Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 17:1 - Yoruba Bible

1 Lẹ́yìn tí Jesu ti sọ ọ̀rọ̀ wọnyi tán, ó gbé ojú sókè ọ̀run, ó ní, “Baba, àkókò náà dé! Jẹ́ kí ògo rẹ hàn lára Ọmọ, kí ògo Ọmọ náà lè hàn lára rẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 NKAN wọnyi ni Jesu sọ, o si gbé oju rẹ̀ soke ọrun, o si wipe, Baba, wakati na de: yìn Ọmọ rẹ logo, ki Ọmọ rẹ ki o le yìn ọ logo pẹlu:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nǹkan wọ̀nyí ni Jesu sọ, ó sì gbé ojú rẹ̀ sókè ọ̀run, ó sì wí pé: “Baba, wákàtí náà dé, yin ọmọ rẹ lógo, kí ọmọ rẹ kí ó lè yìn ọ́ lógo pẹ̀lú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 17:1
20 Iomraidhean Croise  

Ìwọ ni mo gbé ojú sókè sí, ìwọ tí o gúnwà ní ọ̀run.


Ọkàn mi ń ṣe hílàhílo bí ẹyẹ aláàpáǹdẹ̀dẹ̀ ati ẹyẹ àkọ̀, mò ń ké igbe arò bí àdàbà. Mo wòkè títí ojú ń ro mí, ara ń ní mí, OLUWA, nítorí náà ṣe ààbò mi.


Ó pada wá ní ẹẹkẹta, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ ṣì wà níbi tí ẹ̀ ń sùn, tí ẹ̀ ń gbádùn ìsinmi yín? Àbùṣe bùṣe! Àkókò náà tó. Wọn yóo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́.


“Ṣugbọn èyí agbowó-odè dúró ní òkèèrè. Kò tilẹ̀ gbé ojú sókè. Ó bá ń lu ara rẹ̀ láyà (bí àmì ìdárò), ó ní, ‘Ọlọrun ṣàánú mi, èmi ẹlẹ́ṣẹ̀.’


Ṣebí ojoojumọ ni mo wà pẹlu yín ninu Tẹmpili. Ẹ kò ṣe fọwọ́ kàn mí? Ṣugbọn àkókò yín ati ti aláṣẹ òkùnkùn nìyí.”


Nígbà tí Jesu gbọ́, ó ní, “Àìsàn yìí kì í ṣe ti ikú, fún ògo Ọlọrun ni, kí á lè ṣe Ọmọ Ọlọrun lógo nípa rẹ̀ ni.”


Wọ́n bá gbé òkúta náà kúrò. Jesu gbé ojú sókè, ó ní, “Baba, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ nítorí ò ń gbọ́ tèmi.


Jesu dá wọn lóhùn pé, “Àkókò náà dé wàyí tí a óo ṣe Ọmọ-Eniyan lógo.


Nígbà tí àkókò Àjọ̀dún Ìrékọjá ku ọjọ́ kan, Jesu mọ̀ pé àkókò tó, tí òun yóo kúrò láyé yìí lọ sọ́dọ̀ Baba. Fífẹ́ tí ó fẹ́ràn àwọn eniyan rẹ̀ tó wà láyé yìí, ó fẹ́ràn wọn dé òpin.


Àkókò ń bọ̀, ó tilẹ̀ ti dé, nígbà tí ẹ óo túká, tí olukuluku yín yóo lọ sí ilé rẹ̀, tí ẹ óo fi èmi nìkan sílẹ̀. Ṣugbọn kò ní jẹ́ èmi nìkan nítorí Baba wà pẹlu mi.


Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí wá ọ̀nà láti mú un, ṣugbọn ẹnikẹ́ni kò fi ọwọ́ kàn án nítorí àkókò rẹ̀ kò ì tíì tó.


Ó wí èyí nípa Ẹ̀mí tí àwọn tí ó gbà á gbọ́ yóo gbà láì pẹ́, nítorí nígbà náà ẹnikẹ́ni kò ì tíì rí ẹ̀bùn Ẹ̀mí gbà nítorí a kò ì tíì ṣe Jesu lógo.


Jesu wí báyìí nígbà tí ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu Tẹmpili ninu iyàrá ìṣúra. Ẹnikẹ́ni kò mú un, nítorí àkókò rẹ̀ kò ì tíì tó.


Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki ati Ọlọrun Jakọbu, Ọlọrun àwọn baba wa ni ó dá Ọmọ rẹ̀, Jesu lọ́lá. Jesu yìí ni ẹ fi lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́, òun ni ẹ sẹ́ níwájú Pilatu nígbà tí ó fi dá a sílẹ̀.


Ẹ̀yin tí ẹ ti ipasẹ̀ rẹ̀ gba Ọlọrun tí ó jí i dìde kúrò ninu òkú gbọ́, tí ó ṣe é lógo, kí igbagbọ ati ìrètí yín lè wà ninu Ọlọrun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan