Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 20:1 - Yoruba Bible

1 Ní kutukutu ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, kí ilẹ̀ tó mọ́, Maria Magidaleni lọ sí ibojì náà, ó rí i pé wọ́n ti yí òkúta kúrò lẹ́nu rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 LI ọjọ ikini ọ̀sẹ ni kùtùkùtù nigbati ilẹ kò ti imọ́, ni Maria Magdalene wá si ibojì, o si ri pe, a ti gbé okuta kuro li ẹnu ibojì.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ní kùtùkùtù ọjọ́ kìn-ín-ní ọ̀sẹ̀, nígbà tí ilẹ̀ kò tí ì mọ́, ni Maria Magdalene wá sí ibojì, ó sì rí i pé, a ti gbé òkúta kúrò lẹ́nu ibojì.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 20:1
19 Iomraidhean Croise  

Maria Magidaleni wà lára wọn, ati Maria ìyá Jakọbu ati ti Josẹfu ati ìyá àwọn ọmọ Sebede.


Ó tẹ́ ẹ sí inú ibojì rẹ̀ titun tí òun tìkalárarẹ̀ ti gbẹ́ sí inú àpáta. Ó yí òkúta ńlá kan dí ẹnu ọ̀nà ibojì náà. Ó bá kúrò níbẹ̀.


Nítorí náà, pàṣẹ kí wọ́n ṣọ́ ibojì náà títí di ọjọ́ kẹta. Bí a kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lè wá jí òkú rẹ̀ lọ, wọn yóo wá wí fún àwọn eniyan pé, ‘Ó ti jinde kúrò ninu òkú.’ Ìtànjẹ ẹẹkeji yóo wá burú ju ti àkọ́kọ́ lọ.”


Wọ́n bá lọ, wọ́n sé ẹnu ibojì náà, wọ́n fi èdìdì sí ara òkúta tí wọ́n gbé dí i. Wọ́n sì fi àwọn olùṣọ́ sibẹ pẹlu.


Nígbà tí Ọjọ́ Ìsinmi ti kọjá, tí ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ mọ́ ní ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, Maria Magidaleni ati Maria keji wá wo ibojì Jesu.


Ilẹ̀ mì tìtì, nítorí angẹli Oluwa sọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run wá. Ó yí òkúta tí ó wà lẹ́nu ibojì kúrò, ó sì jókòó lórí rẹ̀.


Josẹfu bá ra aṣọ funfun kan, ó sọ òkú Jesu kalẹ̀, ó fi aṣọ náà wé e, ó tẹ́ ẹ sí ibojì tí wọ́n gbẹ́ sí inú àpáta, lẹ́yìn náà ó yí òkúta dí ẹnu ibojì náà.


Àwọn obinrin náà sọ ohun gbogbo tí a rán wọn fún Peteru ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ ní ṣókí. Nígbà tí Jesu jí dìde ní òwúrọ̀ ọjọ́ kinni ọ̀sẹ̀, ó kọ́ fara han Maria Magidaleni, tí Jesu lé ẹ̀mí èṣù meje kúrò ninu rẹ̀ nígbà kan.


Orí Jesu tún wú, ó bá lọ síbi ibojì. Ninu ihò òkúta ni ibojì náà wà, òkúta sì wà ní ẹnu ọ̀nà rẹ̀.


Wọ́n bá gbé òkúta náà kúrò. Jesu gbé ojú sókè, ó ní, “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí ò ń gbọ́ tèmi.


Ìyá Jesu ati arabinrin ìyá rẹ̀ ati Maria aya Kilopasi ati Maria Magidaleni dúró lẹ́bàá agbelebu Jesu.


Lẹ́yìn ọjọ́ mẹjọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn tún wà ninu ilé, Tomasi náà wà láàrin wọn. Ìlẹ̀kùn wà ní títì bẹ́ẹ̀ ni Jesu bá tún dé, ó dúró láàrin wọn, ó ní, “Alaafia fun yín!”


Ní alẹ́ ọjọ́ Satide, a péjọ láti jẹun; Paulu wá ń bá àwọn onigbagbọ sọ̀rọ̀. Ó ti wà lọ́kàn rẹ̀ pé lọ́jọ́ keji ni òun óo tún gbéra. Nítorí náà ó sọ̀rọ̀ títí dòru.


Ní ọjọọjọ́ ìsinmi, kí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín máa mú ọrẹ ninu ohun ìní rẹ̀, kí ó máa fi í sọ́tọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun bá ti bukun un. Kí ó má ṣe jẹ́ pé nígbà tí mo bá dé ni ẹ óo ṣẹ̀ṣẹ̀ máa gba ọrẹ jọ.


Nígbà tí ó di Ọjọ́ Oluwa, ni Ẹ̀mí bá gbé mi. Mo gbọ́ ohùn ńlá kan lẹ́yìn mi bí ìgbà tí fèrè bá ń dún,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan