Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 16:23 - Yoruba Bible

23 “Ní ọjọ́ náà, ẹ kò ní bi mí léèrè ohunkohun. Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ohunkohun tí ẹ bá bèèrè lọ́dọ̀ Baba ní orúkọ mi, yóo fun yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

23 Ati ni ijọ na ẹnyin kì o bi mi lẽre ohunkohun. Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ohunkohun ti ẹnyin ba bère lọwọ Baba li orukọ mi, on o fifun nyin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

23 Àti ní ọjọ́ náà ẹ̀yin kì ó bi mí lérè ohunkóhun. Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, ohunkóhun tí ẹ̀yin bá béèrè lọ́wọ́ Baba ní orúkọ mi, òhun ó fi fún yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 16:23
22 Iomraidhean Croise  

Kí wọn tó pè mí, n óo ti dá wọn lóhùn, kí wọn tó sọ̀rọ̀ tán, n óo ti gbọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ sọ.


Ohunkohun tí ẹ bá bèèrè ninu adura, bí ẹ bá gbàgbọ́, ẹ óo rí i gbà.”


“Ẹ bèèrè, a óo sì fi fun yín. Ẹ wá kiri, ẹ óo sì rí. Ẹ kanlẹ̀kùn, a óo sì ṣí i fun yín.


Ní ọjọ́ náà, ẹ̀yin yóo mọ̀ pé èmi wà ninu Baba mi, ati pé ẹ̀yin wà ninu mi, èmi náà sì wà ninu yín.


Judasi keji, (kì í ṣe Judasi Iskariotu), bi í pé, “Oluwa, kí ló dé tí o ṣe wí pé o kò ní fi ara rẹ han aráyé, ṣugbọn àwa ni ìwọ óo fi ara hàn?”


Tomasi wí fún un pé, “Oluwa, a kò mọ ibi tí ò ń lọ, báwo ni a ti ṣe lè mọ ọ̀nà ibẹ̀?”


Bí ẹ bá ń gbé inú mi, tí ọ̀rọ̀ mi ń gbé inú yín, ẹ óo bèèrè ohunkohun tí ẹ bá fẹ́, ẹ óo sì rí i gbà.


Jesu mọ̀ pé wọ́n ń fẹ́ bi òun léèrè ọ̀rọ̀ yìí. Ó wá wí fún wọn pé, “Nítorí èyí ni ẹ ṣe ń bá ara yín jiyàn, nítorí mo sọ pé, ‘Laìpẹ́ ẹ kò ní rí mi mọ́,’ ati pé, ‘Lẹ́yìn náà, láìpẹ́ ẹ óo tún rí mi?’


Ní ọjọ́ náà, ẹ óo bèèrè nǹkan ní orúkọ mi, n kò ní wí fun yín pé èmi yóo ba yín bẹ Baba.


A wá mọ̀ wàyí pé o mọ ohun gbogbo, kò ṣẹ̀ṣẹ̀ di ìgbà tí eniyan bá bi ọ́ kí o tó dáhùn ọ̀rọ̀. Nítorí náà, a gbàgbọ́ pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni o ti wá.”


Nítorí nípasẹ̀ rẹ̀ ni àwa mejeeji ṣe rí ààyè láti dé ọ̀dọ̀ Baba nípa Ẹ̀mí kan náà.


Ẹ̀yin ọmọ mi, mò ń kọ ìwé yìí si yín, kí ẹ má baà dẹ́ṣẹ̀. Bí ẹnikẹ́ni bá wá dẹ́ṣẹ̀, a ní alágbàwí kan pẹlu Baba tíí ṣe Jesu Kristi olódodo.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan