Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 18:18 - Yoruba Bible

18 Àwọn ẹrú ati àwọn ẹ̀ṣọ́ jọ dúró ní àgbàlá, wọ́n ń yáná tí wọ́n fi èédú dá, nítorí òtútù mú. Peteru náà dúró lọ́dọ̀ wọn, òun náà ń yáná.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

18 Awọn ọmọ-ọdọ ati awọn onṣẹ si duro nibẹ̀, awọn ẹniti o ti daná ẹyín; nitori otutù mu, nwọn si nyána: Peteru si duro pẹlu wọn, o nyána.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

18 Àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ àti àwọn aláṣẹ sì dúró níbẹ̀, àwọn ẹni tí ó ti dáná nítorí ti òtútù mú, wọ́n sì ń yáná: Peteru sì dúró pẹ̀lú wọn, ó ń yáná.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 18:18
16 Iomraidhean Croise  

Orí mi má jẹ́ kí n bá wọn pa ìmọ̀ pọ̀, ẹlẹ́dàá mi má sì jẹ́ kí n bá wọn kẹ́gbẹ́. Nítorí wọn a máa fi ibinu paniyan, wọn a sì máa ṣá akọ mààlúù lọ́gbẹ́ bí ohun ìdárayá.


Ó dé ibi ihò àpáta kan, ó sì sùn níbẹ̀ mọ́jú ọjọ́ keji. OLUWA bá a sọ̀rọ̀, ó bi í pé, “Elija, kí ni ò ń ṣe níhìn-ín?”


Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni náà tí kò gba ìmọ̀ràn àwọn eniyan burúkú, tí kò bá àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ rìn, tí kò sì bá àwọn ẹlẹ́gàn kẹ́gbẹ́.


Bí eniyan bá ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóo gbọ́n, ṣugbọn ẹni tí ó bá ń bá òmùgọ̀ kẹ́gbẹ́ yóo ṣìnà.


Peteru wà ní òkèèrè, ó ń tẹ̀lé e títí ó fi wọ agbo-ilé Olórí Alufaa, ó bá jókòó pẹlu àwọn iranṣẹ, wọ́n jọ ń yá iná.


Nígbà tí ó rí Peteru tí ó ń yáná, ó tẹjú mọ́ ọn, ó ní, “Ìwọ náà wà pẹlu Jesu ará Nasarẹti.”


Òógùn ojú rẹ̀ dàbí kí ẹ̀jẹ̀ máa kán bọ́ sílẹ̀.]


Simoni Peteru wà níbi tí ó dúró, tí ó ń yáná. Wọ́n sọ fún un pé, “Ṣé kì í ṣe pé ọ̀kan ninu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ ni ọ́?” Ó sẹ́, ó ní, “Rárá o!”


Judasi bá mú àwọn ọmọ-ogun ati àwọn ẹ̀ṣọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi, wọ́n wá sibẹ pẹlu ògùṣọ̀ ati àtùpà ati àwọn ohun ìjà.


Nígbà tí wọ́n gúnlẹ̀, wọ́n rí ẹja lórí iná eléèédú, wọ́n tún rí burẹdi.


Nígbà tí wọ́n dá wọn sílẹ̀, wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹgbẹ́ wọn, wọ́n ròyìn ohun gbogbo tí àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà sọ fún wọn.


Ẹ má jẹ́ kí wọ́n tàn yín jẹ. Ẹgbẹ́ burúkú a máa ba ìwà rere jẹ́.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan