Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 15:9 - Yoruba Bible

9 Gẹ́gẹ́ bí Baba ti fẹ́ràn mi, bẹ́ẹ̀ ni mo fẹ́ràn yín. Ẹ máa gbé inú ìfẹ́ mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Gẹgẹ bi Baba ti fẹ mi, bẹ̃li emi si fẹ nyin: ẹ duro ninu ifẹ mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 “Gẹ́gẹ́ bí Baba ti fẹ́ mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi sì fẹ́ yín: ẹ dúró nínú ìfẹ́ rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 15:9
9 Iomraidhean Croise  

“Mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín kí ayọ̀ mi lè wà ninu yín, kí ẹ lè ní ayọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.


Kò sí ẹni tí ó ní ìfẹ́ tí ó ju èyí lọ, pé ẹnìkan kú nítorí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀.


Mo ti mú kí orúkọ rẹ hàn sí wọn, n óo sì tún fihàn, kí ìfẹ́ tí o fẹ́ mi lè wà ninu wọn, kí èmi náà sì wà ninu wọn.”


Baba fẹ́ràn Ọmọ, ó sì ti fi ohun gbogbo sí ìkáwọ́ rẹ̀.


kí ẹ lè ní agbára, pẹlu gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun, láti mọ bí ìfẹ́ Kristi ti gbòòrò tó, bí ó ti gùn tó, bí ó ti ga tó, ati bí ó ti jìn tó;


Ǹjẹ́ nisinsinyii, ẹ̀yin ọmọ, ẹ máa gbé inú rẹ̀, kí á lè ní ìgboyà nígbà tí ó bá farahàn, kí ojú má baà tì wá láti wá siwaju rẹ̀ nígbà tí ó bá dé.


Ṣugbọn ẹ̀yin, àyànfẹ́ mi, ẹ fi igbagbọ yín tí ó mọ́ jùlọ ṣe odi fún ara yín, kí ẹ máa gbadura nípa agbára tí ó wà ninu Ẹ̀mí Mímọ́.


ati láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, ẹlẹ́rìí òtítọ́, ẹnikinni tí ó jinde láti inú òkú ati aláṣẹ lórí àwọn ọba ilé ayé. Ẹni tí ó fẹ́ràn wa, tí ó fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan