Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 14:16 - Yoruba Bible

16 N óo bèèrè lọ́wọ́ Baba, yóo wá fun yín ní Alátìlẹ́yìn mìíràn tí yóo wà pẹlu yín títí lae.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

16 Emi ó si bère lọwọ Baba, on ó si fun nyin li Olutunu miran, ki o le mã ba nyin gbé titi lailai,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Nígbà náà èmi yóò wá béèrè lọ́wọ́ Baba. Òun yóò sì fún yín ní olùtùnú mìíràn. Olùtùnú náà yóò máa bá yín gbé títí láé

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 14:16
31 Iomraidhean Croise  

Ẹ máa kọ́ wọn láti kíyèsí gbogbo nǹkan tí mo pa láṣẹ fun yín. Kí ẹ mọ̀ dájú pé mo wà pẹlu yín ní ìgbà gbogbo, títí dé òpin ayé.”


Ohunkohun tí ẹ bá bèèrè lọ́wọ́ mi ní orúkọ mi, èmi yóo ṣe é.


“Èmi kò ní fi yín sílẹ̀ bí aláìlárá. Mò ń pada bọ̀ wá sọ́dọ̀ yín.


Ṣugbọn Alátìlẹ́yìn náà, Ẹ̀mí Mímọ́ tí Baba yóo rán wá ní orúkọ mi, ni yóo kọ yín, tí yóo sì ran yín létí ohun gbogbo tí mo sọ fun yín.


“Nígbà tí Alátìlẹ́yìn tí n óo rán si yín láti ọ̀dọ̀ Baba bá dé, àní Ẹ̀mí tí ń fi òtítọ́ Ọlọrun hàn, tí ó wá láti ọ̀dọ̀ Baba, yóo jẹ́rìí nípa mi.


Bákan náà ni: inú yín bàjẹ́ nisinsinyii, ṣugbọn n óo tún ri yín, inú yín yóo wá dùn, ẹnikẹ́ni kò ní lè mú ayọ̀ yín kúrò lọ́kàn yín.


N kò bẹ̀bẹ̀ pé kí o mú wọn kúrò ninu ayé. Ẹ̀bẹ̀ mi ni pé kí o pa wọ́n mọ́ kúrò lọ́wọ́ Èṣù.


“N kò gbadura fún àwọn wọnyi nìkan. Ṣugbọn mo tún ń gbadura fún àwọn tí yóo gbà mí gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ wọn,


Ṣugbọn ẹnikẹ́ni tí ó bá mu ninu omi tí èmi yóo fi fún un, òùngbẹ kò ní gbẹ ẹ́ mọ́ lae, ṣugbọn omi tí n óo fún un yóo di orísun omi ninu rẹ̀ tí yóo máa sun títí dé ìyè ainipẹkun.”


Ó wí èyí nípa Ẹ̀mí tí àwọn tí ó gbà á gbọ́ yóo gbà láì pẹ́, nítorí nígbà náà ẹnikẹ́ni kò ì tíì rí ẹ̀bùn Ẹ̀mí gbà nítorí a kò ì tíì ṣe Jesu lógo.


Nígbà tí ó wà lọ́dọ̀ wọn, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn má kúrò ní Jerusalẹmu. Ó ní, “Ẹ dúró títí ìlérí tí Baba mí ṣe yóo fi ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gbọ́ tí mo sọ fun yín.


Ayọ̀ kún ọkàn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu. Bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀mí Mímọ́ sì kún inú wọn.


Gbogbo ìjọ ní Judia, ati Galili, ati Samaria wà ní alaafia, wọ́n sì fìdí múlẹ̀. Wọ́n ń gbé ìgbé-ayé wọn pẹlu ìbẹ̀rù Oluwa, wọ́n sì ń pọ̀ sí i nípa ìrànlọ́wọ́ Ẹ̀mí Mímọ́.


Nítorí ìjọba Ọlọrun kì í ṣe ọ̀ràn nǹkan jíjẹ ati nǹkan mímu, ọ̀ràn òdodo, alaafia ati ayọ̀ ninu Ẹ̀mí Mímọ́ ni.


Kí Ọlọrun tí ó ń fúnni ní ìrètí fi ayọ̀ tí ò kún ati alaafia fun yín nípa igbagbọ yín, kí ẹ lè máa dàgbà ninu ìrètí tí ẹ ní ninu Ẹ̀mí Mímọ́.


Ìrètí irú èyí kì í ṣe ohun tí yóo dójú tì wá, nítorí a ti tú ìfẹ́ Ọlọrun dà sí wa lọ́kàn nípa Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó fún wa.


Àbí ta ni yóo dá wọn lẹ́bi? Dájúdájú, kò lè jẹ́ Kristi, ẹni tí ó kú, àní sẹ́ ẹni tí a jí dìde kúrò ninu òkú, tí ó jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọrun, tí ó sì ń bẹ̀bẹ̀ fún wa.


Ṣugbọn èso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, alaafia, sùúrù, àánú, iṣẹ́ rere, ìṣòtítọ́,


Nítorí náà, bí ẹ bá ní ìwúrí kankan ninu Kristi, bí ìfẹ́ rẹ̀ bá fun yín ní ìtùnú, bí ẹ bá ní ìrẹ́pọ̀ ninu Ẹ̀mí, bí ẹ bá ní ojú àánú,


Oluwa wa fúnrarẹ̀ ati Ọlọrun Baba wa, tí ó fẹ́ wa, tí ó fún wa ní ìtùnú ayérayé ati ìrètí rere nípa oore-ọ̀fẹ́,


Ìdí nìyí tí ó fi lè gba àwọn tí wọ́n bá súnmọ́ Ọlọrun nípasẹ̀ rẹ̀ là, lọ́nà gbogbo títí lae nítorí pé ó wà láàyè títí láti máa bẹ̀bẹ̀ fún wọn.


Ẹ̀yin ọmọ mi, mò ń kọ ìwé yìí si yín, kí ẹ má baà dẹ́ṣẹ̀. Bí ẹnikẹ́ni bá wá dẹ́ṣẹ̀, a ní alágbàwí kan pẹlu Baba tíí ṣe Jesu Kristi olódodo.


ẹ jẹ́ kí òróró tí Jesu ta si yín lórí máa gbé inú yín, ẹ kò sì nílò ẹnikẹ́ni láti máa kọ yín lẹ́kọ̀ọ́. Ṣugbọn gẹ́gẹ́ bí òróró rẹ̀ ninu yín ti ń kọ yín nípa ohun gbogbo, òtítọ́ ni, kì í ṣe irọ́, ẹ máa gbé inú rẹ̀, bí ó ti kọ yín.


nítorí òtítọ́ tí ó ń gbé inú wa, tí ó sì wà pẹlu wa yóo wà títí lae.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan