Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 16:21 - Yoruba Bible

21 Nígbà tí aboyún bá ń rọbí, ó gbọdọ̀ jẹ ìrora, nítorí àkókò ìkúnlẹ̀ rẹ̀ tó. Ṣugbọn nígbà tí ó bà bímọ tán, kò ní ranti gbogbo ìrora rẹ̀ mọ́, nítorí ayọ̀ pé ó bí ọmọ kan sinu ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

21 Nigbati obinrin bá nrọbi, a ni ibinujẹ, nitoriti wakati rẹ̀ de: ṣugbọn nigbati o ba ti bí ọmọ na tan, on kì si iranti irora na mọ́, fun ayọ̀ nitori a bí enia si aiye.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

21 Nígbà tí obìnrin bá ń rọbí, a ní ìbìnújẹ́, nítorí tí wákàtí rẹ̀ dé: ṣùgbọ́n nígbà tí ó bá ti bí ọmọ náà tán, òun kì í sì í rántí ìrora náà mọ́, fún ayọ̀ nítorí a bí ènìyàn sí ayé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 16:21
18 Iomraidhean Croise  

Lẹ́yìn náà Ọlọrun wí fún obinrin náà pé, “N óo fi kún ìnira rẹ nígbà tí o bá lóyún, ninu ìrora ni o óo máa bímọ. Sibẹsibẹ, lọ́dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yóo máa fà sí, òun ni yóo sì máa ṣe olórí rẹ.”


O óo gbàgbé àwọn ìyọnu rẹ, nígbà tí o bá sì ranti rẹ̀, yóo dàbí ìkún omi tí ó ti wọ́ lọ.


Ó sọ àgàn di ọlọ́mọ, ó sọ ọ́ di abiyamọ onínúdídùn. Ẹ máa yin OLUWA.


ẹnu yóo sì yà wọ́n. Ìpayà ati ìrora yóo mú wọn, wọn yóo wà ninu ìrora bí obinrin tí ó ń rọbí; wọn óo wo ara wọn tìyanu-tìyanu, ojú yóo sì tì wọ́n.


Nítorí náà, gbogbo ẹ̀gbẹ́ ní ń dùn mí, gbogbo ara ní ń ro mí bí obinrin tí ń rọbí lọ́wọ́. A tẹrí mi ba kí n má baà gbọ́ nǹkankan, wọ́n dẹ́rù bà mí kí n má baà ríran.


“Kí ó tó bẹ̀rẹ̀ sí rọbí, ó ti bímọ. Kí ìrora obí tó mú un, ó ti bí ọmọkunrin kan.


Ẹ máa yí nílẹ̀, kí ẹ sì máa kérora bí obinrin tí ń rọbí, ẹ̀yin ará Jerusalẹmu; nítorí pé ẹ gbọdọ̀ jáde ní ìlú yín wàyí, ẹ óo lọ máa gbé inú pápá; ẹ óo lọ sí Babiloni. Ibẹ̀ ni a óo ti gbà yín là, níbẹ̀ ni OLUWA yóo ti rà yín pada kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá yín.


Kí ló dé, tí ò ń pariwo bẹ́ẹ̀? Ṣé ẹ kò ní ọba ni? Tabi ẹ kò ní olùdámọ̀ràn mọ́, ni ìrora fi mu yín bí obinrin tí ń rọbí?


Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Máa yọ̀, ìwọ àgàn tí kò bímọ rí. Sọ̀rọ̀ kí o kígbe sókè, ìwọ tí kò rọbí rí. Nítorí àwọn ọmọ àgàn pọ̀ ju ti obinrin tí ó ní ọkọ lọ.”


Nígbà tí àwọn eniyan bá ń wí pé, “Àkókò alaafia ati ìrọ̀ra nìyí,” nígbà náà ni ìparun yóo dé bá wọn lójijì, wọn kò sì ní ríbi sá sí; yóo dàbí ìgbà tí obinrin bá lóyún, tí kò mọ ìgbà tí òun yóo bí.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan