Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 16:7 - Yoruba Bible

7 Sibẹ òtítọ́ ni mo sọ fun yín. Ó sàn fun yín pé kí n lọ. Nítorí bí n kò bá lọ, Alátìlẹ́yìn tí mo wí kò ní wá sọ́dọ̀ yín. Ṣugbọn bí mo bá lọ, n óo rán an si yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

7 Ṣugbọn otitọ li emi nsọ fun nyin; anfani ni yio jẹ fun nyin bi emi ba lọ: nitori bi emi kò ba lọ, Olutunu kì yio tọ̀ nyin wá: ṣugbọn bi mo ba lọ, emi o rán a si nyin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Ṣùgbọ́n òtítọ́ ni èmi ń sọ fún yín; àǹfààní ni yóò jẹ́ fún yín bí èmi bá lọ: nítorí bí èmi kò bá lọ, Olùtùnú kì yóò tọ̀ yín wá; ṣùgbọ́n bí mo bá lọ, èmi ó rán an sí yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 16:7
19 Iomraidhean Croise  

Ó gun òkè gíga, ó kó àwọn eniyan nígbèkùn; ó gba ẹ̀bùn lọ́wọ́ àwọn eniyan, ati lọ́wọ́ àwọn ọlọ̀tẹ̀ pàápàá. OLUWA Ọlọrun yóo máa gbébẹ̀.


N óo rán ẹ̀bùn tí Baba mi ṣe ìlérí sí orí yín. Ṣugbọn ẹ dúró ninu ìlú yìí títí agbára láti òkè wá yóo fi sọ̀kalẹ̀ sórí yín.”


“Òtítọ́ ni mo sọ fun yín pé opó pọ̀ ní Israẹli ní àkókò Elija, nígbà tí kò fi sí òjò fún ọdún mẹta ati oṣù mẹfa, tí ìyàn fi mú níbi gbogbo.


Ṣugbọn mo sọ fun yín dájúdájú, àwọn mìíràn wà ninu àwọn tí ó dúró níhìn-ín tí wọn kò ní kú títí wọn óo fi rí ìjọba Ọlọrun.”


Ṣugbọn Alátìlẹ́yìn náà, Ẹ̀mí Mímọ́ tí Baba yóo rán wá ní orúkọ mi, ni yóo kọ yín, tí yóo sì ran yín létí ohun gbogbo tí mo sọ fun yín.


Ẹ gbọ́ nígbà tí mo sọ fun yín pé, ‘Mò ń lọ, ṣugbọn n óo tún pada wá sọ́dọ̀ yín.’ Bí ẹ bá fẹ́ràn mi ni, yíyọ̀ ni ẹ̀ bá máa yọ̀ pé, mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba, nítorí Baba jù mí lọ.


Bí mo bá lọ pèsè àyè sílẹ̀ dè yín, n óo tún pada wá láti mu yín lọ sọ́dọ̀ ara mi, kí ẹ lè wà níbi tí èmi pàápàá bá wà.


“Nígbà tí Alátìlẹ́yìn tí n óo rán si yín láti ọ̀dọ̀ Baba bá dé, àní Ẹ̀mí tí ń fi òtítọ́ Ọlọrun hàn, tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Baba, yóo jẹ́rìí nípa mi.


Nígbà tí ó bá dé, yóo fi han aráyé pé wọ́n ti ṣìnà ninu èrò wọn nípa ẹ̀ṣẹ̀, ati nípa òdodo, ati nípa ìdájọ́ Ọlọrun.


Ó wí èyí nípa Ẹ̀mí tí àwọn tí ó gbà á gbọ́ yóo gbà láì pẹ́, nítorí nígbà náà ẹnikẹ́ni kò ì tíì rí ẹ̀bùn Ẹ̀mí gbà nítorí a kò ì tíì ṣe Jesu lógo.


Peteru bá tẹnu bọ̀rọ̀. Ó ní, “Ó wá yé mi gan-an pé Ọlọrun kì í ṣe ojuṣaaju.


Nisinsinyii tí a ti gbé e ka ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun, ó ti gba ìlérí Ẹ̀mí Mímọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba, ó wá tú u jáde. Ohun tí ẹ̀ ń rí, tí ẹ sì ń gbọ́ nìyí.


Àwa mọ̀ dájú pé Ọlọrun a máa mú kí ohun gbogbo yọrí sí rere fún àwọn tí ó fẹ́ràn rẹ̀, àwọn tí ó ti pè gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ̀ láti ayébáyé.


Ìjìyà wa mọ níwọ̀n, ati pé fún àkókò díẹ̀ ni. Àyọrísí rẹ̀ ni ògo tí ó pọ̀ pupọ, tí yóo wà títí, tí ó sì pọ̀ ju ìyà tí à ń jẹ lọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan