Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 15:5 - Yoruba Bible

5 “Èmi ni àjàrà, ẹ̀yin ni ẹ̀ka. Ẹni tí ó bá ń gbé inú mi, tí èmi náà sì ń gbé inú rẹ̀, yóo máa so èso pupọ. Ẹ kò lè dá ohunkohun ṣe lẹ́yìn mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

5 Emi ni àjara, ẹnyin li ẹka. Ẹniti o ngbé inu mi, ati emi ninu rẹ̀, on ni yio so eso ọ̀pọlọpọ: nitori ni yiyara nyin kuro lọdọ mi, ẹ ko le ṣe ohun kan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 “Èmi ni àjàrà, ẹ̀yin ni ẹ̀ka. Ẹni tí ó ń gbé inú mi, àti èmi nínú rẹ̀, òun ni yóò so èso lọ́pọ̀lọpọ̀: nítorí ní yíya ara yín kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ kò lè ṣe ohun kan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 15:5
28 Iomraidhean Croise  

Èso olódodo ni igi ìyè, ṣugbọn ìwà aibikita fún òfin a máa paniyan.


Ẹ̀ ń fi ẹ̀ṣẹ̀ àwọn eniyan mi wá oúnjẹ fún ara yín, ẹ sì ń mú kí wọ́n máa dá ẹ̀ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀


Ṣugbọn nítorí kò ní gbòǹgbò ninu ara rẹ̀, ọ̀rọ̀ náà yóo wà fún ìgbà díẹ̀. Nígbà tí inúnibíni tabi ìṣòro bá dé nítorí ọ̀rọ̀ náà, lẹsẹkẹsẹ a kùnà.


Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé bí ẹyọ irúgbìn kan kò bá bọ́ sílẹ̀, kí ó kú, òun nìkan ni yóo dá wà. Ṣugbọn bí ó bá kú, á mú ọpọlọpọ èso wá.


Kì í ṣe ẹ̀yin ni ẹ yàn mí. Èmi ni mo yàn yín, tí mo ran yín pé kí ẹ lọ máa so èso tí kò ní bàjẹ́, kí Baba lè fun yín ní ohunkohun tí ẹ bá bèèrè ní orúkọ mi.


Nígbà náà ni Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé, Ọmọ kò lè dá nǹkankan ṣe yàtọ̀ sí ohun tí ó bá rí tí Baba ń ṣe. Àwọn ohun tí Ọmọ rí pé Baba ń ṣe ni òun náà ń ṣe.


Bí ọkunrin yìí kò bá wá láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun, kì bá tí lè ṣe ohunkohun.”


Kò sí ìgbàlà lọ́dọ̀ ẹlòmíràn; bẹ́ẹ̀ ni kò sí orúkọ mìíràn tí a fi fún eniyan lábẹ́ ọ̀run nípa èyí tí a lè fi gba eniyan là.”


bẹ́ẹ̀ gan-an ni gbogbo wa, bí á tilẹ̀ pọ̀, ara kan ni wá ninu Kristi, ẹnìkọ̀ọ̀kan wa sì jẹ́ ẹ̀yà ara ẹnìkejì rẹ̀.


Ṣugbọn nisinsinyii tí ẹ ti bọ́ lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀, tí ẹ ti di ẹrú Ọlọrun, èrè tí ẹ óo máa rí, ti ohun mímọ́ ni. Ìyè ainipẹkun ni yóo sì yọrí sí.


Bẹ́ẹ̀ náà ni, ẹ̀yin ará mi, ẹ̀yin náà ti kú ní ti Òfin, nígbà tí ẹ di ara kan náà pẹlu Kristi. Ẹ ti ní ọkọ mìíràn, àní, ẹni tí a ti jí dìde kúrò ninu òkú, kí á lè sin Ọlọrun lọ́nà tí yóo yọrí sí rere.


Ife ibukun tí à ń dúpẹ́ fún, ṣebí àjọpín ninu ẹ̀jẹ̀ Kristi ni. Burẹdi tí a bù, ṣebí àjọpín ninu ara Kristi ni.


Nítorí gẹ́gẹ́ bí ara ti jẹ́ ọ̀kan, tí ó ní ọpọlọpọ ẹ̀yà, bí gbogbo àwọn ẹ̀yà ara ti pọ̀ tó, sibẹ tí ara jẹ́ ọ̀kan ṣoṣo, bẹ́ẹ̀ ni Kristi rí.


Ẹ̀yin ni ara Kristi, ẹ̀yà ara rẹ̀ ni ẹnìkọ̀ọ̀kan yín.


Nítorí a kò lè ṣe nǹkankan tí ó lòdì sí òtítọ́, àfi òtítọ́.


Ṣugbọn ẹni tí ó ń pèsè irúgbìn fún afunrugbin, tí ó tún ń pèsè oúnjẹ fún jíjẹ, yóo pèsè èso lọpọlọpọ fun yín, yóo sì mú kí àwọn èso iṣẹ́ àánú yín pọ̀ sí i.


Ṣugbọn èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, alaafia, sùúrù, àánú, iṣẹ́ rere, ìṣòtítọ́,


Nítorí èso ìmọ́lẹ̀ ni oríṣìíríṣìí iṣẹ́ rere, òdodo ati òtítọ́.


Mo tún gbadura pé kí ẹ lè kún fún èso iṣẹ́ òdodo tí ó ti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi wá fún ògo ati ìyìn Ọlọrun.


Mo lè ṣe ohun gbogbo ninu Kristi ẹni tí ó ń fún mi ní agbára.


Kì í ṣe ẹ̀bùn ni mò ń wá, ṣugbọn mò ń wá ọpọlọpọ èso fún anfaani yín.


A tún ń gbadura pé kí ìgbé-ayé yín lè jẹ́ èyí tí ó wu Oluwa lọ́nà gbogbo, kí iṣẹ́ rere yín máa pọ̀ sí i, kí ẹ máa tẹ̀síwájú ninu ìmọ̀ Ọlọrun.


Ìyìn rere yìí ti dé ọ̀dọ̀ yín gẹ́gẹ́ bí ó ti dé ọ̀dọ̀ gbogbo aráyé, ó ń so èso, ó sì ń dàgbà. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí láàrin ẹ̀yin náà láti ọjọ́ tí ẹ ti gbọ́, tí ẹ sì ti mọ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun nítòótọ́.


Láti òkè ni gbogbo ẹ̀bùn rere ati gbogbo ẹ̀bùn pípé ti ń wá, a máa wá láti ọ̀dọ̀ Baba tí ó dá ìmọ́lẹ̀, baba tí kì í yí pada, tí irú òjìji tíí máa wà ninu ìṣípò pada kò sì sí ninu rẹ̀.


Ẹ wá sọ́dọ̀ ẹni tíí ṣe òkúta ààyè tí eniyan kọ̀ sílẹ̀ ṣugbọn tí Ọlọrun yàn, tí ó ṣe iyebíye lójú rẹ̀.


Ṣugbọn ẹ máa dàgbà ninu oore-ọ̀fẹ́ ati ìmọ̀ Oluwa ati olùgbàlà wa, Jesu Kristi. Tirẹ̀ ni ògo nisinsinyii ati títí laelae. Amin.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan