Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 14:1 - Yoruba Bible

1 “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín dàrú. Ẹ gba Ọlọrun gbọ́, kí ẹ sì gba èmi náà gbọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

1 Ẹ maṣe jẹ ki ọkàn nyin dàru: ẹ gbà Ọlọrun gbọ́, ẹ gbà mi gbọ́ pẹlu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 “Ẹ má ṣe jẹ́ kí ọkàn yín kí ó dàrú: ẹ gba Ọlọ́run gbọ́, kí ẹ sì gbà mí gbọ́ pẹ̀lú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 14:1
37 Iomraidhean Croise  

Ìwọ ọkàn mi, kí ló dé tí o fi rẹ̀wẹ̀sì? Kí ló dé tí ara rẹ kò fi balẹ̀ ninu mi? Gbẹ́kẹ̀ rẹ lé Ọlọrun; nítorí pé n óo tún yìn ín, olùrànlọ́wọ́ mi ati Ọlọrun mi.


Nígbà náà ni mo wí pé, “Ohun tí ó bà mí lọ́kàn jẹ́ ni pé Ọ̀gá Ògo kò jẹ́wọ́ agbára mọ́.”


O óo pa àwọn tí wọ́n gbé ọkàn wọn lé ọ mọ́ ní alaafia pípé, nítorí pé wọ́n gbẹ́kẹ̀lé ọ.


Ìbànújẹ́ mi pọ̀ kọjá ohun tí ó ṣe é wòsàn, àárẹ̀ mú ọkàn mi.


Nígbà tí Jesu rí i tí ó ń sunkún, tí àwọn Juu tí ó bá a jáde tún ń sunkún, orí rẹ̀ wú, ọkàn rẹ̀ wá bàjẹ́.


Jesu bá tún sọ pé, “Ọkàn mí dàrú nisinsinyii. Kí ni ǹ bá wí? Ọkàn kan ń sọ pé kí n wí pé, ‘Baba, yọ mí kúrò ninu àkókò yìí.’ Ṣugbọn nítorí àkókò yìí gan-an ni mo ṣe wá sí ayé.


Jesu bá kígbe pé, “Ẹni tí ó bá gbà mí gbọ́, kì í ṣe èmi ni ó gbàgbọ́ bíkòṣe ẹni tí ó rán mi níṣẹ́.


Mo wí fun yín nisinsinyii kí ó tó ṣẹlẹ̀, kí ẹ lè mọ ẹni tí èmi í ṣe nígbà tí ó bá ti ṣẹlẹ̀ tán.


Ẹ kò ì tíì bèèrè ohunkohun ní orúkọ mi títí di ìsinsìnyìí. Ẹ bèèrè, ẹ óo sì rí gbà, kí ẹ lè ní ayọ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.


Wọn yóo ṣe nǹkan wọnyi nítorí wọn kò mọ Baba, wọn kò sì mọ̀ mí.


Ṣugbọn ìbànújẹ́ kún ọkàn yín nítorí mo ti sọ nǹkan wọnyi fun yín.


kí gbogbo eniyan lè bu ọlá fún Ọmọ bí wọ́n ti ń bu ọlá fún Baba. Ẹni tí kò bá bu ọlá fún Ọmọ kò bu ọlá fún Baba tí ó rán an wá sí ayé.


Nítorí ìfẹ́ Baba mi ni pé, kí ẹnikẹ́ni tí ó bá rí Ọmọ rẹ̀, tí ó bá gbà á gbọ́, lè ní ìyè ainipẹkun. Èmi fúnra mi yóo jí wọn dìde ní ọjọ́ ìkẹyìn.”


Kí ẹ wá dáríjì í. Kí ẹ fún un ní ìwúrí. Bí ìbànújẹ́ bá tún pọ̀ lápọ̀jù kí ó má baà wó irú ẹni bẹ́ẹ̀ mọ́lẹ̀.


Nítorí èyí, láti ìgbà tí mo ti gbọ́ nípa igbagbọ yín ninu Oluwa Jesu, ati ìfẹ́ yín sí gbogbo àwọn onigbagbọ, èmi náà


ẹ má jẹ́ kí ọkàn yín tètè mì, tabi kí èrò yín dàrú lórí ọ̀rọ̀ pé Ọjọ́ Oluwa ti dé. Kì báà jẹ́ pé ninu ọ̀rọ̀ wa tabi ninu Ẹ̀mí ni wọ́n ti rò pé a sọ ọ́, tabi bóyá ninu àlàyékálàyé kan tabi ìwé kan tí wọ́n rò pé ọ̀dọ̀ wa ni ó ti wá.


Ẹ̀yin tí ẹ ti ipasẹ̀ rẹ̀ gba Ọlọrun tí ó jí i dìde kúrò ninu òkú gbọ́, tí ó ṣe é lógo, kí igbagbọ ati ìrètí yín lè wà ninu Ọlọrun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan