Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 21:14 - Yoruba Bible

14 Èyí ni ó di ìgbà kẹta tí Jesu fara han àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lẹ́yìn ajinde rẹ̀ ninu òkú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

14 Eyi ni igba kẹta nisisiyi ti Jesu farahàn awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, lẹhin igbati o jinde kuro ninu okú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

14 Èyí ni Ìgbà kẹta nísinsin yìí tí Jesu farahan àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lẹ́yìn ìgbà tí ó jíǹde kúrò nínú òkú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 21:14
6 Iomraidhean Croise  

Lẹ́yìn ọjọ́ mẹjọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tún wà ninu ilé, Tomasi náà wà láàrin wọn. Ìlẹ̀kùn wà ní títì bẹ́ẹ̀ ni Jesu bá tún dé, ó dúró láàrin wọn, ó ní, “Alaafia fun yín!”


Nígbà tí ó di alẹ́ ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, níbi tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wà, tí wọ́n ti ìlẹ̀kùn mọ́rí nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Juu, Jesu dé, ó dúró láàrin wọn. Ó kí wọn pé, “Alaafia fun yín!”


Lẹ́yìn náà, ó fara han àwọn meji kan ninu wọn ní ọ̀nà mìíràn, bí wọ́n ti ń rìn lọ sí ìgbèríko kan.


Lẹ́yìn náà ó fara han àwọn mọkanla bí wọ́n ti ń jẹun. Ó bá wọn wí fún aigbagbọ ati ọkàn líle wọn, nítorí wọn kò gba àwọn tí wọ́n rí i, tí wọ́n sọ pé ó ti jinde gbọ́.


Lẹ́yìn èyí, Jesu tún fara han àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ní òkun Tiberiasi. Bí ó ṣe farahàn wọ́n nìyí:


Àwọn aposteli yìí ni ó fi ara rẹ̀ hàn láàyè lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀ pẹlu ẹ̀rí tí ó dájú. Wọ́n rí i níwọ̀n ogoji ọjọ́, ó sì ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tí ó jẹ mọ́ ti ìjọba Ọlọrun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan