Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 19:1 - Yoruba Bible

1 Nígbà náà ni Pilatu mú Jesu, ó ní kí wọ́n nà án.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 NITORINA ni Pilatu mu Jesu, o si nà á.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nítorí náà ni Pilatu mú Jesu, ó sì nà án.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 19:1
16 Iomraidhean Croise  

Wọ́n to ẹgba sí mi lẹ́yìn, gbogbo ẹ̀yìn mi lé bíi poro oko.


Mo tẹ́ ẹ̀yìn sílẹ̀ fún àwọn tí ń nani lẹ́gba; mo sì kọ ẹ̀rẹ̀kẹ́ sí àwọn tí ń fa eniyan ní irùngbọ̀n tu. N kò fojú pamọ́ nítorí ẹ̀gàn, bẹ́ẹ̀ ni n kò gbójú sá fún itọ́ títu síni lójú.


Ṣugbọn wọ́n ṣá a lọ́gbẹ́ nítorí àìdára wa, wọ́n pa á lára nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa; ìyà tí wọ́n fi jẹ ẹ́ ni ó fún wa ní alaafia, nínà tí a nà án ni ó mú wa lára dá.


Wọn óo fà á lé àwọn tí kì í ṣe Juu lọ́wọ́ láti fi ṣe ẹlẹ́yà, láti nà ati láti kàn mọ́ agbelebu. Ṣugbọn ní ọjọ́ kẹta a óo jí i dìde.”


Nítorí èyí ni mo fi rán àwọn wolii, àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ati àwọn amòfin si yín. Ẹ óo pa òmíràn ninu wọn, ẹ óo sì kan òmíràn mọ́ agbelebu. Ẹ óo na àwọn mìíràn ninu wọn ní ilé ìpàdé yín, ẹ óo sì máa lépa wọn láti ìlú dé ìlú.


Nígbà tí wọ́n bá nà án tán, wọn óo sì pa á. Ṣugbọn ní ọjọ́ kẹta, yóo jí dìde.”


Nítorí náà nígbà tí a bá ti nà án tán, n óo dá a sílẹ̀.” [


Ṣugbọn wọ́n túbọ̀ múra kankan, wọ́n ń kígbe pé kí ó kàn án mọ́ agbelebu. Ohùn wọn bá borí.


Ẹẹmarun-un ni àwọn Juu nà mí ní ẹgba mọkandinlogoji.


A fi àwọn mìíràn ṣẹ̀sín. Wọ́n fi kòbókò na àwọn mìíràn. A fi ẹ̀wọ̀n de àwọn mìíràn. A sọ àwọn mìíràn sẹ́wọ̀n.


Òun fúnrarẹ̀ ni ó ru ẹ̀ṣẹ̀ wa lórí igi, kí á baà lè kú sí ẹ̀ṣẹ̀, kí á wà láàyè sí òdodo. Nípa ìnà rẹ̀ ni ẹ fi ní ìmúláradá.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan