sì tàn ká láàrín àwọn arákùnrin pé, ọmọ-ẹ̀yìn náà kì yóò kú: ṣùgbọ́n Jesu kò wí fún un pé, òun kì yóò kú; ṣùgbọ́n, “Bí èmi bá fẹ́ kí ó dúró títí èmi ó fi dé, kín ni èyí jẹ́ sí ọ?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 21:23
12 Iomraidhean Croise  

Nígbà náà ni ó sọ fún eniyan pé, ‘Wò ó, ìbẹ̀rù OLUWA ni ọgbọ́n, kí á yẹra fún ibi sì ni ìmọ̀.’ ”


Kí ló dé tí ò ń fi ẹ̀sùn kàn án pé kò ní fèsì kankan sí ọ̀rọ̀ rẹ?


Gbogbo aráyé kò jámọ́ nǹkankan lójú rẹ̀; a sì máa ṣe bí ó ti wù ú láàrin àwọn aráyé ati láàrin àwọn ogun ọ̀run. Kò sí ẹni tí ó lè ká a lọ́wọ́ kò, tabi tí ó lè yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò.


Nítorí Ọmọ-Eniyan yóo wá ninu ògo Baba rẹ̀ pẹlu àwọn angẹli rẹ̀, yóo wá fi èrè fún ẹnìkọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.


Ní ọjọ́ kan, Peteru dìde láàrin àwọn arakunrin tí wọ́n tó ọgọfa eniyan, ó ní,


A rí àwọn onigbagbọ níbẹ̀. Wọ́n rọ̀ wá kí á dúró lọ́dọ̀ wọn, a bá ṣe ọ̀sẹ̀ kan níbẹ̀. Báyìí ni a ṣe dé Romu.


Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ wá ẹni meje láàrin yín, tí wọ́n ní orúkọ rere, tí wọ́n kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ ati ọgbọ́n, kí á yàn wọ́n láti mójútó ètò yìí.


Nítorí nígbàkúùgbà tí ẹ bá ń jẹ burẹdi yìí, tí ẹ sì ń mu ninu ife yìí, ẹ̀ ń kéde ikú Oluwa títí yóo fi dé.


Nítorí náà, kí ẹnikẹ́ni má ṣe ìdájọ́ kí àkókò rẹ̀ tó tó, nígbà tí Oluwa yóo dé, tí yóo tan ìmọ́lẹ̀ sí ohun gbogbo tí ó fara pamọ́ sinu òkùnkùn, tí yóo mú kí gbogbo èrò ọkàn eniyan farahàn kedere. Nígbà náà ni olukuluku yóo gba iyìn tí ó yẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.


“Àwọn nǹkan àṣírí mìíràn wà, tí kò hàn sí eniyan àfi OLUWA Ọlọrun wa nìkan, ṣugbọn àwọn nǹkan tí ó fihàn wá jẹ́ tiwa ati ti àwọn ọmọ wa títí lae, kí á lè máa ṣe àwọn nǹkan tí ó wà ninu ìwé òfin yìí.


Ẹ̀yin ará, ẹ mú sùúrù títí Oluwa yóo fi dé. Ẹ wo àgbẹ̀ tí ó ń retí èso tí ó dára ninu oko, ó níláti mú sùúrù fún òjò àkọ́rọ̀ ati òjò àrọ̀kẹ́yìn.


Ṣugbọn ṣá, ẹ di ohun tí ẹ ní mú ṣinṣin títí n óo fi dé.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan