Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 19:9 - Yoruba Bible

9 Ó bá tún wọ ààfin lọ, ó bi Jesu pé, “Níbo ni o ti wá?” Ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 O si tun wọ̀ inu gbọ̀ngan idajọ lọ, o si wi fun Jesu pe, Nibo ni iwọ ti wá? Ṣugbọn Jesu kò da a lohùn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Ó sì tún wọ inú gbọ̀ngàn ìdájọ́ lọ, ó sì wí fún Jesu pé, “Níbo ni ìwọ ti wá?” Ṣùgbọ́n Jesu kò dá a lóhùn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 19:9
18 Iomraidhean Croise  

Wọ́n ni í lára, wọ́n pọ́n ọn lójú, sibẹsibẹ kò lanu sọ̀rọ̀, wọ́n fà á lọ bí ọ̀dọ́ aguntan tí wọn ń lọ pa, ati bí aguntan tíí yadi níwájú àwọn tí ń rẹ́ irun rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò lanu sọ̀rọ̀.


Ṣugbọn Jesu kò fọhùn. Olórí Alufaa wá sọ fún un pé, “Mo fi Ọlọrun alààyè bẹ̀ ọ́, sọ fún wa bí ìwọ ni Mesaya, Ọmọ Ọlọrun.”


Àwọn ọmọ-ogun gomina bá mú Jesu lọ sí ibùdó wọn, gbogbo wọn bá péjọ lé e lórí.


Ó bi Jesu ní ọpọlọpọ ìbéèrè ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn rárá.


Lẹ́yìn náà wọ́n mú Jesu kúrò níwájú Kayafa lọ sí ààfin. Ilẹ̀ ti mọ́ ní àkókò yìí. Àwọn fúnra wọn kò wọ inú ààfin, kí wọn má baà di aláìmọ́, kí wọn baà lè jẹ àsè Ìrékọjá.


Pilatu bá tún wọ ààfin lọ, ó bi Jesu pé, “Ṣé ìwọ ni ọba àwọn Juu?”


Jesu dáhùn pé, “O wí èyí fúnrarẹ ni àbí ẹlòmíràn ni ó sọ bẹ́ẹ̀ fún ọ nípa mi?”


Pilatu wá bi í pé, “Èyí ni pé ọba ni ọ́?” Jesu dá a lóhùn pé, “O ti fi ẹnu ara rẹ wí pé Ọba ni mí. Nítorí rẹ̀ ni a ṣe bí mi, nítorí bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe wá sáyé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́. Gbogbo ẹni tí ó bá ń ṣe ti òtítọ́ yóo gbọ́ ohùn mi.”


Nígbà náà ni Pilatu sọ fún un pé, “Èmi ni ìwọ kò dá lóhùn? O kò mọ̀ pé mo ní àṣẹ láti dá ọ sílẹ̀, mo sì ní àṣẹ láti kàn ọ́ mọ́ agbelebu?”


Nígbà tí Pilatu gbọ́ gbolohun yìí, ẹ̀rù túbọ̀ bà á.


Jesu dá wọn lóhùn pé, “Bí mo bá ń jẹ́rìí ara mi, sibẹ òtítọ́ ni ẹ̀rí mi, nítorí mo mọ ibi tí mo ti wá, mo sì mọ ibi tí mò ń lọ. Ṣugbọn ẹ̀yin kò mọ ibi tí mo ti wá, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò sì mọ ibi tí mò ń lọ.


Ẹ má jẹ́ kí ẹ̀rù àwọn alátakò bà yín rárá ninu ohunkohun. Èyí ni yóo jẹ́ ẹ̀rí ìparun wọn, yóo sì jẹ́ ẹ̀rí ìgbàlà yín. Ọlọrun ni yóo ṣe é.


Obinrin náà bá lọ sọ fún ọkọ rẹ̀, ó ní, “Eniyan Ọlọrun kan tọ̀ mí wá, ìrísí rẹ̀ jọ ìrísí angẹli Ọlọrun. Ó bani lẹ́rù gidigidi. N kò bèèrè ibi tí ó ti wá, kò sì sọ orúkọ ara rẹ̀ fún mi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan