Johanu 18:1 - Yoruba Bible1 Lẹ́yìn tí Jesu ti gba adura yìí tán, òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ jáde lọ sí òdìkejì àfonífojì odò Kidironi. Ọgbà kan wà níbẹ̀. Ó wọ inú ọgbà náà, òun ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Faic an caibideilBibeli Mimọ1 NIGBATI Jesu si ti sọ nkan wọnyi tan, o jade pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ lọ soke odò Kedroni, nibiti agbala kan wà, ninu eyi ti o wọ̀, on ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní1 Nígbà tí Jesu sì ti sọ nǹkan wọ̀nyí tán, ó jáde pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lọ sókè odò Kidironi, níbi tí àgbàlá kan wà, nínú èyí tí ó wọ̀, Òun àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀. Faic an caibideil |
Josaya bá pàṣẹ fún Hilikaya olórí alufaa, ati àwọn alufaa yòókù ati àwọn tí wọn ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà ilé OLUWA, pé kí wọ́n kó gbogbo ohun èlò ìsìn oriṣa Baali, ati ti oriṣa Aṣera, ati ti àwọn ìràwọ̀ jáde. Ọba jó àwọn ohun èlò náà níná lẹ́yìn odi ìlú, lẹ́bàá àfonífojì Kidironi, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n kó eérú wọn lọ sí Bẹtẹli.