Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 13:8 - Yoruba Bible

8 Peteru dá a lóhùn pé, “O kò ní fọ ẹsẹ̀ mi laelae!” Jesu wí fún un pé, “Bí n kò bá wẹ̀ ọ́, a jẹ́ pé ìwọ kò ní nǹkankan ṣe pẹlu mi.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bibeli Mimọ

8 Peteru wi fun u pe, Iwọ kì yio wẹ̀ mi li ẹsẹ lai. Jesu da a lohùn pe, Bi emi kò bá wẹ̀ ọ, iwọ kò ni ìpin lọdọ mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Peteru wí fún un pé, “Ìwọ kì yóò wẹ̀ ẹsẹ̀ mi láé.” Jesu sì dalóhùn pé, “Bí èmi kò bá wẹ̀ ọ́, ìwọ kò ní ìpín ní ọ̀dọ̀ mi.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 13:8
28 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn Jakọbu dáhùn, ó ní, “Ọmọ tèmi kò ní bá yín lọ, nítorí pé ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan ni ó kù. Bí ohunkohun bá ṣẹlẹ̀ sí i ní ìrìn àjò tí ẹ fẹ́ lọ yìí, mo ti darúgbó, ìbànújẹ́ rẹ̀ ni yóo rán mi sọ́run.”


Aláìníláárí ẹ̀dá kan wà ní ààrin àwọn ará Giligali tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ṣeba, ọmọ Bikiri, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini. Ọkunrin yìí fọn fèrè, ó ní, “Kò sí ohun tí ó kàn wá pẹlu Dafidi, a kò sì ní ìpín nílé ọmọ Jese. Ẹ pada sí ilé yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli.”


Nígbà tí gbogbo Israẹli rí i pé, ọba kò gbọ́ tiwọn, wọ́n dá a lóhùn pé, “Kí ló kàn wá pẹlu ìdílé Dafidi? Kí ló dà wá pọ̀ pẹlu ọmọ Jese? Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ẹ pada sílé yín, kí Dafidi máa bojútó ilé rẹ̀!”


Wẹ̀ mí mọ́ kúrò ninu àìdára mi, kí o sì wẹ̀ mí kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ mi!


Fi ewé hisopu fọ̀ mí, n óo sì mọ́; wẹ̀ mí, n óo sì funfun ju ẹ̀gbọ̀n òwú lọ.


Nígbà tí OLUWA bá ti fọ èérí Jerusalẹmu dànù, tí ó sì jó o níná tí ó sì mú ẹ̀bi ìpànìyàn kúrò níbẹ̀, nípa pé kí wọn máa ṣe ìdájọ́ òtítọ́,


N óo wọ́n omi mímọ́ si yín lórí, àìmọ́ yín yóo sì di mímọ́. N óo wẹ̀ yín mọ́ kúrò ninu gbogbo ìbọ̀rìṣà yín.


OLUWA ní, “Nígbà tó bá yá, orísun omi kan yóo ṣí sílẹ̀ fún ilé Dafidi, ati fún àwọn ará Jerusalẹmu láti wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò ninu ẹ̀ṣẹ̀ ati ìwà èérí wọn.


Ni Peteru bá pè é sí ẹ̀gbẹ́ kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí bá a wí pé, “Ọlọrun má jẹ́! Oluwa, irú èyí kò ní ṣẹlẹ̀ sí ọ.”


Ọmọ náà dá a lóhùn pé, ‘N kò ní lọ.’ Ṣugbọn lẹ́yìn ìgbà díẹ̀, ó ronupiwada, ó bá lọ.


Peteru dá a lóhùn pé, “Bí gbogbo àwọn yòókù bá tilẹ̀ pada lẹ́yìn rẹ, bíi tèmi kọ́!”


Peteru sọ fún un pé, “Bí mo bá tilẹ̀ níláti bá ọ kú, n kò ní sẹ́ ọ.” Bákan náà ni gbogbo àwọn ọmọ-ẹ̀yìn yòókù sọ.


Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Simoni Peteru, Peteru bi í pé, “Oluwa, ìwọ ni o fẹ́ fọ ẹsẹ̀ mi?”


Simoni Peteru bá sọ fún un pé, “Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, Oluwa, ẹsẹ̀ mi nìkan kọ́, ati ọwọ́ ati orí mi ni kí o fọ̀ pẹlu.”


Jesu dáhùn pé, “Mo fẹ́ kí o mọ̀ dájúdájú pé, ẹnikẹ́ni tí a kò bá fi omi ati Ẹ̀mí bí, kò lè wọ ìjọba Ọlọrun.


Ó wá bèèrè pé, kí ni mo tún ń fẹ́ nisinsinyii? Ó ní kí n dìde, kí n ṣe ìrìbọmi, kí n wẹ ẹ̀ṣẹ̀ mi nù, kí n pe orúkọ Oluwa.


Àwọn mìíràn wà ninu yín tí wọn ń hu irú ìwà báyìí tẹ́lẹ̀. Ṣugbọn nisinsinyii, a ti wẹ̀ yín mọ́, a ti yà yín sọ́tọ̀, a ti da yín láre nípa orúkọ Oluwa Jesu Kristi ati nípa Ẹ̀mí Ọlọrun wa.


Ó ṣe èyí láti yà á sọ́tọ̀. Ó sọ ọ́ di mímọ́ lẹ́yìn tí ó ti fi omi wẹ̀ ẹ́ nípa ọ̀rọ̀ iwaasu.


Ẹ óo sì máa yọ̀ níwájú OLUWA Ọlọrun yín, ati ẹ̀yin ati àwọn ọmọ yín lọkunrin ati lobinrin, ati àwọn iranṣẹkunrin yín, ati àwọn iranṣẹbinrin yín, ati àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n wà láàrin ìlú yín, nítorí pé wọn kò ní ìpín ninu ilẹ̀ yín.


Ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni da yín lẹ́bi, kí ó sọ fun yín pé kí ẹ máa fi ìyà jẹ ara yín, kí ẹ máa sin àwọn angẹli. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ń ṣe ìgbéraga nípa ìran tí ó ti rí, ó ń gbéraga lásán nípa nǹkan ti ara rẹ̀;


Ó lè dàbí ẹni pé ọgbọ́n wà ninu àwọn nǹkan wọnyi fún ìsìn ti òde ara ati fún ìjẹra-ẹni-níyà ati fún ìkóra-ẹni-níjàánu. Ṣugbọn wọn kò ṣe anfaani rárá láti jẹ́ kí eniyan borí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti ara.


kì í ṣe nítorí iṣẹ́ rere kan tí a ṣe, ṣugbọn nítorí àánú rẹ̀ ni ó fi gbà wá là, nípa ìwẹ̀mọ́ pẹlu omi tí ó fi tún wa bí, ati Ẹ̀mí Mímọ́ tí ó fi sọ wá di ẹni titun.


Nítorí náà, ẹ jẹ́ kí á súnmọ́ ọ̀dọ̀ rẹ̀ pẹlu òtítọ́ ọkàn ati igbagbọ tí ó kún, kí á fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wẹ ọkàn wa mọ́, kí ó wẹ ẹ̀rí-ọkàn burúkú wa nù, kí á fi omi mímọ́ wẹ ara wa.


ati láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, ẹlẹ́rìí òtítọ́, ẹnikinni tí ó jinde láti inú òkú ati aláṣẹ lórí àwọn ọba ilé ayé. Ẹni tí ó fẹ́ràn wa, tí ó fi ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wa.


Mo bá dá a lóhùn pé, “Alàgbà, ìwọ ni ó mọ̀ wọ́n.” Ó wá sọ fún mi pé, “Àwọn wọnyi ni wọ́n ti kọjá ninu ọpọlọpọ ìpọ́njú. Wọ́n ti fọ aṣọ wọn, wọ́n ti sọ wọ́n di funfun ninu ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́ Aguntan.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan