Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 15:8 - Yoruba Bible

8 Báyìí ni ògo Baba mi yóo ṣe yọ, pé kí ẹ máa so ọpọlọpọ èso. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ṣe jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Ninu eyi li a yìn Baba mi logo pe, ki ẹnyin ki o mã so eso pupọ; ẹnyin o si jẹ ọmọ-ẹhin mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Nínú èyí ní a yìn Baba mi lógo pé, kí ẹ̀yin kí ó máa so èso púpọ̀; ẹ̀yin ó sì jẹ́ ọmọ-ẹ̀yìn mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 15:8
19 Iomraidhean Croise  

Gbogbo àwọn eniyan rẹ yóo jẹ́ olódodo, àwọn ni yóo jogún ilẹ̀ náà títí lae. Àwọn ni ẹ̀ka igi tí mo gbìn, iṣẹ́ ọwọ́ mi, kí á baà lè yìn mí lógo.


Ó ní kí n máa fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ní Sioni, ní inú dídùn dípò ìkáàánú, kí n fún wọn ní ayọ̀ dípò ìbànújẹ́, kí n jẹ́ kí wọn máa kọrin ìyìn dípò ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn, kí á lè máa pè wọ́n ní igi òdodo, tí OLUWA gbìn, kí á lè máa yìn ín lógo.


Ẹ lọ sórí àwọn òkè, kí ẹ gé igi ìrólé láti kọ́ ilé náà, kí inú mi lè dùn sí i, kí n sì lè farahàn ninu ògo mi. Bẹ́ẹ̀ ni èmi OLUWA wí.


Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni ìmọ́lẹ̀ yín níláti máa tàn níwájú àwọn eniyan, kí wọn lè rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn lè máa yin Baba yín tí ó ń bẹ lọ́run lógo.


Ṣugbọn èmi wá ń sọ fun yín pé, ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín. Ẹ máa gbadura fún àwọn tí ó ṣe inúnibíni yín.


Ẹ̀rù ba àwọn eniyan tí wọn ń wo ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Wọ́n fi ògo fún Ọlọrun tí ó fi irú àṣẹ bẹ́ẹ̀ fún eniyan.


Ṣugbọn ẹ máa fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín; ẹ ṣoore. Ẹ máa yá eniyan lówó láì ní ìrètí láti gbà á pada. Èrè yín yóo pọ̀, ẹ óo wá jẹ́ ọmọ Ọ̀gá Ògo nítorí ó ń ṣoore fún àwọn aláìmoore ati àwọn eniyan burúkú.


Èyí ni yóo jẹ́ kí gbogbo eniyan mọ̀ pé ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá fẹ́ràn ara yín.”


“Èmi ni àjàrà, ẹ̀yin ni ẹ̀ka. Ẹni tí ó bá ń gbé inú mi, tí èmi náà sì ń gbé inú rẹ̀, yóo máa so èso pupọ. Ẹ kò lè dá ohunkohun ṣe lẹ́yìn mi.


Jesu bá wí fún àwọn Juu tí ó gbà á gbọ́ pé, “Bí ẹ̀yin bá ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ mi, ọmọ-ẹ̀yìn mi ni yín nítòótọ́;


Nítorí náà, ìbáà jẹ́ pé ẹ̀ ń jẹ ni, tabi pé ẹ̀ ń mu ni, ohunkohun tí ẹ bá ń ṣe, ẹ máa ṣe é fún ògo Ọlọrun.


Iyebíye ni Ọlọrun rà yín, nítorí náà, ẹ fi ara yín yin Ọlọrun.


Mo tún gbadura pé kí ẹ lè kún fún èso iṣẹ́ òdodo tí ó ti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi wá fún ògo ati ìyìn Ọlọrun.


Kí wọn má máa ja ọ̀gá wọn lólè. Ṣugbọn kí wọn jẹ́ olóòótọ́ ati ẹni tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé ní ọ̀nà gbogbo. Báyìí ni wọn yóo fi ṣe ẹ̀kọ́ Ọlọrun Olùgbàlà wa lọ́ṣọ̀ọ́ ninu ohun gbogbo.


Kí wọn máa fara balẹ̀, kí wọn sì fara mọ́ ọkọ wọn nìkan. Kí wọn má ya ọ̀lẹ ninu iṣẹ́ ilé, kí wọn sì jẹ́ onínú rere. Kí wọn máa gbọ́ràn sí ọkọ wọn lẹ́nu, kí ẹnikẹ́ni má baà lè sọ ìsọkúsọ sí ọ̀rọ̀ Ọlọrun.


Kí ìgbé-ayé yín láàrin àwọn abọ̀rìṣà jẹ́ èyí tí ó dára, tí ó fi jẹ́ pé bí wọ́n bá tilẹ̀ ń sọ̀rọ̀ yín ní àìdára, sibẹ nígbà tí wọ́n bá ṣe akiyesi ìwà rere yín, wọn yóo yin Ọlọrun lógo ní ọjọ́ ìdájọ́.


Bí ẹnikẹ́ni bá ń sọ̀rọ̀, kí ó mọ̀ pé ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀ Ọlọrun ni òun ń sọ. Bí ẹnikẹ́ni bá ṣe iṣẹ́ iranṣẹ, kí ó ṣe é pẹlu gbogbo agbára tí Ọlọrun fún un. Ninu ohun gbogbo ẹ máa hùwà kí ògo lè jẹ́ ti Ọlọrun nípasẹ̀ Jesu Kristi: òun ni ògo ati agbára jẹ́ tirẹ̀ lae ati laelae. Amin.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan