Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 19:10 - Yoruba Bible

10 Nígbà náà ni Pilatu sọ fún un pé, “Èmi ni ìwọ kò dá lóhùn? O kò mọ̀ pé mo ní àṣẹ láti dá ọ sílẹ̀, mo sì ní àṣẹ láti kàn ọ́ mọ́ agbelebu?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

10 Nitorina Pilatu wi fun u pe, Emi ni iwọ ko fọhun si? iwọ kò mọ̀ pe, emi li agbara lati dá ọ silẹ, emi si li agbara lati kàn ọ mọ agbelebu?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Nítorí náà, Pilatu wí fún un pé, “Èmi ni ìwọ kò fọhùn sí? Ìwọ kò mọ̀ pé, èmi ní agbára láti dá ọ sílẹ̀, èmi sì ní agbára láti kàn ọ́ mọ́ àgbélébùú?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 19:10
5 Iomraidhean Croise  

Nítorí pé Ọlọrun sọ ọ́ di ẹni ńlá, gbogbo eniyan, gbogbo orílẹ̀-èdè ati gbogbo ẹ̀yà ń tẹríba fún un tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù. A máa pa ẹni tí ó bá fẹ́, a sì máa dá ẹni tí ó fẹ́ sí. A máa gbé ẹni tí ó bá fẹ́ ga, a sì máa rẹ ẹni tí ó bá wù ú sílẹ̀.


Ṣugbọn ẹ ní àṣà kan, pé kí n dá ẹnìkan sílẹ̀ fun yín ní àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá. Ṣé ẹ fẹ́ kí n dá ‘Ọba àwọn Juu’ sílẹ̀ fun yín?”


Jesu dá a lóhùn pé, “O kò ní àṣẹ lórí mi àfi èyí tí a ti fi fún ọ láti òkè wá. Nítorí náà, ẹni tí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ pọ̀jù ni ẹni tí ó fà mí lé ọ lọ́wọ́.”


Ó bá tún wọ ààfin lọ, ó bi Jesu pé, “Níbo ni o ti wá?” Ṣugbọn Jesu kò dá a lóhùn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan