Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 13:9 - Yoruba Bible

9 Simoni Peteru bá sọ fún un pé, “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, Oluwa, ẹsẹ̀ mi nìkan kọ́, ati ọwọ́ ati orí mi ni kí o fọ̀ pẹlu.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

9 Simoni Peteru wi fun u pe, Oluwa, kì iṣe ẹsẹ mi nikan, ṣugbọn ati ọwọ́ ati ori mi pẹlu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Simoni Peteru wí fún ún pé, “Olúwa, kì í ṣe ẹsẹ̀ mi nìkan, ṣùgbọ́n àti ọwọ́ àti orí mi pẹ̀lú.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 13:9
9 Iomraidhean Croise  

Ọwọ́ mi mọ́, n kò ní ẹ̀bi, OLUWA, mo sì ń jọ́sìn yí pẹpẹ rẹ ká.


Wẹ̀ mí mọ́ kúrò ninu àìdára mi, kí o sì wẹ̀ mí kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ mi!


Fi ewé hisopu fọ̀ mí, n óo sì mọ́; wẹ̀ mí, n óo sì funfun ju ẹ̀gbọ̀n òwú lọ.


Ìwọ Jerusalẹmu, fọ ibi dànù kúrò lọ́kàn rẹ, kí á lè gbà ọ́ là. Yóo ti pẹ́ tó tí èrò burúkú yóo fi máa wà lọ́kàn rẹ?


Nígbà tí Pilatu rí i pé òun kò lè yí wọn lọ́kàn pada, ati pé rògbòdìyàn fẹ́ bẹ́ sílẹ̀, ó mú omi, ó fọ ọwọ́ rẹ̀ níwájú wọn. Ó ní, “N kò lọ́wọ́ ninu ikú ọkunrin yìí. Ẹ̀yin ni kí ẹ mójútó ọ̀ràn náà.”


Jesu wí fún un pé, “Ẹni tí ó bá ti wẹ̀ nílé, tí ó bá jáde, kò sí ohun tí ó kù jù pé kí á fọ ẹsẹ̀ rẹ̀ lọ, gbogbo ara rẹ̀ á wá di mímọ́. Ẹ̀yin mọ́, ṣugbọn kì í ṣe gbogbo yín.”


Peteru dá a lóhùn pé, “O kò ní fọ ẹsẹ̀ mi laelae!” Jesu wí fún un pé, “Bí n kò bá wẹ̀ ọ́, a jẹ́ pé ìwọ kò ní nǹkankan ṣe pẹlu mi.”


Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pẹlu òtítọ́ ọkàn ati igbagbọ tí ó kún, kí á fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wẹ ọkàn wa mọ́, kí ó wẹ ẹ̀rí-ọkàn burúkú wa nù, kí á fi omi mímọ́ wẹ ara wa.


Èyí jẹ́ àkàwé ìrìbọmi tí ó ń gba eniyan là nisinsinyii. Kì í ṣe láti wẹ ìdọ̀tí kúrò lára, bíkòṣe ọ̀nà tí ẹ̀bẹ̀ eniyan fi lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọrun nípa ẹ̀rí ọkàn rere, nípa ajinde Jesu Kristi,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan