Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 2:18 - Yoruba Bible

18 Àwọn Juu wá bi í pé, “Àmì wo ni ìwọ óo fihàn wá gẹ́gẹ́ bíi ìdí tí o fi ń ṣe nǹkan wọnyi?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

18 Nigbana li awọn Ju dahùn, nwọn si wi fun u pe Àmi wo ni iwọ fi hàn wa, ti iwọ fi nṣe nkan wọnyi?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

18 Nígbà náà ní àwọn Júù dáhùn, wọ́n sì bi í pé, “Ààmì wo ni ìwọ lè fihàn wá, tí ìwọ fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 2:18
14 Iomraidhean Croise  

Ó sì fún wọn ní àmì kan ní ọjọ́ náà, tí wọn yóo fi mọ̀ pé OLUWA ni ó gba ẹnu òun sọ̀rọ̀. Ó ní, “Pẹpẹ yìí yóo wó lulẹ̀, eérú orí rẹ̀ yóo sì fọ́n dànù.”


“Bí Farao bá wí pé kí ẹ ṣe iṣẹ́ ìyanu kan fún òun kí òun lè mọ̀ pé òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ yín, kí ìwọ Mose sọ fún Aaroni pé kí ó ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ níwájú Farao ọba, kí ọ̀pá náà lè di ejò.”


Nígbà tí Jesu dé inú Tẹmpili, bí ó ti ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́, àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà ìlú wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Irú agbára wo ni o fi ń ṣe nǹkan wọnyi? Ta ni ó sì fún ọ ní agbára náà?”


Àwọn Farisi jáde lọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wọ́n ń dán an wò nípa fífi ọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò, wọ́n ní kí ó fi àmì láti ọ̀run hàn wọ́n.


Nígbà tí ọ̀pọ̀ eniyan péjọ yí i ká, ó bẹ̀rẹ̀ sí wí pé, “Ìran burúkú ni ìran yìí; ó ń wá àmì. Kò sí àmì kan tí a óo fún un àfi àmì Jona.


Èyí ni ẹ̀rí tí Johanu jẹ́ nígbà tí àwọn Juu ranṣẹ sí i láti Jerusalẹmu. Wọ́n rán àwọn alufaa ati àwọn kan ninu ẹ̀yà Lefi kí wọ́n lọ bi í pé “Ta ni ọ́?”


Wọ́n wá bi í pé, “Kí ló dé tí o fi ń ṣe ìrìbọmi nígbà tí kì í ṣe ìwọ ni Mesaya tabi Elija tabi wolii tí à ń retí?”


Wọ́n wá bi í pé, “Iṣẹ́ ìyanu wo ni ìwọ óo ṣe, tí a óo rí i, kí á lè gbà ọ́ gbọ́? Iṣẹ́ wo ni o óo ṣe?


Wọ́n mú Peteru ati Johanu wá siwaju ìgbìmọ̀. Wọ́n wá bi wọ́n pé, “Irú agbára wo ni ẹ fi ṣe ohun tí ẹ ṣe yìí? Orúkọ ta ni ẹ lò?”


“Mo ṣebí a pàṣẹ fun yín pé kí ẹ má fi orúkọ yìí kọ́ ẹnikẹ́ni mọ́? Sibẹ gbogbo ará Jerusalẹmu ni ó ti gbọ́ nípa ẹ̀kọ́ yín yìí. Ẹ wá tún di ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ọkunrin yìí lé wa lórí?”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan