Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 14:4 - Yoruba Bible

4 Ẹ kúkú ti mọ ọ̀nà ibi tí mò ń lọ.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

4 Ẹnyin si mọ̀ ibi ti emi gbé nlọ, ẹ si mọ̀ ọ̀na na.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Ẹ̀yin mọ ibi tí èmi gbé ń lọ, ẹ sì mọ ọ̀nà náà.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 14:4
13 Iomraidhean Croise  

Dandan ni pé kí Mesaya jìyà, kí ó tó bọ́ sinu ògo rẹ̀.”


Èmi ni ìlẹ̀kùn. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gba ọ̀dọ̀ mi wọlé yóo rí ìgbàlà, yóo máa wọlé, yóo máa jáde, yóo sì máa rí oúnjẹ jẹ.


Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ jẹ́ iranṣẹ mi, ó níláti tẹ̀lé mi. Níbi tí èmi alára bá wà, níbẹ̀ ni iranṣẹ mi yóo wà. Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ́ iranṣẹ mi, Baba mi yóo dá a lọ́lá.”


Jesu mọ̀ pé Baba ti fi ohun gbogbo lé òun lọ́wọ́, ati pé ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni òun ti wá, ọ̀dọ̀ Ọlọrun ni òun sì ń lọ.


Yàrá pupọ ni ó wà ninu ilé Baba mi. Bí kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ n óo sọ fun yín pé mò ń lọ pèsè àyè sílẹ̀ dè yín?


Ẹ gbọ́ nígbà tí mo sọ fun yín pé, ‘Mò ń lọ, ṣugbọn n óo tún pada wá sọ́dọ̀ yín.’ Bí ẹ bá fẹ́ràn mi ni, yíyọ̀ ni ẹ̀ bá máa yọ̀ pé, mò ń lọ sọ́dọ̀ Baba, nítorí Baba jù mí lọ.


Bí mo bá lọ pèsè àyè sílẹ̀ dè yín, n óo tún pada wá láti mu yín lọ sọ́dọ̀ ara mi, kí ẹ lè wà níbi tí èmi pàápàá bá wà.


Tomasi wí fún un pé, “Oluwa, a kò mọ ibi tí ò ń lọ, báwo ni a ti ṣe lè mọ ọ̀nà ibẹ̀?”


Mo wá láti ọ̀dọ̀ Baba, mo jáde wá sinu ayé, n óo tún fi ayé sílẹ̀ láti lọ sọ́dọ̀ Baba.”


Ẹni tí ó bá gba Ọmọ gbọ́ ní ìyè ainipẹkun. Ṣugbọn ẹni tí ó bá ṣàìgbọràn sí Ọmọ kò ní rí ìyè, ṣugbọn ibinu Ọlọrun wà lórí rẹ̀.


Nítorí ìfẹ́ Baba mi ni pé, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí Ọmọ rẹ̀, tí ó bá gbà á gbọ́, lè ní ìyè ainipẹkun. Èmi fúnra mi yóo jí wọn dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn.”


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan