Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 16:16 - Yoruba Bible

16 “Láìpẹ́ ẹ kò ní rí mi mọ́. Lẹ́yìn náà, láìpẹ́ ẹ óo sì tún rí mi.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Nigba diẹ, ẹnyin kì o si ri mi: ati nigba diẹ ẹ̀wẹ, ẹ ó si ri mi, nitoriti emi nlọ sọdọ Baba.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 “Nígbà díẹ̀, ẹ̀yin kì ó sì rí mi: àti nígbà díẹ̀ si, ẹ ó sì rí mi, nítorí tí èmi ń lọ sọ́dọ̀ Baba.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 16:16
19 Iomraidhean Croise  

Lẹ́yìn tí Jesu Oluwa ti bá wọn sọ̀rọ̀ tán, a gbé e lọ sí òkè ọ̀run, ó wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun.


Jesu dá wọn lóhùn pé, “Ìmọ́lẹ̀ wà láàrin yín fún àkókò díẹ̀ sí i. Ẹ máa rìn níwọ̀n ìgbà tí ẹ ní ìmọ́lẹ̀, kí òkùnkùn má baà bò yín mọ́lẹ̀. Ẹni tí ó bá ń rìn ninu òkùnkùn kò mọ ibi tí ó ń lọ.


Jesu mọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo lé òun lọ́wọ́, ati pé ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni òun ti wá, ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni òun sì ń lọ.


Ẹ̀yin ọmọ, àkókò díẹ̀ ni mo ní sí i pẹlu yín. Ẹ óo wá mi, ṣugbọn bí mo ti sọ fún àwọn Juu pé, ‘Níbi tí mò ń lọ, ẹ̀yin kò ní lè dé ibẹ̀,’ bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fun yín nisinsinyii.


Wọ́n ṣìnà ní ti òdodo nítorí mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba, ẹ kò sì ní rí mi mọ́.


Bákan náà ni: inú yín bàjẹ́ nisinsinyii, ṣugbọn n óo tún ri yín, inú yín yóo wá dùn, ẹnikẹ́ni kò ní lè mú ayọ̀ yín kúrò lọ́kàn yín.


Mo wá láti ọ̀dọ̀ Baba, mo jáde wá sinu ayé, n óo tún fi ayé sílẹ̀ láti lọ sọ́dọ̀ Baba.”


Ṣugbọn nisinsinyii mò ń lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́. Ẹnìkankan ninu yín kò wí pé, ‘Níbo ni ò ń lọ?’


Ṣugbọn nisinsinyii mò ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ. Mò ń sọ ọ̀rọ̀ wọnyi ninu ayé, kí wọ́n lè ní ayọ̀ mi lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ ninu ọkàn wọn.


Nisinsinyii, Baba, jẹ́ kí ògo rẹ hàn lára mi; àní kí irú ògo tí mo ti ní pẹlu rẹ kí a tó dá ayé tún hàn lára mi.


Jesu bá dáhùn pé, “Àkókò díẹ̀ ni ó kù tí n óo lò pẹlu yín, lẹ́yìn náà n óo lọ sọ́dọ̀ ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.


Àwọn aposteli yìí ni ó fi ara rẹ̀ hàn láàyè lẹ́yìn ìjìyà rẹ̀ pẹlu ẹ̀rí tí ó dájú. Wọ́n rí i níwọ̀n ogoji ọjọ́, ó sì ń bá wọn sọ̀rọ̀ nípa nǹkan tí ó jẹ mọ́ ti ìjọba Ọlọrun.


Kí á máa wo Jesu olùpilẹ̀ṣẹ̀ ati aláṣepé igbagbọ wa. Ẹni tí ó farada agbelebu, kò sì ka ìtìjú ikú lórí agbelebu sí nǹkankan nítorí ayọ̀ tí ó wà níwájú rẹ̀. Ó ti wá jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún ìtẹ́ Ọlọrun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan