Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 19:2 - Yoruba Bible

2 Àwọn ọmọ-ogun bá fi ìtàkùn ẹlẹ́gùn-ún hun adé, wọ́n fi dé e lórí; wọn wọ̀ ọ́ ní ẹ̀wù kan bíi ẹ̀wù àlàárì,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

2 Awọn ọmọ-ogun si hun ade ẹgún, nwọn si fi de e li ori, nwọn si fi aṣọ igunwà elesè àluko wọ̀ ọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Àwọn ọmọ-ogun sì hun adé ẹ̀gún, wọ́n sì fi dé e ní orí, wọ́n sì fi aṣọ ìgúnwà elése àlùkò wọ̀ ọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 19:2
7 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn kòkòrò lásán ni mí, n kì í ṣe eniyan; ayé kẹ́gàn mi, gbogbo eniyan sì ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà.


Ẹ gbọ́ ohun tí OLUWA, Olùràpadà Israẹli, ati Ẹni Mímọ́ rẹ̀, sọ, fún ẹni tí ayé ń gàn, tí àwọn orílẹ̀-èdè kórìíra, iranṣẹ àwọn aláṣẹ, ó ní, “Àwọn ọba yóo rí ọ, wọn óo dìde, àwọn ìjòyè yóo rí ọ, wọn óo sì dọ̀bálẹ̀. Nítorí OLUWA, tí ó jẹ́ olódodo, Ẹni Mímọ́ Israẹli, tí ó ti yàn ọ́.”


Àwọn eniyan kẹ́gàn rẹ̀, wọ́n sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀; ẹni tí inú rẹ̀ bàjẹ́ tí ó sì mọ ìkáàánú ni. Ó dàbí ẹni tí àwọn eniyan ń wò ní àwòpajúdà. A kẹ́gàn rẹ̀, a kò sì kà á kún.


Hẹrọdu ati àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ ń kẹ́gàn rẹ̀, wọ́n ń fi í ṣe ẹlẹ́yà. Wọ́n gbé ẹ̀wù dáradára kan wọ̀ ọ́; Hẹrọdu bá tún fi ranṣẹ pada sí Pilatu.


Nígbà náà ni Jesu jáde pẹlu adé ẹ̀gún ati ẹ̀wù àlàárì. Pilatu wá sọ fún wọn pé, “Ẹ wò ó, ọkunrin náà nìyí.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan