Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 18:16 - Yoruba Bible

16 Ṣugbọn Peteru dúró lóde lẹ́bàá ẹnu ọ̀nà. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn keji tí Olórí Alufaa mọ̀ jáde, ó bá mú Peteru wọ agbo-ilé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Ṣugbọn Peteru duro li ẹnu-ọ̀na lode. Nigbana li ọmọ-ẹhin miran nì, ti iṣe ẹni mimọ̀ fun olori alufa, o jade lọ, o si ba oluṣọna na sọ ọ, o si mu Peteru wọle.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Ṣùgbọ́n Peteru dúró ní ẹnu-ọ̀nà lóde. Nígbà náà ni ọmọ-ẹ̀yìn mìíràn náà tí í ṣe ẹni mí mọ̀ fún olórí àlùfáà jáde, ó sì bá olùṣọ́nà náà sọ̀rọ̀, ó sì mú Peteru wọlé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 18:16
7 Iomraidhean Croise  

Peteru jókòó lóde ní àgbàlá. Ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹbinrin wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Ìwọ náà wà pẹlu Jesu ará Galili.”


Gẹ́gẹ́ bí àṣà, ní àkókò àjọ̀dún, gomina a máa dá ẹlẹ́wọ̀n kan sílẹ̀ fún àwọn eniyan, ẹnikẹ́ni tí wọn bá fẹ́.


Ní ọdọọdún, ni àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá, Pilatu a máa dá ẹlẹ́wọ̀n kan tí wọ́n bá bẹ̀bẹ̀ fún sílẹ̀.


Ṣugbọn gbogbo wọn bẹ̀rẹ̀ sí pariwo pé, “Mú eléyìí lọ! Baraba ni kí o dá sílẹ̀ fún wa.”


Nígbà tí Peteru kan ìlẹ̀kùn tí ó wà lójúde, ọdọmọbinrin kan tí ń jẹ́ Roda wá láti ṣí i.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan