Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 19:5 - Yoruba Bible

5 Nígbà náà ni Jesu jáde pẹlu adé ẹ̀gún ati ẹ̀wù àlàárì. Pilatu wá sọ fún wọn pé, “Ẹ wò ó, ọkunrin náà nìyí.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Nitorina Jesu jade wá, ti on ti ade ẹgún ati aṣọ elesè àluko. Pilatu si wi fun wọn pe, Ẹ wò ọkunrin na!

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Nítorí náà Jesu jáde wá, ti òun ti adé ẹ̀gún àti aṣọ elése àlùkò. Pilatu sì wí fún wọn pé, Ẹ wò ọkùnrin náà!

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 19:5
8 Iomraidhean Croise  

Gun orí òkè gíga lọ, ìwọ Sioni, kí o máa kéde ìyìn rere. Gbé ohùn rẹ sókè pẹlu agbára Jerusalẹmu, ìwọ tí ò ń kéde ìyìn rere ké sókè má ṣe bẹ̀rù; sọ fún àwọn ìlú Juda pé, “Ẹ wo Ọlọrun yín.”


Ṣugbọn nisinsinyii, Jakọbu, gbọ́ nǹkan tí OLUWA ẹlẹ́dàá rẹ wí, Israẹli, gbọ́ ohun tí ẹni tí ó dá ọ sọ. Ó ní, “Má bẹ̀rù, nítorí mo ti rà ọ́ pada; mo ti pè ọ́ ní orúkọ rẹ, èmi ni mo ni ọ́.


Nítorí náà, OLUWA fúnrarẹ̀ yóo fun yín ní àmì kan. Ẹ gbọ́! Ọlọ́mọge kan yóo lóyún yóo sì bí ọmọkunrin kan, yóo pe orúkọ rẹ̀ ní Imanuẹli.


Ó ní, “Ṣé ọ̀rọ̀ yìí kò kàn yín ni, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ̀ ń kọjá lọ? Ẹ̀yin náà ẹ wò ó, kí ẹ ṣe akiyesi rẹ̀, bóyá ìbànújẹ́ kan wà tí ó dàbí èyí tí ó dé bá mi yìí; tí OLUWA mú kí ó dé bá mi, ní ọjọ́ ibinu gbígbóná rẹ̀.


Wọ́n fi ẹ̀gún hun adé, wọ́n fi dé e lórí. Wọ́n fi ọ̀pá sí ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀. Wọ́n wá ń kúnlẹ̀ níwájú rẹ̀, wọ́n ń fi ṣe yẹ̀yẹ́; wọ́n ń wí pé, “Kabiyesi, ọba àwọn Juu.”


Ní ọjọ́ keji, Johanu rí Jesu tí ó ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Wo ọ̀dọ́ aguntan Ọlọrun, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ aráyé lọ.


Àwọn ọmọ-ogun bá fi ìtàkùn ẹlẹ́gùn-ún hun adé, wọ́n fi dé e lórí; wọn wọ̀ ọ́ ní ẹ̀wù kan bíi ẹ̀wù àlàárì,


Kí á máa wo Jesu olùpilẹ̀ṣẹ̀ ati aláṣepé igbagbọ wa. Ẹni tí ó farada agbelebu, kò sì ka ìtìjú ikú lórí agbelebu sí nǹkankan nítorí ayọ̀ tí ó wà níwájú rẹ̀. Ó ti wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọrun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan