Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 15:6 - Yoruba Bible

6 Bí ẹnikẹ́ni kò bá gbé inú mi, a óo jù ú sóde bí ẹ̀ka, yóo sì gbẹ; wọn óo mú un, wọn óo sì fi dáná, yóo bá jóná.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

6 Bi ẹnikan kò ba gbé inu mi, a gbe e sọnu gẹgẹ bi ẹka, a si gbẹ; nwọn a si kó wọn jọ, nwọn a si sọ wọn sinu iná, nwọn a si jóna.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Bí ẹnìkan kò bá gbé inú mi, a gbé e sọnù gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ka, a sì gbẹ; wọn a sì kó wọn jọ, wọn a sì sọ wọ́n sínú iná, wọn a sì jóná.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 15:6
20 Iomraidhean Croise  

Ẹni tí yóo fọwọ́ kan ẹ̀gún gbọdọ̀ lo ohun èlò tí a fi irin ṣe tabi igi ọ̀kọ̀, láti fi wọ́n jóná patapata.”


Kò ní bọ́ kúrò ninu òkùnkùn, iná yóo jó àwọn ẹ̀ka rẹ̀, afẹ́fẹ́ yóo sì fẹ́ àwọn ìtànná rẹ̀ dànù.


ohun ọ̀gbìn tí o fi ọwọ́ ọ̀tún rẹ gbìn, àní, ọ̀dọ́ igi tí o fi ọwọ́ ara rẹ tọ́jú.


Ṣugbọn a lé ìwọ kúrò ninu ibojì rẹ, bí ọmọ tí a bí kí oṣù rẹ̀ tó pé, tí a gbé òkú rẹ̀ sọnù; tí a jù sáàrin òkú àwọn jagunjagun tí a pa lójú ogun; àwọn tí a jù sinu kòtò olókùúta, bí àwọn tí a tẹ̀ ní àtẹ̀pa.


Nítorí ìlú olódi ti di ahoro, ó di ibùgbé tí a kọ̀ sílẹ̀, tí a sì patì bí aginjù; ibẹ̀ ni àwọn ọmọ mààlúù yóo ti máa jẹko, wọn óo dùbúlẹ̀ níbẹ̀, wọn óo sì máa jẹ àwọn ẹ̀ka igi rẹ̀.


“Sọ fún wọn pé, èmi OLUWA Ọlọrun ní kí o bèèrè lọ́wọ́ wọn pé, ‘Ṣé àjàrà yìí yóo ṣe dáradára? Ṣé idì ti àkọ́kọ́ kò ní fa gbòǹgbò rẹ̀ tu, kí ó gé ẹ̀ka rẹ̀, kí àwọn ewé rẹ̀ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ yọ sì rọ?’ Kò ṣẹ̀ṣẹ̀ nílò alágbára tabi ọ̀pọ̀ eniyan, láti fà á tu tigbòǹgbò tigbòǹgbò.


Ọmọ-Eniyan yóo rán àwọn angẹli rẹ̀, wọn yóo kó gbogbo àwọn amúni-ṣìnà ati àwọn arúfin kúrò ninu ìjọba rẹ̀.


Judasi bá da owó náà sílẹ̀ ninu Tẹmpili, ó jáde, ó bá lọ pokùnso.


A sì ti fi àáké lé gbòǹgbò igi báyìí, nítorí náà, igikígi tí kò bá so èso rere ni a óo gé lulẹ̀, tí a óo fi dáná.


Igikígi tí kò bá so èso rere, gígé ni a óo gé e lulẹ̀, tí a óo sì fi dáná.


Gígé ni yóo gé gbogbo ẹ̀ka ara mi tí kò bá so èso, ṣugbọn yóo re ọwọ́ gbogbo ẹ̀ka tí ó bá ń so èso, kí wọ́n lè mọ́, kí wọ́n sì lè máa so sí i lọpọlọpọ.


Ohun tí ó kù ni pé kí á máa retí ìdájọ́ pẹlu ìpayà ati iná ńlá tí yóo pa àwọn ọ̀tá Ọlọrun.


Nítorí bí wọ́n bá ti bọ́ lọ́wọ́ ìbàjẹ́ ayé nípa mímọ Oluwa ati olùgbàlà wa, Jesu Kristi, tí wọ́n tún wá pada sí ìwà àtijọ́, tí ìwà yìí bá tún borí wọn, ìgbẹ̀yìn wọn á wá burú ju ipò tí wọ́n wà lákọ̀ọ́kọ́ lọ.


Ọ̀dọ̀ wa ni wọ́n ti kúrò ṣugbọn wọn kì í ṣe ara wa. Nítorí bí ó bá jẹ́ pé ara wa ni wọ́n, wọn ìbá dúró lọ́dọ̀ wa. Ṣugbọn kí ó lè hàn dájú pé gbogbo wọn kì í ṣe ara wa ni wọ́n ṣe kúrò lọ́dọ̀ wa.


Ẹnikẹ́ni tí kò bá sí orúkọ rẹ̀ ninu ìwé ìyè, a óo sọ ọ́ sinu adágún iná.


Ṣugbọn àwọn ojo, àwọn alaigbagbọ, àwọn ẹlẹ́gbin, àwọn apànìyàn, àwọn àgbèrè, àwọn oṣó, àwọn abọ̀rìṣà, ati gbogbo àwọn èké ni yóo ní ìpín wọn ninu adágún iná tí ń jó, tí a fi imí-ọjọ́ dá. Èyí ni ikú keji.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan