Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 16:8 - Yoruba Bible

8 Nígbà tí ó bá dé, yóo fi han aráyé pé wọ́n ti ṣìnà ninu èrò wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀, ati nípa òdodo, ati nípa ìdájọ́ Ọlọrun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Nigbati on ba si de, yio fi òye yé araiye niti ẹ̀ṣẹ, ati niti ododo, ati niti idajọ:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Nígbà tí òun bá sì dé, yóò fi òye yé aráyé ní ti ẹ̀ṣẹ̀, àti ní ti òdodo, àti ní ti ìdájọ́:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 16:8
10 Iomraidhean Croise  

Bí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá bo gbogbo ara eniyan láti orí dé àtẹ́lẹsẹ̀ níwọ̀n bí alufaa ti lérò pé ó lè mọ lára eniyan,


“N óo fi ẹ̀mí àánú ati adura sí ọkàn àwọn ọmọ Dafidi ati àwọn ará Jerusalẹmu, tóbẹ́ẹ̀ tí yóo jẹ́ pé, bí wọ́n bá wo ẹni tí wọ́n gún lọ́kọ̀, wọn yóo máa ṣọ̀fọ̀ bí ẹni tí ń ṣọ̀fọ̀ ọmọ rẹ̀ kanṣoṣo. Wọn yóo sì sọkún tẹ̀dùntẹ̀dùn bí ẹni tí àkọ́bí rẹ̀ ṣàìsí.


Sibẹ òtítọ́ ni mo sọ fun yín. Ó sàn fun yín pé kí n lọ. Nítorí bí n kò bá lọ, Alátìlẹ́yìn tí mo wí kò ní wá sọ́dọ̀ yín. Ṣugbọn bí mo bá lọ, n óo rán an si yín.


Wọ́n ti ṣìnà ninu èrò wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀ nítorí pé wọn kò gbà mí gbọ́.


Ta ni ninu yín tí ó ká ẹ̀ṣẹ̀ mọ́ mi lọ́wọ́ rí? Bí mo bá ń sọ òtítọ́, kí ló dé tí ẹ kò fi gbà mí gbọ́?


Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lọ lọ́kọ̀ọ̀kan, àwọn àgbààgbà ni wọ́n kọ́ lọ. Gbogbo wọ́n bá túká pátá láìku ẹnìkan. Ó wá ku obinrin yìí nìkan níbi tí ó dúró sí.


Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́, ọ̀rọ̀ náà gún wọn lọ́kàn. Wọ́n wá bi Peteru ati àwọn aposteli yòókù pé, “Ẹ̀yin ará, kí ni kí á wá ṣe?”


Ṣugbọn bí gbogbo yín bá ń sọ àsọtẹ́lẹ̀, bí ẹnìkan tí ó jẹ́ alaigbagbọ tabi ẹnìkan tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ nǹkan nípa igbagbọ bá wọlé, yóo gbọ́ ohun tí ó jẹ́ ìbáwí ati ohun tí yóo mú un yẹ ara rẹ̀ wò ninu ọ̀rọ̀ tí ẹ̀ ń sọ.


láti ṣe ìdájọ́ lórí gbogbo ẹ̀dá. Yóo bá gbogbo àwọn eniyan burúkú wí fún gbogbo ìwà burúkú tí wọ́n ti hù, ati gbogbo ọ̀rọ̀ líle tí àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ tí kò bẹ̀rù Ọlọrun ti sọ sí òun Oluwa.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan