Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 20:9 - Yoruba Bible

9 (Nítorí ohun tí Ìwé Mímọ́ wí kò tíì yé wọn pé dandan ni kí ó jí dìde ninu òkú.)

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Nitoripe nwọn kò sá ti imọ̀ iwe-mimọ́ pe, on kò le ṣaima jinde kuro ninu okú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 (Nítorí tí wọn kò sá à tí mọ ìwé mímọ́ pé, Jesu ní láti jíǹde kúrò nínú òkú.)

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 20:9
22 Iomraidhean Croise  

Nítorí o kò ní gbàgbé mi sí ipò òkú, bẹ́ẹ̀ ni o kò ní jẹ́ kí ẹni tí ó fi tọkàntọkàn sìn ọ́ rí ìdíbàjẹ́.


Okun inú mi ti gbẹ bí àpáàdì, ahọ́n mi sì ti lẹ̀ mọ́ mi lẹ́nu; o ti fi mí sílẹ̀ sinu eruku isà òkú.


Yóo gbé ikú mì títí lae, OLUWA yóo nu omijé nù kúrò lójú gbogbo eniyan. Yóo mú ẹ̀gàn àwọn eniyan rẹ̀ kúrò, ní gbogbo ilẹ̀ ayé. OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.


Àwọn òkú wa yóo jí, wọn óo dìde kúrò ninu ibojì. Ẹ tají kí ẹ máa kọrin, ẹ̀yin tí ó sùn ninu erùpẹ̀. Nítorí pé ìrì ìmọ́lẹ̀ ni ìrì yín, ẹ óo sì sẹ ìrì náà sì ilẹ̀ àwọn òkú.


N kò ní rà wọ́n pada kúrò lọ́wọ́ agbára isà òkú, n kò ní rà wọ́n pada kúrò lọ́wọ́ ikú. Ikú! Níbo ni àjàkálẹ̀ àrùn rẹ wà? Ìwọ isà òkú! Ìparun rẹ dà? Àánú kò sí lójú mi mọ́.


Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ṣìnà, nítorí pé ẹ kò mọ Ìwé Mímọ́ ati agbára Ọlọrun.


Dandan ni pé kí Mesaya jìyà, kí ó tó bọ́ sinu ògo rẹ̀.”


Ṣugbọn gbolohun yìí kò yé wọn, nítorí a ti fi ìtumọ̀ rẹ̀ pamọ́ fún wọn, kí ó má baà yé wọn. Ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti bi í nípa ọ̀rọ̀ yìí.


Nítorí náà, nígbà tí a ti jí i dìde kúrò ninu òkú, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ranti pé ó ti sọ èyí fún wọn, wọ́n wá gba Ìwé Mímọ́ gbọ́ ati ọ̀rọ̀ tí Jesu ti sọ.


Ó ń ṣe àlàyé fún wọn, ó tún ń tọ́ka sí àkọsílẹ̀ inú Ìwé Mímọ́ láti fihàn pé dandan ni kí Mesaya jìyà, kí ó jinde kúrò ninu òkú. Lẹ́yìn náà ó sọ fún wọn pé, Mesaya yìí náà ni Jesu tí òun ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún wọn.


Ṣugbọn Ọlọrun tú ìdè ikú, ó jí i dìde ninu òkú! Kò jẹ́ kí ikú ní agbára lórí rẹ̀.


Ati pé a sin ín, a sì jí i dìde ní ọjọ́ kẹta, gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti wí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan