Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 2:6 - Yoruba Bible

6 Ìkòkò òkúta mẹfa kan wà níbẹ̀, tí wọ́n ti tọ́jú fún omi ìwẹ-ọwọ́-wẹ-ẹsẹ̀ àwọn Juu, ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gbà tó bíi garawa omi marun-un tabi mẹfa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Ikoko okuta omi mẹfa li a si gbé kalẹ nibẹ̀, gẹgẹ bi iṣe ìwẹnu awọn Ju, ọkọkan nwọn gbà to ìwọn ládugbó meji tabi mẹta.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Ìkòkò òkúta omi mẹ́fà ni a sì gbé kalẹ̀ níbẹ̀, irú èyí tí àwọn Júù máa ń fi ṣe ìwẹ̀nù, èyí tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn gbà tó ìwọ̀n ogún sí ọgbọ̀n jálá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 2:6
9 Iomraidhean Croise  

Òun bá dáhùn pé, ‘Ọgọrun-un garawa epo.’ Ó sọ fún un pé, ‘Gba ìwé àkọsílẹ̀ rẹ, tètè jókòó, kọ aadọta.’


Jesu wí fún àwọn iranṣẹ pé, “Ẹ pọn omi kún inú àwọn ìkòkò wọnyi.” Wọ́n bá pọnmi kún wọn.


Ọ̀rọ̀ nípa ìwẹ̀mọ́ di àríyànjiyàn láàrin àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Johanu ati ọkunrin Juu kan.


Ó ṣe èyí láti yà á sọ́tọ̀. Ó sọ ọ́ di mímọ́ lẹ́yìn tí ó ti fi omi wẹ̀ ẹ́ nípa ọ̀rọ̀ iwaasu.


Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pẹlu òtítọ́ ọkàn ati igbagbọ tí ó kún, kí á fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wẹ ọkàn wa mọ́, kí ó wẹ ẹ̀rí-ọkàn burúkú wa nù, kí á fi omi mímọ́ wẹ ara wa.


ẹ̀kọ́ nípa ìrìbọmi, ìgbé-ọwọ́-lé eniyan lórí, ajinde kúrò ninu òkú, ati ìdájọ́ ìkẹyìn.


Ohun tí a rí dì mú ninu wọn kò ju nípa jíjẹ ati mímu lọ, ati nípa oríṣìíríṣìí ọ̀nà ìwẹ ọwọ́, wẹ ẹsẹ̀. Ìwọ̀nyí jẹ́ ìlànà àwọn nǹkan tí a lè fojú rí, tí yóo sì máa wà títí di àkókò àtúnṣe.


Gẹ́gẹ́ bí ìlànà òfin, nígbà tí Mose bá ti ka gbogbo àṣẹ Ọlọrun fún àwọn eniyan tán, a mú ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ mààlúù ati ti ewúrẹ́ pẹlu omi, ati òwú pupa ati ẹ̀ka igi hisopu, a fi wọ́n Ìwé Òfin náà ati gbogbo àwọn eniyan.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan