Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 18:5 - Yoruba Bible

5 Wọ́n dá a lóhùn pé, “Jesu ará Nasarẹti ni.” Ó sọ fún wọn pé, “Èmi gan-an nìyí.” Judasi, ẹni tí ó fi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, dúró pẹlu wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Nwọn si da a lohùn wipe, Jesu ti Nasareti. Jesu si wi fun wọn pe, Emi niyi. Ati Judasi pẹlu, ẹniti o fi i hàn, duro pẹlu wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Wọ́n sì dá a lóhùn wí pé, “Jesu ti Nasareti.” Jesu sì wí fún wọn pé, “Èmi nìyí.” (Àti Judasi ọ̀dàlẹ̀, dúró pẹ̀lú wọn.)

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 18:5
8 Iomraidhean Croise  

Ìwà àgàbàgebè wọn ń takò wọ́n; wọ́n ń polongo ẹ̀ṣẹ̀ wọn bíi ti Sodomu: Wọn kò fi bò rárá. Ègbé ni fún wọn, nítorí pé àwọn ni wọ́n mú ibi wá sórí ara wọn.


Ǹjẹ́ ojú a tilẹ̀ máa tì wọ́n nígbà tí wọ́n bá ń hu ìwà ìbàjẹ́? Rárá o, ojú kì í tì wọ́n, nítorí pé wọn kò lójútì. Nítorí náà àwọn náà óo ṣubú nígbà tí àwọn yòókù bá ṣubú, a óo bì wọ́n ṣubú nígbà tí mo bá ń jẹ wọ́n níyà, OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.


Ó bá ń gbé ìlú kan tí à ń pé ní Nasarẹti. Èyí rí bẹ́ẹ̀ kí ọ̀rọ̀ tí àwọn wolii sọ lè ṣẹ pé, “A óo pè é ní ará Nasarẹti.”


Àwọn èrò tí ń bọ̀ wá sì dá wọn lóhùn pé, “Jesu, wolii, láti ìlú Nasarẹti ti Galili ni.”


Nataniẹli bi í pé, “Ṣé nǹkan rere kan lè ti Nasarẹti wá?” Filipi dá a lóhùn pé, “Wá wò ó.”


Nígbà tí Jesu rí ohun gbogbo tí yóo ṣẹlẹ̀ sí òun, ó jáde lọ pàdé wọn, ó bi wọ́n pé, “Ta ni ẹ̀ ń wá?”


Nígbà tí ó sọ fún wọn pé, “Èmi gan-an nìyí,” wọ́n bì sẹ́yìn, ni wọ́n bá ṣubú lulẹ̀.


Pilatu kọ àkọlé kan, ó fi sórí agbelebu. Ohun tí ó kọ sórí rẹ̀ ni pé, “Jesu ará Nasarẹti, ọba àwọn Juu.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan