Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 17:6 - Yoruba Bible

6 “Mo ti fi orúkọ rẹ han àwọn eniyan tí o fún mi ninu ayé. Tìrẹ ni wọ́n, ìwọ ni o wá fi wọ́n fún mi. Wọ́n sì ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Emi ti fi orukọ rẹ hàn fun awọn enia ti iwọ ti fifun mi lati inu aiye wá: tirẹ ni nwọn ti jẹ ri, iwọ si ti fi wọn fun mi; nwọn si ti pa ọ̀rọ rẹ mọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 “Èmi ti fi orúkọ rẹ hàn fún àwọn ènìyàn tí ìwọ ti fún mi láti inú ayé wá: tìrẹ ni wọ́n ti jẹ́, ìwọ sì ti fi wọ́n fún mi; wọ́n sì ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 17:6
48 Iomraidhean Croise  

Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ sọ́kàn, kí n má baà ṣẹ̀ ọ́.


N óo ròyìn orúkọ rẹ fún àwọn ará mi; láàrin àwùjọ àwọn eniyan ni n óo sì ti máa yìn ọ́:


ṣugbọn ìdí pataki tí òun fi jẹ́ kí wọ́n wà láàyè ni láti fi agbára òun hàn Farao, kí wọ́n lè máa ròyìn orúkọ òun OLUWA káàkiri gbogbo ayé.


Nítorí ọgbọ́n yóo wọnú ọkàn rẹ, ìmọ̀ yóo sì tu ẹ̀mí rẹ lára,


Ra òtítọ́, má sì tà á, ra ọgbọ́n, ẹ̀kọ́ ati òye pẹlu.


Kò sí ẹni tí ó rí Ọlọrun rí nígbà kan. Ẹnìkan ṣoṣo tí ó jẹ́ ọmọ bíbí Ọlọrun, kòríkòsùn Baba, ni ó fi ẹni tí Baba jẹ́ hàn.


Baba, ṣe orúkọ rẹ lógo.” Ohùn kan bá wá láti ọ̀run, ó ní, “Mo ti ṣe é lógo ná, èmi óo sì tún ṣe é lógo sí i.”


Bí ó bá jẹ́ pé ti ayé ni yín, ayé ìbá fẹ́ràn yín bí àwọn ẹni tirẹ̀. Ṣugbọn ẹ kì í ṣe ti ayé nítorí mo ti yàn yín kúrò ninu ayé; ìdí rẹ̀ nìyí tí ayé fi kórìíra yín.


Ẹ̀yin ti di mímọ́ nítorí ọ̀rọ̀ tí mo ti sọ fun yín.


Bí ẹ bá ń gbé inú mi, tí ọ̀rọ̀ mi ń gbé inú yín, ẹ óo bèèrè ohunkohun tí ẹ bá fẹ́, ẹ óo sì rí i gbà.


Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ wọn, mo fi agbára orúkọ rẹ pa àwọn tí o ti fi fún mi mọ́. Mo pa wọ́n mọ́, ọ̀kan ninu wọn kò ṣègbé àfi ọmọ ègbé, kí Ìwé Mímọ́ lè ṣẹ.


Mo ti fi ọ̀rọ̀ rẹ fún wọn. Ayé kórìíra wọn nítorí wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi náà kì í ti ṣe tíí ayé.


Wọn kì í ṣe ti ayé, gẹ́gẹ́ bí èmi kì í tíí ṣe ti ayé.


Gẹ́gẹ́ bí o ti fún un ní àṣẹ lórí ẹ̀dá gbogbo, pé kí ó lè fi ìyè ainipẹkun fún gbogbo ẹni tí o ti fún un.


“Baba, mo fẹ́ kí àwọn tí o fi fún mi wà pẹlu mi níbi tí èmi gan-an bá wà, kí wọ́n lè máa wo ògo tí o ti fi fún mi, nítorí o ti fẹ́ràn mi kí á tó fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀.


Mo ti mú kí orúkọ rẹ hàn sí wọn, n óo sì tún fihàn, kí ìfẹ́ tí o fẹ́ mi lè wà ninu wọn, kí èmi náà sì wà ninu wọn.”


Nisinsinyii ó ti yé wọn pé láti ọ̀dọ̀ rẹ ni ohun gbogbo tí o fún mi ti wá.


(Kí ọ̀rọ̀ tí ó ti sọ lè ṣẹ tí ó wí pé, “Ọ̀kan kan kò ṣègbé ninu àwọn tí o ti fi fún mi.”)


Gbogbo ẹni tí Baba ti fi fún mi yóo wá sọ́dọ̀ mi. Ẹnikẹ́ni tí ó bá wá sọ́dọ̀ mi, n kò ní ta á nù;


Èyí ni ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́, pé kí n má ṣe sọ ẹnikẹ́ni nù ninu àwọn tí ó fi fún mi, ṣugbọn kí n jí wọn dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn.


Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé bí ẹnikẹ́ni bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kò ní kú laelae.”


Àwọn Juu wá sọ fún un pé, “A wá mọ̀ dájú pé o ní ẹ̀mí èṣù wàyí! Abrahamu kú. Àwọn wolii kú. Ìwọ wá ń sọ pé, ‘Bí ẹnikẹ́ni bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kò ní tọ́ ikú wò laelae.’


Nígbà tí àwọn tí kì í ṣe Juu gbọ́, inú wọn dùn. Wọ́n dúpẹ́ fún ọ̀rọ̀ Oluwa. Gbogbo àwọn tí a ti yàn láti ní ìyè ainipẹkun bá gbàgbọ́.


Ọlọrun kò kọ àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀, àwọn tí ó ti yàn láti ìpilẹ̀ṣẹ̀. Tabi ẹ kò mọ ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ ninu ìtàn Elija? Ó ní,


Nítorí Ọlọrun tí ó ní kí ìmọ́lẹ̀ tàn láti inú òkùnkùn, òun ni ó tan ìmọ́lẹ̀ sí ọkàn wa, kí ìmọ́lẹ̀ ìmọ̀ ògo Ọlọrun lè tàn sí wa ní ojú Kristi.


Kí ọ̀rọ̀ Kristi máa gbé inú yín lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Kí ẹ máa fi gbogbo ọgbọ́n kọ́ ara yín, kí ẹ máa fún ara yín ní ìwúrí nípa kíkọ Orin Dafidi, ati orin ìyìn ati orin àtọkànwá. Ẹ máa kọrin sí Ọlọrun pẹlu ọpẹ́ ninu ọkàn yín.


Di àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ tí ó yẹ, tí o ti gbà láti ọ̀dọ̀ mi mú, pẹlu igbagbọ ati ìfẹ́ tí ó wà ninu Kristi Jesu.


Ó ní, “Èmi óo pe orúkọ rẹ ní gbangba fún àwọn arakunrin mi. Ní ààrin àwùjọ ni n óo yìn ọ́.”


Ṣugbọn Kristi ṣe olóòótọ́ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ninu ìdílé rẹ̀. Àwa gan-an ni ìdílé rẹ̀ náà, bí a bá dúró pẹlu ìgboyà tí à ń ṣògo lórí ìrètí wa.


Èmi Peteru, aposteli Jesu Kristi ni mò ń kọ ìwé yìí sí ẹ̀yin tí ẹ fọ́n káàkiri àwọn ìlú àjèjì bíi Pọntu, Galatia, Kapadokia, Esia ati Bitinia.


A tún mọ̀ pé Ọmọ Ọlọrun ti dé, ó ti fún wa ní làákàyè kí á lè mọ ẹni Òtítọ́. À ń gbé inú Ọlọrun, àní inú Ọmọ rẹ̀, Jesu Kristi. Òun ni Ọlọrun tòótọ́ ati ìyè ainipẹkun.


Mo mọ ibi tí ò ń gbé, ibẹ̀ ni Satani tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí. Sibẹ o di orúkọ mi mú, o kò bọ́hùn ninu igbagbọ ní ọjọ́ tí wọ́n pa Antipasi ẹlẹ́rìí òtítọ́ mi ní ìlú yín níbi tí Satani fi ṣe ilé.


Nítorí o ti fi ìfaradà pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, Èmi náà yóo pa ọ́ mọ́ ní àkókò ìdánwò tí ń bọ̀ wá bá ayé, nígbà tí a óo dán gbogbo àwọn tí ó ń gbé inú ayé wò.


Mo mọ iṣẹ́ rẹ. Wò ó! Mo fi ìlẹ̀kùn kan tí ó ṣí sílẹ̀ siwaju rẹ, tí ẹnikẹ́ni kò lè tì. Mo mọ̀ pé agbára rẹ kéré, sibẹ o ti pa ọ̀rọ̀ mi mọ́. O kò sẹ́ orúkọ mi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan