Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 19:7 - Yoruba Bible

7 Àwọn Juu dá a lóhùn pé, “A ní òfin kan, nípa òfin náà, ikú ni ó tọ́ sí i, nítorí ó fi ara rẹ̀ ṣe Ọmọ Ọlọrun.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Awọn Ju da a lohùn wipe, Awa li ofin kan, ati gẹgẹ bi ofin wa o yẹ lati kú, nitoriti o fi ara rẹ̀ ṣe Ọmọ Ọlọrun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Àwọn Júù dá a lóhùn wí pé, “Àwa ní òfin kan, àti gẹ́gẹ́ bí òfin, wa ó yẹ fún un láti kú, nítorí ó gbà pé ọmọ Ọlọ́run ni òun ń ṣe.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 19:7
14 Iomraidhean Croise  

Nítòótọ́, ó ti gbé ìkáàánú wa lọ, ó sì ti ru ìbànújẹ́ wa; sibẹsibẹ a kà á sí ẹni tí a nà, tí a sì jẹ níyà láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun.


Ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ OLUWA, pípa ni wọn yóo pa á. Gbogbo ìjọ eniyan yóo sọ ọ́ ní òkúta pa, kì báà jẹ́ àlejò, kì báà jẹ́ onílé; tí ó bá ṣá ti sọ̀rọ̀ òdì sí orúkọ OLUWA, pípa ni wọn yóo pa á.


Nígbà tí ọ̀gágun tí ó dúró lọ́kàn-ánkán rẹ̀ rí bí ó ti dákẹ́ lẹ́yìn tí ó ti kígbe, ó ní, “Dájúdájú, ọmọ Ọlọrun ni ọkunrin yìí.”


Nígbà tí Pilatu gbọ́ gbolohun yìí, ẹ̀rù túbọ̀ bà á.


Nítorí èyí àwọn Juu túbọ̀ ń wá ọ̀nà láti pa á, nítorí kì í ṣe pé ó ba Ọjọ́ Ìsinmi jẹ́ nìkan ni, ṣugbọn ó pe Ọlọrun ní Baba rẹ̀, ó sọ ara rẹ̀ di ọ̀kan náà pẹlu Ọlọrun.


Wọ́n ní, “Ọkunrin yìí ń kọ́ àwọn eniyan láti sin Ọlọrun ní ọ̀nà tí ó lòdì sí òfin.”


Ọmọ rẹ̀ yìí ni Ọlọrun fi agbára Ẹ̀mí Mímọ́ yàn nígbà tí ó jí i dìde kúrò ninu òkú. Òun náà ni Jesu Kristi Oluwa wa,


Ṣugbọn wolii tí ó bá fi orúkọ mi jẹ́ iṣẹ́ tí n kò rán an, tabi tí ó jẹ́ iṣẹ́ kan fun yín ní orúkọ àwọn oriṣa, wolii náà gbọdọ̀ kú ni.’


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan